Afẹ́fẹ́ gáàsì fa ìbúgbàmù - èèyàn mẹ́ta kú, èèyàn 300 farapa

Ènìyàn mẹ́ta ti pàdánù ẹ̀mí wọn, tí ọ̀pọ̀ si farapa níbi afẹ́fẹ́ gáàsì tó bú gbàmù ní orílẹ̀ èdè Kenya.

Èèyàn tó fẹ́ẹ̀ tó ọ̀ọ́dúnrún ni wọ́n farapa níbi ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé ní nǹkan bíi aago mọ́kànlá àbọ̀ alẹ́ ọjọ́bọ̀.

Agbẹnusọ ìjọba ní ọkọ̀ ńlá kan tó gbé afẹ́fẹ́ gáàsì ní ẹkùn Embakasi ló ṣàdédé gbiná lójijì.

Àwọn ilé, iléeṣẹ́, àti ọkọ̀ ló bàjẹ́, tí àwọn fídíò sì ń ṣàfihàn bí bí iná ọ̀hún ṣe ń fò lọ sí àwọn ilé ní agbègbè náà.

Àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò ti wà níbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà, tí wọ́n sì ní ìwádìí ti bẹ̀rẹ̀ láti mọ nǹkan tó ṣokùnfà ìbúgbàmù ọ̀hún èyí fa ìjàmbá iná náà.

Ìwádìí BBC fi hàn pé àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò ti nawọ́ gán èèyàn kan, ìyẹn ẹ̀ṣọ́ ààbò tó ń mójútó ọgbà tí ìbúgbàmù náà ti wáyé lórí ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún.

Ọ̀gá àgbà iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Embakasi, Wesley Kimeto ní ọmọdé kan wà lára àwọn tó pàdánù ẹ̀mí wọn àti pé ó ṣeéṣe kí àwọn tó máa pàdánù ẹ̀mí wọn tún lé kún.

Àwọn aláṣẹ ní èèyàn 271 ni wọ́n ti gbé lọ sí ilé ìwòsàn, tí àwọn ọmọdé mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n sì wà lára wọn.

Mayor Nairobi, Sakaja Johnson ní ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn tó farapa ló ti gba ìtọ́jú tí wọ́n sì ti lọ sí ilé wọn àmọ́ tí wọ́n ti gbé àwọn mọ́kàndínlógójì lọ sí ilé ìwòsàn mìíràn fún ìtọ́jú tó péye.

Wọ́n fi kun pé lójú ẹsẹ̀ ni wọ́n ti ṣe ìtọ́jú àwọn mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n nítorí wọn ò ṣèṣe púpọ̀.

Agbẹnusọ ìjọba Kenya, Isaac Mwaura ní iná náà fò lọ sí ilé tí wọ́n ń kó aṣọ pamọ́ sí, tó sì jó gbogbo ilé náà palẹ̀.

Àtẹ̀jáde ìjọba ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkọ̀, okoòwò kéékèèké àtàwọn ilé ìgbé ló bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ.

Wọ́n ti rí iná náà pa báyìí àmọ́ iṣẹ́ ń lọ lọ́wọ́ láti mọ̀ bóyá àwọn ènìyàn há sínú àwọn ilé, tí iṣẹ́ sì ń lọ láti dóòlà àwọn ènìyàn.

Wọ́n ní ìwádìí ń lọ́ láti fi mọ̀ bóyá àwọn ènìyàn jóná mọ́ inú ilé nínú àwọn ilé ìgbé tó jóná náà.

Àjọ tọ ń mójútó ohun àmúṣagbára ní orílẹ̀ èdè náà, The Energy and Petroleum Regulatory Authority (EPRA) NÍNÚ ÀTẹ̀jáde kan ní ilé tí wọ́n ti ń ta gáàsì náà kò tẹ̀lé ìlànà òfin.

Wọ́n ní ẹ̀ẹ̀mẹta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni àwọn ti kọ̀ láti fún iléeṣẹ́ náà láṣẹ láti kọ́ ibi tí wọn yóò máa kó gáàsì pamọ́ sí ní agbègbè náà.

Wọ́n ní àwọn kọ̀ láti fún wọn láṣẹ nítorí kò sí ìpèsè ààbò tó péye láti ọwọ́ iléeṣẹ́ náà àti pé àdúgbò tí wọ́n kọ sí jẹ́ èyí tí ilé ìgbé pọ̀ níbẹ̀.

Ohun tí kò yé ni bí iléeṣẹ́ náà ṣe ń ṣe iṣẹ́ láì gbàṣẹ.

Mwaura ni ẹni tó ni iléeṣẹ́ náà gbọ́dọ̀ fún àwọn tọ farapa ní owó gbà má bínú, kí wọ́n sì gbà pé àwọn ni ó ṣokùnfà ìbúgbàmù náà.

Àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣojú wọn ní ìbúgbàmù náà fa bí àwọn agolo gáàsì ṣe ń fò kiri tó sì ń fa ìjàmbá iná káàkiri.

Jackline Karimi ní òun sá jáde kúrò nínú ilé òun. Apá rẹ̀ kan jóná, tí ẹsẹ̀ rẹ̀ ọ̀tún náà sì ní àpá.

Ó ní òun rí obìnrin kan tó ń jóná àmọ́ àwọn kò lè ràn-án lọ́wọ́ nítorí oníkálukú ń sá àsálà fún ẹ̀mí ara rẹ̀ ni.

Obìnrin míì tí ilé rẹ̀ kò jìnà síbi tí ìbúgbàmù náà ti wáyé ní òun ń wá ọ̀rẹ́ òun tó ní ọmọ ìkọkó lọ́wọ́ tí ilé rẹ̀ sì ti jóná ráúráú.

Boniface Sifuna sọ fún Reuters pé agolo gáàsì ló dá àpá sí òun lára.

Agbẹnusọ ìjọba, Mwaura ní àwọn ti ṣí ibùdó kan tí wọ́n ti ṣètò dídólà àwọn èèyàn.