You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù alápẹ̀rẹ̀ Nàìjíríà, D’Tigress lu Australia ní Olympics pẹ̀lú 75 sí 62
Ikọ agbabọọlu alapẹrẹ awọn obinrin Naijiria, D’Tigress ti bẹrẹ ikopa wọn ni idije Olympics Paris 2024 lọwọ ẹrọ pẹlu gbigbo ewuro si ẹnu awọn akẹgbẹ wọn lati orilẹede Australia.
Australia lo wa ni ipo kẹta pepele igbelewọn awọn ikọ agbabọọlu alapẹrẹ awọn obinrin lagbaye.
Ninu ifẹsẹwọnsẹ wọn to waye lọjọ Aje ni ilu Lille ikọ D’Tigress fi ajulọ han Australia pẹlu apẹrẹ marundinlọgọrin si mejilelọgọta.
Esi Ifẹsẹwọnsẹ naa mu ko jẹ igba keji ti ikọ D’Tigress yoo maa bori ifẹsẹwọnsẹ ni idije Olympics. Ọdun 2004 ni wn kọkọ ṣe bẹẹ nigba ti wọn fi ajulọ han South Korea pẹ̀lu apẹrẹ mejidinlaadọrin si mẹrinlelọgọta.
Amọṣa igba akọkọ niyi ti wọn yoo maa bori ninu ifẹsẹwọnọsẹ akọkọ yoowu ti wọn yoo gba ni idije Olympics.
Fun Australia, igba keji ni ṣisẹ n tẹle ree ti wọn yoo maa jẹ iya ajẹpọnula. Tẹlẹ nṣe ni wọn maa n ṣe awure iya fun awọn orilẹede yoowu ti wọn ba koju.
Pẹlu esi ifẹsẹwọnsẹ yii, ikọ D’Tigress ti ọs orilẹede Naijiria di orilẹede akọkọ ni Afirika ti yoo bori Australia ni idije ife yẹ agbaye ati Olympics.