BBC tú àṣírí ilé tí wọ́n ti ń fi pàṣán bó ìdí àwọn arúgbó

Ẹka oluwadii ileeṣẹ iroyin BBC, Africa Eye, ti tu aṣiri bi awọn oṣiṣẹ ile itọju arugbo kan ni Kenya ṣe n fi iya jẹ awọn arugbo lọna ti ko tọ.

Awọn fọran ti a ya ni ikọkọ tu aṣiri bi awọn oṣiṣẹ naa ṣe n fi iya jẹ awọn arugbo ọhun bii ki wọn na wọn wọn pẹlu ẹgba; ki wọn ma ṣe itọju wọn ti wọn ba n ṣaisan tabi ki wọn fun wọn lounjẹ lai si ninu abọ, ati bẹẹbẹẹ lọ.

Nnkan bii ogun kilomita si ilu Nairobi ni ile itọju arugbo naa, Thogoto Care Home for the Aged, wa.

Ninu awọn fọran ti a ya pẹlu oṣiṣẹ ile arugbo naa mẹta pẹlu iya arugbo kan, a ri bi wọn ṣe n ba iya arugbo naa sọrọ nipa ibi to lọ, ti wọn si n ko paṣan bo idi iya agba naa.

Ẹgbẹ Women's Guild ti ijọ Presbyterian Church of East Africa lo da ile arugbo ọhun silẹ lọpọ ọdun sẹyin, nibi ti awọn arugbo ti iye wọn to aadọta n gbe.

Iye ile itọju arugbo to wa niluu Nairobi ti le ni ilọpo mẹta laarin ọdun mẹwaa sẹyin, pupọ ninu awọn ile itọju arugbo ọhun si ni kii gba owo ilegbe lọwọ awọn arugbo naa latari pe awọn ile ijọsin kan lo n ṣe onigbọwọ wọn.

Ajọ kan to n ri si eto ikaniyan nilẹ Amẹrika, United States Census Bureau sọ lọdun 2020 pe iye awọn arugbo to wa ni Afrika yoo le si lati miliọnu márùndínlọ́gọ́rin si òjìlènígba dín marun miliọnu ni ọgbọn ọdun si asiko yii.

Njẹ o tọ lati maa fi iya jẹ awọn arugbo, ati pe irufẹ ijiya wo lo tọ si ẹnikẹni to ba fi iya jẹ arugbo?

Wo fidio to wa loke yii fun ẹkunrẹrẹ abọ iwadii wa.