You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Omíyalé àti ilẹ̀ rírì ṣọṣẹ́ ní Nepal, èèyàn 100 jáde láyé
O kere tan, ọgọrun eeyan lo ti jade layer lẹyin iṣẹlẹ omiyale ati ilẹ riri to waye lorilẹede Nepal.
Yatọ si awọn to jade laye, ọpọ awọn mii lo di awati lẹyin ojo arọrọda to waye fun ọjọ meji lerelera ni ilu Kathmandu to jẹ olu ilu orilẹede naa.
Ọpọ eeyan lo ha si ori orule ile wọn latari ojo arọrọda naa bi awọn adoola ẹmi ṣe n gbiyanju lati doola awọn eeyan.
Lọwọ yii, ọpọlọpọ awọn ile gbigbe to wa lẹba odo ni omi ti gbe lọ, bẹẹ ni omi gba oju popo.
Ijọba orilẹede ọhun sọ pe nnkan bii ẹgbẹrun mẹta eeyan lawọn ti doola bayii bo tilẹ jẹ ọpọ lo dagbare faye.
Niluu Bhaktapur, eeyan marun un lo ku nibẹ, lara wọn ni alaboyun ati ọmọbirin to jẹ ọmọ ọdun mẹrin lẹyin ti ile wo le wọn lori.
Ni Dhading, wọn yọ oku eeyan meji labẹ ọkọ akero bọọsi ti ilẹ bo mọlẹ.
Eeyan mejila, to fi mọ awakọ naa lo wa ninu ọkọ akero ọhun.
Lara awọn to tun jade laye ni agbabọọlu mẹfa ti ilẹ bo mọlẹ ni gbagede ti wọn ti n gbaradi fun ifẹsẹwọnsẹ.
A gbọ pe bi ilẹ ṣe n bo awọn eeyan mọlẹ naa ni omi n gbe ọpọ awọn mii lọ.
Oṣoju mi koro kan, Jitendra Bhandari sọ fun BBC pe “fun ọpọlọpọ wakati ni wọn fi n bẹbẹ fun iranlọwọ ṣugbọn ko si ohun ti a le ṣe.”
Agbẹnusọ ijọba, Prithvi Subba Gurung, sọ fun ileeṣẹ iroyin Nepal Television Corporation pe omiyale naa ti ṣakoba fun ọpa to n gbe omi ati ila ẹrọ ibaraẹnisọrọ.
Wayi o, nnkan bii ẹgbẹrun mẹwaa ọlọpaa ni ijọba ilẹ naa ti da si igboro bayii lati doola awọn ti iṣẹlẹ naa kan gbọnbgọn.