Àna ààrẹ Mugabe ń béèrè fún dúkìá tó tó $80m àti àwọn nǹkan míì lẹ́yìn tí ọmọ ààrẹ kọ̀ọ́ sílẹ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Igbeyawo Ọmọbìnrin ààrẹ orílè-èdè Zimbabwe nigba kan, Robert Mugabe, to tuka, ti fẹ́ da nǹkan silẹ si í lọrun bayii.
Oṣù Kẹta ni Bona Mugabe, ẹni ọdún mẹtalọgbọn, ja iwe ikọsilẹ fun ọkọ rẹ, Simba Chikore, lẹyin ọdún mẹ́sàn-àn.
Awakọ̀ baalu ni Ọgbẹni Chikore tẹ́lẹ̀.
Ninu iwe ile ẹjọ́ to tẹ BBC lọ́wọ́, lo ti fi oju han pe Chikore n beere fun ọpọlọpọ dukia, tó ni awọn kojọ ninu ìgbéyàwó ọlọdun mẹ́sàn-àn náà.
Lara àwọn nnkan to n beere ni ilẹ̀ ńláńlá, ọkọ, ọkọ̀ bọginni, ati owo tabua.
Ọgbẹni Chikore n fẹ́ ki ile ẹjọ́ fún un lara ile màrúndínlọ́gbọ̀n ti àpapọ̀ owo rẹ tó ọgọrin mílíọ̀nù Dọla. O tun fẹ́ awọn irinṣẹ́ ti wọn n lo fun iṣẹ́ agbẹ.
O ni kekere ni àwọn nnkan ti oun béèrè fun ninu dukia iyawo oun.
Ikọsilẹ yii si lo ti ṣí oju awọn ọmọ orílè-èdè Zimbabwe, si ọrọ̀ ti ẹbi Mugabe ní, ti ọpọ si n beere pe báwo ni wọ́n ṣe kó ọrọ̀ naa jọ.
Chikore sọ pe ẹ̀bùn, àti owó iṣẹ́ ti àwọn ṣe fun ààrẹ Mugabe, to fi mọ́ ogún tó fi silẹ nigba to kú lọ́dún 2019, làwọn fi ko ọrọ̀ naa jọ.
Iroyin sọ pe Robert Mugabe ko fi ìwé ìpín ogún silẹ nigba to ku, ti oun fúnra rẹ ko si ni dukia kankan.
Ṣùgbọ́n ṣá, ẹni to jẹ agbẹnusọ fun Mugabe nigba ayé rẹ̀, George Charamba, sọ pe irọ patapata ni pe tọkọtaya, Síbà Chikore ati Bona Mugabe, ni ilẹ̀ oko mọkanlelogun.
O ni ìjọba lo ni gbogbo ilẹ̀, ti awọn eeyan yá lati fi dá oko.












