Ó ṣéese kí àwọn tó ń lo 'X' bẹ̀rẹ̀ sí ní san owó láìpẹ̀- Elon Musk

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Elon Musk ti da laba pe o ṣeeṣe ki awọn eeyan to n lọ ayelujara X ti ọpọ mọ si Twitter bẹrẹ si ni ma san owo lati le lo ayejuara naa.
O sọ eleyi lasiko to n ba Olotu ijọba Israel, Benjamin Netanyahu sọrọ. O ni si san owo nikan ni ọna abayọ lati gbe ogun ti awọn ipenija ayelujara naa.
“A n gbinyanju lati mu aba sisan owo kekere lososu fun awọn onibara wa.”
Ileeṣẹ BBC kan si X fun alaye lẹkunrẹrẹ sugbọn a ko ti gba idahun lati ileeṣẹ naa.
A ko ti le sọ boya ọrọ ẹnu lasan ni tabi Musk n fi akoko naa kede igbesẹ rẹ tuntun fun onibara rẹ.
Musk ti sọm saaju pe ọna abayọ lati gbe ogun ti awọn ayederu eeyan lori ayelujara ni lati ma gba owo fun idanimọ lọwọ awọn onibara.
Lati igba to ti gba isakoso Twitter lọdun to kọja, lo ti n pe fun sisan owo awọn eeyan to n lo opo naa lati le opo to jẹ ojulowo.
O ti bẹrẹ si ma fun awọn eeyan to san owo loju opo ni ọpọlọpọ anfani sugbọn sibẹsibẹ awọn eeyan mi si le lo Twitter lọfẹ
Lorilẹede Amẹrika, X n gba owo toto dọla mẹjọ, Awọn owo ti orilẹede kankan san yatọ si arawọn bayi.












