You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ẹgbẹ́ Afẹ́nifẹ́re kìlọ̀ nípa àbá tó ń pè fún sísọ àjèjì di ọmọ onílùú ní Naijiria
Ẹgbẹ to n ri si ọrọ Yoruba ni Naijiria, Afẹnifẹre, ti kilọ nipa aba kan to n pe fun sisọ awọn ajeji to ba ti gbe niluu kan fọdun mẹwaa di ọmọ ilu naa.
Afẹnifẹre sọ pe eyi le da rogbodiyan ẹya kan si ikeji silẹ.
Ikilọ yii n waye latari aba kan ti wọn n gbeyẹwo nile igbimọ Aṣoju-ṣofin Naijiria lọwọ, eyi ti wọn pe ni 'Indigene Bill'.
Aba naa to n pe fun sisọ ajeji to ba gbe niluu kan fun ọdun mẹwaa di ọmọ ibẹ ni wọn lo n waye lati tun awọn apa kan ofin Naijiria ti wọn ṣe ni 1999 ṣe.
Igbakeji Abẹnugan ile igbimọ naa, Benjamin Okezie Kalu pẹlu awọn aṣofin mẹfa mi-in ni wọn n ṣagbatẹru aba ọhun.
Ọjọruu, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹta ọdun 2025 yii ni aba naa la ipele agbeyẹwo keji, ( Second reading) kọja.
Kí ni àbá yìí dúró fún gan-an?
Gẹgẹ bi alaye awọn to n ṣagbatẹru aba yii, ohun to wa fun ni lati fun awọn eeyan ti wọn ti gbe lagbegbe kan fọdun mẹwaa lai kuro nibẹ ni ẹtọ ti awọn ọmọ ilu naa gan-an ni.
Bakan naa ni aba yii yoo tun jẹ kawọn obinrin to fẹ ọmọ ilu naa lọkọ lẹtọ kan naa.
Bi wọn ba buwọ lu aba ọhun, to di ofin, yoo mu awọn ayipada kan ba ofin to de jijẹ ọmọ oniluu, iyẹn nipa ki eeyan maa gbe nibi kan.
Yoo tun mu ayipada ba abala awọn obinrin to fẹ ọkọ niluu naa.
Eyi yoo yatọ si ilana ti Yoruba gbagbọ, ti i ṣe jijẹ ọmọ ibi kan nipaṣe ẹ ki wọn bi eeyan lati ẹbi tati iran kan nibẹ.
Ẹhonu Afẹnifẹre
Atẹjade kan ti Jare Ajayi, Akọwe Apapọ ẹgbẹ Afẹnifẹre fi sita, ṣalaye pe aba yii tako bi eeyan ṣe le jẹ ọmọ oniluu.
Akọwe Afẹnifẹre ṣalaye pe ọna mẹrin ni awọn awujọ to laju maa n pin jijẹ ọmọ oniluu si.
Awọn naa ni: Awọn ọmọ oniluu gangan, awọn araalu, awọn olugbe ati awọn alejo.
Ajayi sọ pe awọn alejo le pada gba iwe igbeluu titi aye nilana ofin.
Ṣugbọn jijẹ ọmọ oniluu gbọdọ jẹ nipa awọn alalẹ, iṣẹmbaye ati ki eeyan ni gbongbo gẹgẹ bii ọmọ ibilẹ ti wọn fi ori rẹ sọlẹ sibẹ.
"Afenifere n ke si ile igbimọ aṣofin agba lati gbagbe nipa aba yii, ki wọn gbaju mọ bi wọn yoo ṣe tun Naijiria to lọna ti yoo mu ki ẹkun kọọkan mọ ibi to ti wa, ti yoo si fun wọn ni ominira labẹ ilana iṣejọba ti wọn da silẹ funra wọn."
Bẹẹ ni apa kan atẹjade naa ka.
Ẹgbẹ Afẹnifẹre ko ṣai sọ pe ifẹ inu awọn kan lati gbooro si i, ki wọn si le jẹ gaba le awọn mi-in lori ninu oṣelu lo fa aba yii.
Afẹnifẹre kilọ pe aba naa ko le ṣe daadaa fun awọn ilu.
Wọn ni yoo wulẹ dana ogun silẹ bi ija ẹlẹyamẹya ṣe n waye lawọn ilu kan ni Naijiria bayii ni, nibi ti awọn ọmọ oniluu ti n ba awọn ajeji to waa gbe niluu wọn ja.