Ẹbùn ọdún Kérésìmesì tirẹ̀ pọ̀ju tèmi lọ dá wàhálà sílẹ̀:àbúrò fà ìbínú yọ, tó sí yìnbọn pa ẹ̀gbọ́n

Awọn ọdọkunrin meji kan to jẹ ọmọ iya kanna ti wa lahamọ ọlọpaa lẹyin ti wọn yinbọn pa ẹgbọn wọn obinrin nitori ọrọ ẹbun ọdun Keresimesi.

Arabinrin ẹni ọdun mẹtalelogun yi la gbọ pe aburo rẹ ọkunrin yinbọn lu laya lasiko to wa pẹlu ọmọ ikoko oṣu mẹwa rẹ to gbe sinu kẹkẹ ti wọn fi n yi ọmọ ka.

Ileeṣẹ ọlọpaa nilu Florida lorileede America lo fidi ọrọ yi mulẹ.

Lẹyin to yinbọn lu ẹgbọn rẹ ni ẹgbọn tiẹ naa lọkunrin fa ibọn tiẹ naa yọ to si yin lu gẹgẹ bi ileeṣẹ ọlọpaa adugbo Pinellas ti ṣe ṣalaye.

Wọn fi kun ninu ọrọ wọn pe arinyanjiyan lori ẹni to gba ẹbun julọ laarin wọn lo ṣokunfa iyinbọn mọ araẹni.

Bob Gualtieri to jẹ ọga ọlọpaa sọ fawọn akọroyin pe ẹgbọn to dagba ninu awọn ọdọmọkunrin yi,ẹni ọdun mẹẹdogun salọ lẹyin to yinbọn tan to si sọ ibn naa nu.

Eyi aburo ẹni ọdun mẹrinla la gbọ pe wọn gbe lọ sile iwosan to si ti n gba itọju lọwọ.

Bi ara rẹ ba ya, wọn yoo fi si ahamọ gẹgẹ bi ọlọpaa ti ṣe ṣalaye.

Awọn olupẹjọ lagbegbe naa yoo ṣe agbeyẹwo ẹjọ ọhun lati le mọ boya wọn yoo pe arakunrin yi lẹjọ gẹgẹ bi agbalagba lori ẹsun pe o pa ẹgbọn rẹ.

Wọn gbe ẹgbọn rẹ yi lọ si ile iwosan nibi tawọn oṣiṣẹ ilera ti sọ pe o dagbere faye gẹgẹ bi ọga ọlọpaa Gualtieri ṣe sọ.

O ṣalaye pe arabinrin yi to bi ọmọ meji ko ribi mi daada mọ ko to jade laye ṣugbọn ọmọ to gbe sinu kẹkẹ ọmọde nigba ti iṣẹlẹ yi waye ko farapa.

Ọwọ ọlọpaa pada tẹ aburop rẹ ẹni ọdun mẹẹdogun to salọ ti wọn yoo si fi ẹsun igberolati ṣekupani kan ati ẹsun fifọwọ bo ẹri.