You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Afenifere àtàwọn ọba alayé fẹnukò pé kí Edo, Kogi, Delta àti Kwara darapọ̀ mọ́ ilẹ̀ Yorùbá nínú àtúntò Nàìjíríà
Awọn alẹnulọrọ ati awọn ọba alaye nilẹ kaarọ-o-jiire-bi ti sọ pe awọn fi ara mọ atunto orileede Naijiria, niwọn igba ti yoo ba ti ba ti ṣe anfaani rere fun araalu, paapaa ilẹ Yoruba.
Bakan naa ni wọn sọ pe ko si nnkan to buru nibẹ, bi wọn ba pin awọn ipinlẹ bii Delta, Edo, Kogi ati Kwara mọ ilẹ Yoruba, iyẹn bi awọn alẹnulọrọ wọn ba ti fọwọ sii.
Bi ẹ ko ba gbagbe, laipe yii ni ẹgbẹ agbaagba ilẹ Yoruba kan labẹ ẹgbẹ aburada Council of Yoruba Elders (CYE) sọ ninu atẹjade ti wọn gbe sita lopin ọsẹ to kọja pe asiko ti to fun atunto.
Atẹjade ọhun ti akọwe agba ẹgbẹ naa, Ọmọwe Victor Taiwo pe akọle rẹ ni Ibẹrẹ irin ajo sinu atunto Naijiria, iyẹn ‘The Practical Beginning of the Journey to the Restructuring of Nigeria’, lo ti sọ pe ko si nnkan to tun n ṣiṣẹ mọ ni Naijiria lasiko yii.
“Agbekalẹ apapọ orileede ti dẹnukọlẹ gẹgẹ bii kaadi ayo. Wọn ti n wa ọkọ orileede yii lọ sibi ti ko si ọna mọ, oko iparun. Lonii, ko si ohun kankan to tun n ṣiṣẹ mọ ni Naijiria.
“Awọn araalu ti n koju oriṣiriṣi iṣoro ati ipenija nla bii iyan, ọwọngogo, owo naira to n dẹnukọlẹ, aisi iṣẹ, awọn ileeṣẹ to n dẹnukọlẹ, eto ẹkọ to n dẹnukọlẹ, eto ilera ti ko kaju oṣuwọn, ina mọnamọna ti ko dara, ijinigbe, ipaniyan-ṣẹṣo, idigunjale, aisi eto aabo, to fi mọ iṣẹ ati oṣi pọmbele.
“Ki ẹ si maa wo o, ko si aridaju kankan pe ireti ṣi wa lorileede yii mọ.”
Bakan naa ni wọn tun fi kun un wi pe ipilẹ orileede yii, iyanrin ti wọn sare ko jọ ni wọn fi ṣe e.
Nipa atunto, wọn ni “awọn eeyan kaakiri ẹkun mẹfa to wa nilẹ Yoruba, ni ki wọn ṣe agbekalẹ ipade apapọ, lati tẹle abajade apero ti ọdun 2014 (2014 CONFAB), ki wọn si ṣagbeyẹwo rẹ daadaa, lati le ni ibaṣepọ to dan mọnran.”
Bakan naa ni wọn tun fi kun un pe ẹkun ilẹ Yoruba ni ko ṣagbatẹru apero ọhun nipaṣe agbekalẹ ti wọn pe ni apero ṣaaju apero (Restructuring Before Restructuring).
Bẹẹ ni wọn tun n pe fun atunṣe ilẹ Yoruba nipa kiko awọn ipinlẹ bii Kwara, Kogi, Edo ati Delta mọra.
Kii ṣe asiko yii lo yẹ ka maa pariwo atunto - Olugbọn sọrọ
Ọba Francis Adewale Alao, Olugbọn tilu Orile-Igbọn nigba to n sọ erongba rẹ lori atẹjade ẹgbẹ CYE, o ni ko ohun to buru nibẹ rara niwọn igba ti ẹnu ba ti ko lee lori.
“Gbogbo wa ni ọrọ yii kan lai yọ ẹnikẹni silẹ. O dara nitori pe lara awọn atunto ti a pe fun naa ni.
“Mo ni anfaani lati wa lara awọn aṣoju. Ọmọ wa si ni atunto nilẹ Yoruba. Ẹmi pẹlu awọn Afẹnifẹre ti jokoo sọrọ lati sọrọ lori awọn ipenija.
“A ni iṣoro eto ọrọ aje, eto aabo ati awọn miran. O digba ti ijọba apapọ ba ṣe atunṣe lati mu eto ọrọ aje bọ sipo, ni a le maa sọrọ nipa atunto.
“Gbogbo eeyan lo n fẹ atunto, ṣugbọn iyẹn kọ lo yẹ ko jẹ ohun ti a ma maa gbe sori bayii. Awọn eeyan n jiya bayii, orileede yii n ṣẹjẹ. Ọwọngogo lori ọrọ aje.
“Ijọba yii si n dojukọ ọpọlọpọ iṣoro. Aarẹ sọ fun wa pe ọmọ wa ni atunto jẹ. Bi a ba si fẹ ṣe atunto, kii ṣe niru asiko ti awọn eeyan sunkun ebi yii.”
Ko si ohun to buru nibẹ - Oluwo tilu Iwo
Ọkan pataki lara awọn alẹnulọrọ ilẹ Yoruba, to tun jẹ gbajugbaja Ọba to n sọ bi ọkan rẹ ṣe ri, Ọba Adewale Akanbi, Telu kinni, Oluwo tilu Iwo nipinlẹ Ọṣun naa sọrọ.
Kabiyesi ni, “Ti awọn ipinlẹ naa ba ti fara mọ ọn, to si dun mọ wọn ninu, ti igbagbọ si wa pe a jọ maa ni ajọṣepọ to dara, mo lero pe ko si ohun to buru nibẹ, nnkan to maa ṣe ohun rere funa awa naa ni.
“Ṣe ẹ ri eto iṣẹjọba awa-ara-wa ti ẹ n wo yii, onka ni. Mo nigbagbọ pe anfaani nla lo maa jẹ fun gbogbo wa ni ẹkun Guusu-Iwọ-Oorun ti a wa yii.
“Mo gba wi pe awọn ti wọn jọ fẹ ko wa papọ yẹn, erongba wa yoo ṣọkan, ti yoo si jẹ anfaani nla. Ohun to dara gigi gan-an ni, Ọlọrun yoo si fun wa ṣe.
“Bi wọn ba sọ fun wọn, gbogbo eeyan ni yoo wo o lati mọ boya ohun dara fun wọn ni. Awọn ẹya ti a n sọ yi gan-an, paapaa niluu Ilọrin, ede Yoruba ni wọn n sọ nibẹ, wọn kan ka wọn kun ẹkun Ariwa ni.
“Guusu lo yẹ ki wọn wa tẹlẹtẹlẹ nitori pe Kwara, ko si ẹni to n sọ ede Hausa nibẹ. Bẹẹ naa ni Kogi, bi ko si pe wọn ba gbọ ede miran, Yoruba ni wọn n sọ, gbogbo wọn la jọ sunmọ ara wa.
“Bi ẹ ba si wo agbegbe Ondo, awọn naa sunmọ Delta, bi wọn ba le gba, yoo ṣe ọpọlọpọ oore, yoo si tun gbe agbara nla fun wa bi wọn ba jọ ko wa papọ.
“Laye atijọ bi ẹ ko ba gbagbe, awọn wọnyi wa lara ẹkun iṣejọba Iwọ-Oorun ki wọn to pin wa, iyẹn nigba ti a n ṣe ijọba ẹlẹkun-o-jẹkun. Awọn Itsekiri, Warri wa nigba naa.
“Nigba naa, ẹ maa ri wi pe awọn gan an wa lara awọn igbimọ iṣakoso, bi ẹ ba lọ wo ibi ti wọn pe ni ‘House of Chiefs ni Ibadan' nigba yẹ, Oluwo wa nibẹ, ti a si jọ jẹ minisita.
Ifinifẹdọ lo gbọdọ jẹ - Afẹnifẹre
Agbẹnusọ fun ẹgbẹ Afẹnifẹre, Kọmureedi Jare Ajayi nigba to n sọrọ sọ pe bo tilẹ jẹ pe erongba awọn ko yatọ si ti eyi ti ẹgbẹ CYE gbe jade, sibẹ o ni ifinifẹdọ lo gbọdọ jẹ.
Ajayi sọ pe pinpin awọn ipinlẹ wọnyi mọ ilẹ Yoruba ko gbọdọ jẹ eyi ti ijọba apapọ yoo kan nipa, ati pe asọyepọ gbọdọ wa lati mọ boya o tẹ awọn eeyan naa lọrun.
“Ẹgbẹ ti ẹ darukọ yii ni wọn le dahun boya wọn ba awọn kan sọrọ tabi wọn ko ba awọn kan sọrọ, ṣugbọn gẹgẹ bi ẹ ti ṣe mọ pe ẹgbẹ Afẹnifẹre, a nigbagbọ gidi gan-an ninu atunto orileede Naijiria, a si gbe e larugẹ.
“A nigbagbọ pe awọn eeyan wa to wa ni Kogi, Yoruba gidi ni wọn jẹ, bakan naa nipinlẹ Kwara, a ni awọn eeyan wa nibẹ, wọn si lẹtọọ lati wa pẹlu awọn ọba wọn.
“Bakan naa lo ri pẹlu awọn ipinlẹ yooku bii Edo ati Delta. Ṣugbọn sibẹ, loju ti wa, kii ṣe pe ijọba appọ ni yoo paṣẹ, rara. Ijọba ni yoo beere lọwọ awọn ara ipinlẹ wọnyi lati mọ boya wọn fara mọ ọn.
“Ara ohun to fa ijalulẹ lori eyi ti wọn ti ṣe tẹlẹ niyẹn, to jẹ pe awọn ologun kan-an nipa fun awọn eeyan lasan ni lai beere boya o tẹ wọn lọrun.
“To ba jẹ pe niṣe ni wọn ti beere lọwọ ọtun ati osi lati mọ erongba wọn, gbogbo rukerudo to n ṣẹlẹ yii ko nii waye rara. Nipa bẹẹ, a gba pe awọn ipinlẹ ti wọn darukọ naa, ara ilẹ Yoruba ni wọn jẹ, wọn si wa pẹlu ẹkun Guusu-Iwọ Oorun.
“Ifinufẹdọ lo gbọdọ jẹ, kii ṣe nipa afipa mu, eyi ni ko fi ni jẹ ki ikunsinu, aawọ tabi wahala wa lẹyin rẹ. Ori ohun ti a duro le lori niyẹn, kii ṣe pe a lodi si nnkan ti Council of Yoruba Elders n sọ, ṣugbọn ilana ti awa gbe dani naa niyẹn.”
A fẹ́ kí ìjọba kó Edo, Kogi, Delta àti Kwara pọ̀ mọ́ ilẹ̀ Yorùbá nínú àtúntò Nàìjíríà - Ẹgbẹ́ CYE
Pẹlu bi kudiẹkudiẹ ṣe de ba ọrọ aje ati ọrọ oṣelu, igbimọ awọn agbaagba ni ilẹ Yoruba CYE ti kesi ìjọba apapọ lati gunle atunse orilẹede Naijiria ni ọna ti yoo mu idagbasoke waye.
Igbimọ tun wa jẹ ko di mimọ pe pẹlu awọn rogbodiyan to n lọ lọwọ lorilẹede yii, ko fẹ si nnkankan to ṣíṣẹ mọ lorilẹede Naijiria.
Bakan naa ni naa tun rọ ijọba apapọ lati ṣe atunṣe si awọn ipinlẹ kan to yẹ ko wa labẹ ipinlẹ Yoruba.
Ẹgbẹ naa ni awọn ipinlẹ bí Edo, Kwara, Delta ati Kwara lo yẹ ko jẹ ipinlẹ Yoruba.
Ọrọ yii lo wa ninu atẹjade kan ti akọwe ẹgbẹ, Dokita Victor Taiwo fi lede fun awọn akọroyin lopin ọsẹ.
Lonii, ko si nnkan to n sisẹ mọ lorilẹede yii, gbogbo nnkan ti dawo.
"Ebi n pa araalu, ọwọngogo gbode, owo Naira n lọ soke si, ko si isẹ níta fáwọn ọdọ, eto ẹkọ mẹhẹ, eto ìlera naa bakan naa.
"Ijinigbe, isekupani, idigunjale, eto abo ati isẹ to wọpọ lawujọ, pẹlu gbogbo eyi, ko da bi pe ireti wa."
Igbimọ bu ẹnu atẹlu bi isejọba Aarẹ Bola Tinubu ṣe pàṣẹ pe ki wọn yọ owo iranwọ epo bentiroolu lẹyin to ti pe igbimọ kan tí wọn salaye pe igbesẹ yii yoo fà ìnira tí a n koju lonii.
Bakan naa ni wọn kesi ìjọba pe lati koju awọn isoro yii, wọn ní ṣe atunse nla meji : atunse orilẹede ati atunṣe ilẹ Yoruba.
"Ẹ pe awọn eeyan lati igun mẹfa to wa lorilẹede Naijiria lati jí roro lori bi ajọsepọ nla yoo se wa."