You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Aláàfin Oyo tuntun Ọba Akeem Owoade dé Adé Sango ní Koso, ìlú Oyo mì tìtì
Ori to maa de ade ko ni ṣai dade, bẹẹ ni ọrọ ri pẹlu Alaafin ti ilu Oyo tuntun, Ọba Akeem Abimbola Owoade, to de ade Sango ti wọn tun maa n pe ni ade iṣẹmbaye lonii ọjọ Abamẹta ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu Kẹta yii.
Eyi waye lẹyin ti Kabiyesi Owoade kuro ni Ipebi lọjọ Ẹti ọjọ kejidinlọgbọn oṣu yii nibi ti ori-ade naa ti wa fun bii ọjọ mọkanlelogun.
Gẹgẹ bii alakalẹ aṣa ati iṣe fun ẹnikẹni to ba fẹ jẹ Alaafin, Koso ni Ọba Owoade lọ sun lalẹ ana ọjọ Ẹti.
Nibẹ si ni kabiyesi ti dade Sango lowurọ oni ọjọ Abamẹta ti i ṣe ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu yii.
Ni Koso ni wọn ti ṣe gbogbo eto ibilẹ to yẹ ki wọn o ṣe ṣaaju igba ti kabiyesi yoo dade Sango ki Ọba Owoade to de ade naa.
Alaafin Owoade rin lati Koso gba aarin ilu Oyo pẹlu ero biba lẹyin rẹ pada lọ si aafin Oyo lẹyin to de ade naa tan.
Lẹyin ti ori ade naa de ade yii tan ni awọn araalu ilu ṣẹṣẹ bẹrẹ si ni maa pe e ni kabiyesi.
''Kara o le'' ni wọn n ki Alaafin tuntun tẹlẹ, ki Ọba Owoade to de ade iṣẹmbaye lonii ọjọ Satide.
Ohun ti a gbọ ni pe Alaafin Akeem Owoade ko gbọdọ de Koso mọ titi ti yoo fi jade lẹyin to de ade Sango tan nibẹ.
Ọba Owoade ni Alaafin Oyo ẹlẹẹkẹrindinlaadọta ti yoo jẹ.
Aláàfin Owoade kéde kókó ohun tí yóò ṣe lórí ìtẹ́
Ẹwẹ, Alaafin Ọyọ tuntun, Oba Akeem Abimbola Owoade ti fi ọrọ lede nipa awọn afojusun rẹ lori aleefa.
Atẹjade kan ti Bode Durojaiye, tii se adari ikede ati ipolongo fun Ọba Owoade, fisita fawọn akọroyin lo sisọ loju ọrọ yii.
Ọba Owoade ni ọkan pataki lara awọn akanṣe iṣẹ ti oun yoo ṣe lori itẹ ni lati ri daju pe awọn ọdọ to n fi ẹsẹ gbalẹ kiri, lẹyin ti wọn ti kẹkọọ jade lai ri iṣẹ, yoo kuro ni ẹgbẹ alaini iṣẹ.
Bakan naa ni Kabiyesi fi kun ọrọ rẹ wi pe, oun yoo ṣe agbekalẹ idanilẹkọ nipa iṣẹ ọwọ fun awọn ọdọ.
Alaafin fi idi rẹ mulẹ wi pe, awọn akẹkọọjade kan ti wọn ti kẹkọọ gboye 'Bsc tabi HND' yoo ri iranlọwọ gba lati kọ nipa aabo ori itakun ayelujara, 'Cyber Security', ki wọn le ni anfani lati lọ ṣiṣẹ ni oke okun.
Alaafin Owoade fi kun ọrọ rẹ wi pe, oun yoo tẹsiwaju ni ibi ti Alaafin ana, Oba Adeyemi ti ṣiwọ iṣẹ, fun idagbasoke ọdun Ṣango ati Ọranmiyan.
Bakan naa ni atẹjade naa tọka si pe awọn opo yoo ri iranlọwọ gba fun igbeaye irọrun.
Idagbasoke eto ilera ilu Ọyọ naa ko gbẹyin gẹgẹ bi Ọba alade naa ṣe n gbero lati ke si awọn ẹlẹyinju aanu lati oke okun lati ṣe atilẹyin fun ijọba rẹ.
Ọba Owoade yoo tun riidaju wi pe gbogbo awọn nnkan iṣẹmbaye ilu Ọyọ ti wọn ti ko lọ si ilẹ Gẹẹsi lati ọdun 1895 ni yoo di dida pada.
O fikun pe awọn ohun isembaye naa yoo pada pẹlu ere owo gẹgẹ bi o ṣe n ṣe ileri lati bẹ awọn agbekalẹ ohun atijọ wo.