Bàlúù ogun ju àdó olóró pa èèyàn 17 ní Khartoum, olú ìlú Sudan

Oríṣun àwòrán, Reuters
Eeyan mẹtadinlogun, ninu eyi ti awọn ọmọ wẹwẹ marun un wa, ni ado oloro kan ti wọn ju si agbegbe kan ni Khartoum ti i ṣe olu ilu Sudan ti ran lọ sọrun.
Awọn alaṣẹ lorilẹede Sudan n sọ pe ile marundinlọgbọn ni wọn bajẹ lasiko ti ọkan lara awọn igun ọmogun mejeeji to n gbena woju ara wọn nibẹ fi ju ado oloro si agbegbe Yarmouk lọjọ Satide.
Ikọlu ado oloro yii n waye lẹyin ọjọ kan ti gagun ileeṣẹ ọmọogun orilẹede naa kan fi lerileka pe awọn yoo tubọ tun ina ikọlu da lati koju ija si awọn ọmọ ogun ikọ RSF.
Ija bẹrẹ laarin awọn ọmọ ogun ileeṣẹ ologun Sudan atawọn ọmọ ogun ikọ RSF ni oṣu kẹrin latari edeaiyede emi-ju-ọ-iwọ-o-ju-mi to bẹ silẹ laarin awọn adari ologun lorilẹede naa.
Ko din ni ẹgbẹrun kan awọn eeyan to ti ba ija naa lọ sọrun alakeji, ti ẹgbẹlẹgbẹ miran si tun ti fara ṣeṣe loriṣiriṣi gẹgẹ bi iroyin ti ẹgbẹ awọn dokita lorilẹede naa fi sita.
Oniruru adehun ipẹtusaawọ ni wọn ti kede laarin igun mejeeji lati fun awọn eeyan lanfani ati sa asala kuro lawọn agbegbe ti ina ija ti n jo kikankikan, ṣugbọn ti ko si eyikeyi ninu awọn igun naa to bọwọ fun adehun naa.
Ikọlu to ṣẹṣẹ waye yii, gẹgẹ bi ikọ ọmọogun RSF ṣe sọ, waye lawọn agbegbe bii Mayo, Yarmouk ati Mandela.Amọṣa awọn ikọ ọmọ ogun ilẹ Sudan ko tii fesi kankan lori rẹ.








