Gómìnà Oyetola fẹ́ fi ìbò ìjọba ìbílẹ̀ rán ìpínlẹ̀ Osun sínú ọ̀gbun gbèsè tuntun ni - PDP Osun

rọ ibo ijọba ibilẹ ni ipinlẹ Ọṣun lo tun n da awuyewuye silẹ bayii lẹyin idibo sipo gomina ni ipinlẹ naa eyi ti Sẹnetọ Ademọla Adeleke bori.

Ni ọjọ Aje ọjọ keedogun, oṣu kẹjọ, 'odun 2022 ni ajọ eleto idibo ni ipinlẹ Ọṣun, OSIEC kede nibi ipade kan pẹlawọn akọroyin pe oun ti fi idibo sijọba ibilẹ kaakiri ipinlẹ naa si ọjọ karundinlogun oṣu kẹwaa ọdun 2022.

Ikede yii ṣe ọpọ ni haahin bẹẹ ni ko si ba awọn miran labo.

Lootọ ipinlẹ Ọṣun ko tii ṣe eto ijọba ibilẹ lẹyin ti wọn tu awọn ọmọ igbimọ alakoso ti wọn yan lasiko idibo Parliamentary to waye nigba ijọba Rauf Arẹgbẹṣọla gẹgẹbi gomina ipinlẹ naa.

ara awọn ọna lati tubọ ju ipinlẹ yii sinu ọgbun gbese ati oṣi ni eto idibo ijọba ibilẹ ti wọn n gbe- PDP

Nigba ti ẹgbẹ oṣelu PDP ti yoo gba iṣejọba ni ipinlẹ naa loṣu kọkanla yoo dahun, wọn ni igbesẹ to tako ilana lamẹtọ ni igbesẹ ti ijọba gbe naa lati ṣe eto idibo sijọba ibilẹ ni igba ti oorun ijọba rẹ n rebi ati wọ.

Ninu ọrọ ti alaga igbimọ alakoso fidihẹ ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Ọṣun, Akindele Adekunle sọ lasiko ijiroro kan pẹlawọn oniroyin, ẹgbẹ oṣelu PDP ni ọgbọn ni ijọba ipinlẹ Ọṣun n da lati da ewe bo awọn iwa ijẹkujẹ to ti hu silẹ.

Bakan naa lo ke si ọga agba patapata ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹede Naijiria, ati kọmiṣọnna ọlọpaa nipinlẹ ọhun pe ki wọn tete gbe igbesẹ to yẹ lati dena eefin wahala to n ru naa ko to di ina rogbodiyan ti yoo tigi boju alaafia nipinlẹ naa.

“Eto idibo ti wọn n gbero naa ko le bọ sii rara, nitori gẹgẹbi a ṣe sọ ṣaaju ara awọn ọna lati tubọ ju ipinlẹ yii sinu ọgbun gbese ati oṣi ni.”

Ki lo de ti ipinlẹ Ọṣun n gbero idibo ijọba ibilẹ bayii ti ijọba to wa lode n kogba wọle?

Alaga ajọ eleto idibo ipinlẹ Ọṣun, Ọtunba Oluṣẹgun Ọladuntan ṣalaye pe idibo ọtẹ yii yoo yatọ si tọdun 2018 to jẹ pe awọn aṣoju nikan ni wọn yan sipo nijọba ibilẹ labẹ eto iṣejọba alaṣoju ti oyinbo n pe ni “Parliamentary system.”

O ni lọtẹ yii, eto iṣejọba apaṣẹ waa, “executive presidential system’ ni wọn yoo lo.

O ni eto idibo naa iba ti waye lọdun meji sẹyin bi kii ba ṣe ti ajakalẹ arun COVID-19 ati wahala iwọde EndSARS.