Portable fi ẹ̀ṣẹ́ fọ́ gbajúmọ̀ òṣèré sinimá, Charles Okocha lẹ́nu ní ìdíje ẹ̀ṣẹ́ kíkàn

Yoruba bọ̀, wọn ni, ẹni ija o ba lo n pe ara rẹ ni ọkunrin.

Gbajumọ akọrin takasufe, Portable, ati oṣerekunrin, Charles Okocha, jọ fija pẹẹta ni ọjọru, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kejila ọdun 2023, nigba ti wọn fi ẹṣẹ kikan wọya ija

Ija naa to waye ni eti okun Landmark, ni agbegbe Victoria Island nipinlẹ Eko, ni iroyin sọ pe o bẹrẹ ni nnkan bi aago kan oru.

Bi ogoji iṣẹju si ni wọn fi ja.

Kilo fa ija laarin gbajumọ ilu meji?

Ṣaaju ki ija naa to waye, ni ede aiyede kan ti kọkọ waye laarin awọn gbajumọ mejeeji lori ọrọ owo.

Ni bi ọsẹ diẹ sẹyin ni Portable fi igbe ta pe Okocha yan ounjẹ, lẹyin ti iṣẹ jọ da wọn pọ.

Ninu fidio kan to fi si ori ayelujara Instagram rẹ, Portable fi ẹsun kan pe ogoji miliọnu Naira to yẹ ki awọn jọ pin lori ipolowo ọja kan ti wọn jọ ṣe.

Portable sọ pe dọgba-dọgba lo yẹ ki awọn pin owo naa, ṣugbọn”nisẹ ni Charles Okocha ko pupọ ninu owo naa sapo, to si fun oun ni miliọnu marun-un pere”.

Eyi lo bi akọrin naa ninu to fi jẹjẹ pe oun yoo fi iya jẹ oṣerekunrin naa nibikibi ti awọn ba ti pade.

Isọrọ nigbesi, ko pẹ ti Portable fi idunkooko sita, ni Okocha naa sọ pe oun ni oun gba iṣẹ ipolowo ọja naa, ti oun kan pe Portable lati kun oun lọwọ lori rẹ.

“Lati Eko ni mo ti gbe Portable wa si ilu Abuja ninu baalu, ti mo si fun ni miliọnu marun-un.

O ni awọn ko fi ọwọ si iwe adehun kankan lori bi wọn o ṣe pin owo. O ni oun kan fun Portable ni iye ti oun ro pe o tọ́ si i.

Bawo ni ija ẹṣẹ kikan naa ṣe lọ?

Nitori bo ṣe jẹ pe awọn mejeeji lo leri lati fi iya jẹ ẹnikeji, boya oun lo mu ileeṣẹ kan to n mojuto ẹṣẹ kikan nipinlẹ Eko, lati ba wọn ṣeto ija.

Iroyin sọ pe igba mẹrin ni wọn fi ẹ̀ṣẹ́ ja, ti ẹni kọọkan wọn si gbiyanju lati bori ẹnikeji.

Ni abala keji ninu ija naa, fidio kan to wa lori ayelujara ṣafihan bi Okocha ṣe fi ẹsẹ lu Portable ni alubolẹ. Ọpẹlọpẹ alamojuto ija naa to sare ko si wọn laarin.

Ni abala kẹta, awọn gbajumọ mejeeji gbiyanju lati bori, amọ nigba ti yoo fi di abala kẹrin, o jọ pe o ti rẹ awọn mejeeji. Ṣugbọn bo ṣe rẹ wọn to, ẹṣin kii kọ ere asarele ni Portable fi ṣe.

Awọn ẹsẹ to ko bo alatako rẹ ni wọn fi kede rẹ gẹgẹ bi olubori, bo tilẹ jẹ pe ko lo awọn ilana TKO tabi KO ti awọn akọṣẹmọṣẹ to n ja ẹṣẹ, ma n lo.

Ni ipari ija naa, Portable ni wọn gbe bẹliti olubori kọ ni ọrun.

A ko le e ṣọ boya ija wọn naa jẹ ojulowo, tabi ere idaraya fun awọn ololufẹ wọn.