Ìjọba ṣe àfikún ọjọ́ tí ìforúkọsílẹ̀ fún ètò ẹ̀yáwó àwọn akẹ́kọ̀ọ́ yóò parí, wo bí o ṣe lè jànfààní rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images/Bola Ahmed Tinubu/X
Ajọ NELFUND to n ri si eto ẹyawo fawọn akẹkọọ ti ṣe afikun ọjọ ti iforukọsilẹ fun eto ẹyawo awọn akẹkọọ fun saa igbẹkọ 2025/2026 yoo pari.
Ọjọ kọkanlelọgbọn oṣu Kinni yii lo yẹ ki iforukọsilẹ naa pari tẹlẹ, ṣugbọn ajọ NELFUND ti sun ọjọ naa si ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu Keji to n bọ bayii.
Agbẹnusọ ajọ NELFUND, Oseyemi Oluwatuyi, ṣalaye pe ajọ naa ti ṣi oju opo iforukọsilẹ fun apa keji eto ẹyawo naa lọjọ kẹtalelogun oṣu Kẹwaa ọdun 2025 to kọja.
Ọga agba ajọ NELFUND, Akintunde Sawyerr, ṣalaye ninu atẹjade kan ti ajọ naa fi sita wi pe ijọba ṣe afikun ọjọ ti iforukọsilẹ naa yoo pari lati le fawọn akẹkọọ lanfaani lati pari iforukọsilẹ wọn.
Ọgbẹni Sawyerr tun sọ pe afikun ọjọ ti iforukọsilẹ naa yoo pari yoo tun jẹ ki oniruuru awọn akẹkọọ jẹ anfaani eto ẹyawo naa.
Ọga agba ajọ NELFUND sọ pe nigba ti ajọ naa ri pe awọn akẹkọọ kan nilo akoko sii lati pari iforukọsilẹ wọn fun eto ẹyawo akẹkọọ lo jẹ kawọn ṣe afikun ọjọ ti iforukọsilẹ naa yoo pari.
Ọgbẹni Sawyerr ni afikun ọjọ ti eto naa yoo pari yoo tun fun gbogbo akẹkọọ to koju oṣunwọn fun ẹyawo naa lati janfaani eto ọhun.
O wa rọ gbogbo awọn akẹkọọ ti ko tii pari eto iforukọsilẹ wọn fun eto ẹyawo NELFUND lati lo asiko yii pari rẹ.
Bakan naa ni Sawyerr tun rọ awọn akẹkọọ ti ko tii forukọsilẹ lati ṣe bẹẹ lasiko yii.
Alaye lori ajọ NELFUND ati bi o ṣe le janfaani eto ẹyawo fawọn akẹkọọ
Ajọ NELFUND jẹ ajọ ti ijọba Bola Ahmed Tinubu gbe kalẹ lọdun 2023 lati maa ya awọn ọmọ ile ẹkọ giga ni Naijiria lowo lọna ati san owo ẹkọ wọn.
Labẹ eto naa, awọn akẹkọọ yoo san owo ti wọn ba ya lọwọ ijọba pada amọ wọn ko ni san ele kankan lori rẹ.
Afojusun ajọ naa ni lati ri pe gbogbo araalu lanfani lati kawe nile ẹkọ giga ni Naijiri lai si idiwọ fun wọn latari airi owo san.
Ajọ NELFUND sọ pe ko din ni N161.97bn ti awọn ti ya akẹkọọ 864,798 lati ile ẹkọ giga 263.
Ọgbẹni Sawyerr ni akẹkọọ 1,361,011 kaakiri orilẹede Naijiria ni wọn ti forukọ silẹ fun eto ẹyawo naa bayii.
Lati fi orukọ silẹ fun eto ẹyawo yii, lọ soju opo NELFUND ni https://nelf.gov.ng lati forukọsilẹ fun eto ẹyawo akẹkọọ tirẹ.
Wa fi orukọ rẹ ati orukọ ile ẹkọ rẹ silẹ loju opo iforukọsilẹ naa.
Lẹyin naa ni waa tun fi nọmba igbaniwọle rẹ gẹgẹ bi akẹkọọ soju opo naa.
Bakan naa o nilo lati fi awọn iwe ẹri kan soju opo iforukọsilẹ ọhun.
Amọ ṣa, ri daju pe o ka awọn nnkan to yẹ ki o mọ loju opo naa nipa eto ẹyawo ọhun ki o to dawọle.














