Ẹ̀yin oníṣẹ̀ṣe, ẹ má fi àkókò yín ṣòfò lọ sílé ẹjọ́ lórí ìsìnkú Awujale - Ìjọba ìpínlẹ̀ Ogun

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ìjọba ìpínlẹ̀ Ogun ti ní òun ti gbáradì láti kojú gbogbo ẹjọ́ táwọn ẹlẹ́sìn Ifa, ìyẹn International Council for Ifa Religion (ICIR) fẹ́ pe ìjọba lórí ìlànà tí wọ́n gbà sin òkú Awujale ti ilẹ̀ Ijebu, Ọba Sikiru Kayode Adetona.

Ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù Keje, ọdún 2025 ni Ọba Adetona darapọ̀ mọ́ àwọn babańlá rẹ̀ tí wọ́n sì sin-ín ní ìlànà ẹ̀sìn Islam èyí tó fa awuyewuye káàkiri ilẹ̀ Yorùbá.

Lásìkò ètò ìsìnkú ọba náà ni àwọn ìròyìn kan gba orí ayélujára pé, wọn kò jẹ́ káwọn oníṣẹ̀ṣe kópa níbi ètò ìsìnkú ọba ọ̀hún.

Agbẹjọ́rò àti alákòóso àwọn oníṣẹ̀ṣe ní ìpínlẹ̀ Ogun, Olóyè Ifasola Opeodu tó tún jẹ́ Olúwo ti ìlú Iperu Remo fìdí rẹ̀ múlẹ̀ fún BBC News Yorùbá pé wọ́n lé àwọn oníṣẹ̀ṣe níbi ètò ìsìnkú ọba náà.

Ó ní àwọn tó lé àwọn oníṣẹ̀ṣe kúrò níbi ètò ìsìnkú náà ti ṣẹ̀ sí òfin ìjọba ìpínlẹ̀ Ogun àti pé àwọn máa gba ilé ẹjọ́ lọ lórí ọ̀rọ̀ náà.

Ifasola fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé yàtọ̀ sí pé wọ́n lé àwọn èèyàn náà, wọ́n tún lo àwọn ọmọ ogun láti fi lé wọn kúrò níbi ètò ìsìnkú ọ̀hún.

"Gbogbo àwa oníṣẹ̀ṣe yóò gba ilé ẹjọ́ lọ"

Ó ní kò sí nǹkankan tó ṣẹlẹ̀ ju pé wọ́n tàpá sí òfin ti ìjọba ìpínlẹ̀ Ogun gbé kalẹ̀ lórí àwọn Ọba àtàwọn olóyè lọ́dún 2021.

"Gbogbo àwọn oníṣẹ̀ṣe ilẹ̀ Yorùbá, tó fi mọ́ àwọn ti ìpínlẹ̀ Ogun àti Ijebu-Ode tí ọ̀rọ̀ yìí ti ṣẹlẹ̀, a máa lọ sílé ẹjọ́ láti ṣe àmúlò òfin yẹn gangan, láti lè kojú ìjà sí gbogbo àwọn tó ṣe nǹkan tí wọ́n ṣe yẹn nítorí èèwọ̀ ni, ó dẹ̀ lòdì sí òfin.

"Nǹkan tí òfi sọ ni pé ètò ìṣẹ̀ṣe, ìlànà ìṣẹ̀ṣe àti àṣà w ani wọ́n gbọdọ̀ fi jẹ ọba , òhun sì ni wọ́n gbọ́dọ̀ fi sin ọba.

Ó dẹ̀ wà nínú òfin yẹn wí pé wọn kò gbọdọ̀ yọ ohunkóhun tàbí gé ohunkóhun kúrò lára ọba àmọ́ gbogbo ètùtù ìbílẹ̀ tó bá yẹ kí wọ́n ṣe ni wọ́n gbọdọ̀ ṣe láti ìgbà tí ọba bá ti wàjà.

"Wọ́n gbọ́dọ̀ ṣe ètùtù náà sí ara òkú ẹ̀hún kí wọ́n tó sin-ín."

Ní òpin ọ̀sẹ̀ tó kọjá yìí ni ààrẹ ICIR, dókítà Fayemi Fakayode àti Ifasola Opeodu tún pe ìpàdé pẹ̀lú àwọn akọ̀ròyìn ní ìlú Ibadan níbi tí wọ́n ti bu ẹnu àtẹ́ lu sínsin Awujale ní ìlànà ẹ̀sìn Islam tí wọ́n sì ní ó jẹ́ títẹ àṣà àti òfin lójú mọ́lẹ̀.

Fakayode ní abala ìwé òfin oyè jíjẹ ìpínlẹ̀ Ogun là á kalẹ̀ pé ṣíṣe ẹ̀tọ́ lórí àwọn ọba ní ìlànà ìbílẹ̀ ṣaájú tí àwọn ẹ̀sìn míì.

Wọ́n ní àwọn máa ṣe àrídájú rẹ̀ pé àwọn mú àtúnṣe bá àṣà tuntun yìí, tí àwọn sì máa dá ṣíṣe ojúṣe fáwọn ọba gẹ́gẹ́ bí àṣà àti ìṣe ṣe ti là á kalẹ̀ ní ilẹ̀ Yorùbá nípa fífun àwọn ọba ní ẹ̀yẹ ìkẹyìn bó ṣe tọ́.

'Ìjọba ti wà ní sẹpẹ́ láti kojú àwọn oníṣẹ̀ṣe lórí ẹjọ́ náà'

Ẹ̀wẹ̀, Kọmíṣánnà fún ètò ìdájọ́ ní ìpínlẹ̀ Ogun, Sina Ogungbade ti wá sọ pé fífi àkókò àti owó ṣòfò ni yóò jẹ́ táwọn oníṣẹ̀ṣe bá ní àwọn ń lọ sílé ẹjọ́.

Ogungbade ní ìjọba ti wà ní sẹpẹ́ láti kojú àwọn oníṣẹ̀ṣe lórí ẹjọ́ náà.

Ó tẹmpẹlẹmọ pé ohun tí òfin sọ ní ìjọba tẹ̀lé nípa fífi ààyè gba láti jẹ́ kí wọ́n sin Ọba Adetona ní ìlànà ẹ̀sìn Islam, tó jẹ́ ẹ̀sìn tí ọba náà ń ṣe kó tó jáde láyé.

"Tí wọ́n bá fẹ́ pe ẹjọ́, mà á ní wọ́n káàbọ̀ àmọ́ mò ń fún wọn ní àmọ̀ràn lọ́fẹ̀ẹ́ láti má ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí ó máa jẹ́ àfihàn pé wọn kò mọ ohun tí òfin wí lórí ọ̀rọ̀ náà. Ìgbésẹ̀ wọn kò ní bá nǹkankan dé rárá."

Ogungbade wòye pé bí Awujale tó wàjà àti àwọn ẹbí rẹ̀ ṣe gbèrò láti sin òkú rẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà ẹ̀sìn tó ń sìn kò ní nǹkankan ṣe pẹ̀lú ìṣẹ̀ṣẹ àti pé gbogbo èèyàn ló ní ẹ̀tọ́ láti yan ẹ̀sìn tí wọ́n bá fẹ́ máa sìn.

Ó fi kun pé ìjọba gbé ìgbésẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà òfin láti sin ọba náà ní ìlànà tó si sọ kalẹ̀ àti báwọn ẹbí rẹ̀ ṣe fẹ́.

Kí ni òfin sọ nípa ìlànà ìsìnkú àwọn Ọba ní ìpínlẹ̀ Ogun?

Ní ọdún 2021 ni ìjọba ìpínlẹ̀ Ogun gbé òfin kan kalẹ̀ tí wọ́n pè ní "Obas and Chiefs Law of Ogun State 2021" lójúnà àti bomi pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ aáwọ̀ tó máa ń wáyé lórí ìfinijoyè àti ìsìnkú àwọn ọba tó máa ń wáyé ní ìpínlẹ̀ náà.

Ní pàtàkì jùlọ, àwọn èyí tó máa ń wáyé láàárín àwọn afọbajẹ, àwọn ẹlẹ́sìn mìíràn àtàwọn ẹbí ọba.

Ohun tí òfin náà gbé lórí jùlọ ni ìlànà oyè jíjẹ àti ìsìnkú àwọn ọba ní ìpínlẹ̀ náà.

Abala kẹjọ òfin náà là á kalẹ̀ pé kò sí ẹnikẹ́ni tó gbọ́dọ̀ fi tipátipá mú ọba tàbí olóyè kankan wọ ẹgbẹ́ ìmùlẹ̀ tàbí ẹgbẹ́kẹ́gbẹ́ yòówù tí kò bá fẹ́.

Abala Karùndínlọ́gọ́ta òfin náà ni wọ́n ti ṣe àlàkalẹ̀ bí wọ́n ṣe lè sin àwọn ọba àti gbogbo nǹkan tó rọ̀ mọ́.

Òfin náà sọ pé òkú ọba ní ẹ̀tọ́ láti jẹ́ sínsin ní ìlànà àṣà àti ìṣe ìlú náà níwọ̀n ìgbà tí kò bá ti ní ọwọ́ yíyọ ẹ̀yà ara èèyàn tàbí jíjẹ ẹ̀yà ara èèyàn lọ́wọ́.

Bákan náà ni wọ́n ní àwọn ọba ní àǹfàní láti sọ ìlànà tí wọ́n fẹ́ kí wọ́n fi sin àwọn ṣáájú kí ọba bẹ́ẹ̀ tó wàjà yálà ní ìlànà ẹ̀sìn mùsùlùmí, ìgbàgbọ́ tàbí ìṣẹ̀ṣe àti pé ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ tàpá sí àlàkẹlẹ̀ àwọn ọba náà.

Òfin náà fi kun pé ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ dí àwọn ẹbí ọba tó bá wàjà lọ́wọ́ láti sin òkú wọn ní ìlànà tó bá wù wọ́n.

Ẹnikẹ́ni tó bá tàpá sáwọn ìlànà yìí gẹ́gẹ́ bí òfin ni ó ṣeéṣe kó fi ẹ̀wọ̀n ọdún méjì tàbí ọdún kan gbára láìsí àǹfàní sísan owó ìtanràn.

Gómìnà Dapo Abiodun níbi ètò ìsìnkú Ọba Adetona sọ pé ìsìnkú àwọn ọba yóò máa wáyé ní ìlànà ẹ̀sìn tí wọ́n bá ń sìn gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú òfin ìpínlẹ̀ Ogun.