Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ girama dá olùkọ́ lọ́nà, lù ú lálùbami ní Ogun

Ilé ayé ń lọ à ń tọ̀ ọ́, ọwọ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun ti tẹ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ girama mẹ́wàá kan fẹ́sùn wí pé olùkọ́ wọn kan.

Ìròyìn ni pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà lọ dá olùkọ́ náà tí orúkọ ń jẹ́, Kolawole Shonuga lọ́nà tí wọ́n sì lù ú bí i kíkú bí i yíyè nítorí kò jẹ́ kí wọ́n jí ìwé wò lásìkò ìdánwò.

Ní ilé ẹ̀kọ́ Isanbi Comprehensive High School, Ilisan-Remo, ìjọba ìbílẹ̀ Ikenne ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun.

Lásìkò tí Shonuga ń ṣe àyẹ̀wò àwọn akẹ́kọ̀ọ́ SS1 ló rí akẹ́kọ̀ọ́ kan, Ashimi Adebanjo tó ń jí ìwé wò, tó sì gba ìwé náà lọ́wọ́ rẹ̀.

Lẹ́yìn náà ni àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó jẹ́ akẹgbẹ́ Ashimi lọ dènà dè é lẹ́yìn tí wọ́n jáde tí wọ́n sì lù ú bí ejò àìjẹ.

Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn ṣe sọ ọkàn nínú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà, Kazeem Adelaja la igi mọ́ Shonuga lórí tí àwọn yòókù sì da ọwọ́ bò ó.

Agbenusọ ọlọ́pàá Ogun, Omotola Odutola nígbà tó ń fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ fún BBC Yoruba ní àwọn afurasí mẹ́wàá ni ọwọ́ àwọn tẹ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Odutola ní Shonuga ló wà fi ẹjọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà sùn ní àgọ́ ọlọ́pàá Remo.

Nínú ọ̀rọ̀ tirẹ̀, alága ẹgbẹ́ àwọn olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ girama ní ìpínlẹ̀ Ogun, Felix Agbesanwa ní àwọn ti pinnu pé akẹ́kọ̀ọ́ tó bá fi lè ṣí owó lu olùkọ́ rẹ̀ yóò fojú winá òfin.

Agbesanwa ní òun gbọ́ pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ti fojú ba ilé ẹjọ́ tí àwọn sì ń retí àbájáde ìgbẹ́jọ́ náà.

Ìjọba Ogun korò ojú sí ìṣẹ̀lẹ̀ náà

Ijoba ìpínlẹ̀ ti bu ẹnu àtẹ́ lu ìwà tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà hù tí wọ́n sì jẹ́jẹ̀ẹ́ láti fòpin sí ìwà búburú lọ́wọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́.

Olùbádámọ̀ràn pàtàkì sí gómìnà Abiodun lórí ètò ẹ̀kọ́, sáyẹ́ǹsì àti ìmọ̀ ẹ̀rọ, Ọ̀jọ̀gbọ́n Abayomi Arigbabu ló sọ ọ̀rọ̀ yìí.

Arigbabu ní ìjọba tí ń gbé ìgbésẹ̀ bíi jíjẹ́ kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́, òbí wọn tọwọ́bọ ìwé pé akẹ́kọ̀ọ́ tó bá ti hu ìwà tí kò tọ́ máa kojú ẹ̀sùn rẹ̀.

Ó ní èyí wáyé láti ri pé ìwà ọmọlúwàbí wà lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ gbogbo.

Bákan náà ló gba àwọn òbí lámọ̀ràn láti ba àwọn ọmọ wọn níwọ̀ọ́ wí pé ọmọ tí ọwọ́ bá tẹ̀ tó ń hu ìwà ipá máa jìyà rẹ̀.