Àgbà òṣèré míì ń ṣàìsàn, ó nílò àdúrà yín - Foluke Daramola

Agba osere tiata miran ni wọn ti kede pe o ti wa nidubulẹ aisan, to si nilo adura gidigidi.

Onitọhun ni arabinrin Adenike Adegboye, ti ọpọ eeyan mọ si iya ìbejì ọmọ araye le, ẹni to ti kopa ninu ọ̀pọ̀lọpọ̀ ere tiata sẹ́yìn.

Osere tiata lobinrin, Foluke Daramola lo fi ikede yii sita loju opo Instagram rẹ.

Nigba to lọ sabẹwo si agba osere naa nile iwosan to ti n gba itọju, Foluke wa rọ àwọn ọmọ Naijiria lati ranti Mama naa ninu adura wọn.

Iya ibeji ọmọ araye le náà lo tí ru hangogo ninu fidio tí Foluke gbe síta, ti ọmọ rẹ rẹ obìnrin kan si wa pẹlu rẹ.

Ninu alaye ti Foluke ṣe ninu fidio náà, ó salaye pe obìnrin naa n ronu pupọ ju, lo fa aisan si i lara.

Ó wa rọ àwọn ọmọ Naijiria lati maa gbadura fún un, ki ara rẹ le tete ya.

Bákan náà lo tun bẹ̀rẹ̀ fún iranwọ owo lati ọdọ ọmọ Naijiria fun itọju agba osere tiata yii.

Lẹyin eyi ni Foluke Daramola wa gbe ẹ̀bùn lorisirisi ati owo fun ìyà ìbejì ọmọ araye le, tó ń ṣàìsàn naa.

Ta ni Iya Ibeji ọmọ araye le to n saisan?

Arabinrin Nike Gboye, ta tun mọ si Iya ibeji ọmọ araye le, lo ti le ni ẹni ọgọta ọdun.

Osere tiata naa ni ọkọ rẹ, lo mu u wọnu agbo tiata.

Orukọ ọkọ rẹ naa ni Bisi Gboye, ti onitọhun si ti jẹ Ọlọrun nipe.

Ọmọ bibi ilu Okuku ni Iya ibeji ọmọ araye le, o si tun jẹ ọmọbabinrin nilu ọhun.

Isẹ olukọ ni gbajumọ osere tiata to n saisan naa n se tẹlẹ, nibi to ti pade ọkọ rẹ, ki wọn to dijọ bẹrẹ ere tiata.

Lara awọn gbajumọ ere tiata ti Nike Gboye tí kopa sẹ́yìn ninu rẹ ni Ìyá Àgan, Ọya Gbàjarè, Ẹ̀kọ ìbílẹ̀, aye obìnrin ati omo araye le.