You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Èmi ni igbákejì Ooni Ile Ife nítorí... - Olòrì Folashade Ashley
Olori Ọọni ile Ifẹ, Olori Afọlaṣade Ashley Adeyẹye Ogunwusi ti ṣalaye pe bi ọrọ ba ti di ọrọ omi, oun naa ni igbakeji si Ọọni Ile Ifẹ.
Olori Afọlaṣade Ashley Ogunwusi ṣalaye yii lasiko to fi n ba awọn akọroyin sọrọ nibi ajọdun Olokun to waye nilu Eko.
Olori Afọlaṣadde Ashley ni idi ti oun fi pe ara oun ni igba keji lori ọrọ iṣẹṣe ko ju wi pe oun naa ni oun n karamasiki iṣẹṣe ati wi pe Kabiyesi Ọọni ti fi oun ṣe olori gbogbo omi to wa ni ilẹ Oodua.
Olori Ashley Ogunwusi ni gẹgẹbi ẹni to mọ pataki iṣẹṣe IlẹOodua ni Ọọni ṣe fi oun si akoso awọn omi nilẹ Oodua.
“Gẹgẹbi Olori, Emi naa ni igbakeji si Baba to ba ti di ọrọ omi. Ti baba o ba ti si nibi emi naa ni wọn maa ran pe ki n wa ṣe e.”
Ninu alaye to ṣe, Olori Ashley ni gbogbo ọrọ to ba ti nii ṣe pẹlu iṣẹṣe omi bii Olokun, Ọṣara, Ọṣun, Yemọja ati bẹẹbẹẹ lọ.
Lori ọdun Olokun nilẹ Yoruba, Olori Ashley ni ọdun to ṣe pataki pupọ ni to si fi ara kan gbogbo ẹsin yoowu lagbaye. O ni ko si ẹsin kan lagbaye, yala Islam, Kristẹni tabi iṣẹṣe ti ko fara ti omi ni ọna kan tabi omiran.
“Ko si ẹni to n ba omi ṣọta. Ko si ẹsin kankan ti kii lo omi. Awọn Musulumi ko le gba adura lai lo omi. Bi awọn Kristẹni ba n ṣe adura wọn naa, wọn maa n wa si idi okun wa ṣe adura wọn ati iribọmi. Ko si ẹsin kankan to maa sọ pe oun ko gbagbọ ninu omi nitori pataki omi. Omi labuwẹ omi labumu,. Ti a ba ri ẹnikẹni ti ko gbagbọ ninu omi, a jẹ wi pe nnkan miran ti wa nibẹ niyẹn.”
Bakan naa lo tun lo anfani ọdun naa fi ṣe iwure fun aarẹ ti ilu dibo yan ni Naijiria, Bọla Ahmed Tinubu pe ki Eledumare pese ohun gbogbo to nilo lati fi tu orilẹede Naijiria ṣe.
Ta ni Olori Afọlaṣade Ashley?
Olori Afọlaṣade Ashley ni olori kẹrin ni aafin Oodua. Oṣu kẹwaa ọdun 2022 ni Kabiyesi Ọọniriṣa gbe e niyawo lẹyin ohun ti ọpọ pe ni adehun ifẹ ọlọdun gbọọrọ laarin wọn.
Idile oye, Adeniyi Adegoke ni ilu ile Ifẹ naa ni O ti jade wa.
Ṣaaju rẹ, Ọọni ti kọkọ gbe Olori Mariam, Elizabeth ati Tobi Phillips niyawo.