You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Oṣù kẹ́fà tí a ti gba owó oṣù kẹ́yìn rèé - ASUU
Ẹgbẹ awọn oṣisẹ fasiti ni Naijiria, ASUU, ti sọ pe ko si eyikeyi ninu awọn olukọ fasiti naa to tii gba owo oṣu lati oṣu Keji ọdun yii.
Aarẹ ẹgbẹ naa, Ọjọgbọn Emmanuel Osodeke fẹsun kan ijọba apapọ pe o n fi ebi pa awọn olukọ fasiti ọhun lọna ati le kan nipa fun wọn lati pada sẹnu iṣẹ wọn.
Osodeke lo fi ọrọ naa lede lasiko ifọrọwerọ kan pẹlu ileeṣẹ iroyin abẹle Channels.
O ni bo tilẹ jẹ pe ijọba apapọ n fi ebi pa awọn, ijoba ko ni le fi ebi da awọn pada sile ẹkọ
Aarẹ ASUU sọ pe “Oṣu Kẹfa ree ti wọn ti kọ lati san owo oṣu wa; wọn ro pe ti wọn ba di owo oṣu wa mu, a oo pada wa bẹbẹ lẹyin oṣu mẹta pe a fẹ pada sẹnu iṣẹ.”
“Amọ awa gẹgẹ bii ẹgbẹ ọmọwe ati ọlọpọlọ pipe, a ti gbọn kọja gbogbo arekereke yẹn.”
“Ẹ ko le fi ebi le wa pada sẹnu iṣẹ.”
Ati inu oṣu Keji ni gbogbo awọn akẹkọọ ti wa nile
Ọjọ kẹrinla, oṣu Keji, ọdun yii ni ASUU da iṣẹ silẹ lọna ati mu ki ijọba ṣe awọn nnkan ti wọn ti n bere fun lati ọjọ pipẹ wa.
Iyanṣẹlodi naa lo ti mu ọpọ awọn akẹkọọ ni fasiti ijọba wa nile awọn obi wọn fun nnkan bii oṣu mẹfa.
Amọ nigba to di ọjọ kọkandinlogun, oṣu Keje, Aarẹ Muhammadu Buhari paṣẹ fun minisita eto ẹkọ lati wa ojutu si iyanṣẹlodi naa, ko si jabọ fun oun laarin ọsẹ meji.
Ẹwẹ, nigba ti yoo fi di ọjọ kinni, oṣu Kẹjọ ti a wa yii ni ASUU fi ọsẹ mẹrin mii kun iye ọjọ iyanṣẹlodi ọhun.