You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
'Bí ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ àti obìnrin ṣe forúkọ sílẹ̀ fún PVC kò wúlò tí ...'
Onimọ nipa ọrọ oṣelu ni Naijiria, Ọjọgbọn Adewale Yagboyaju, to jẹ olukọ imọ osẹlu ni Fasiti Ibadan, sọ pe nkan to jẹ iwuri ni esi akọsilẹ awọn oludibo to fi orukọ silẹ jẹ.
O ni eyi tumọ si pe eto ijọba awaarawa ti n di ilana iṣejọba ti ọpọ eeyan fi ara mọ ni Naijiria
Bakan naa lo tun tumọ si pe ilana idibo Naijiria jẹ eyi to n fun gbogbo eeyan ni anfaani lati sẹ ojuṣe wọn
Ọjọ Aje, ọjọ kinni, oṣu Kẹjọ, ni INEC kede pe o le ni miliọnu mẹjọ ọdọ (8,784,677) to fi orukọ silẹ lati gba kaadi idibo wọn ṣaaju idibo ọdun 2023.
Ti apapọ awọn obinrin to ṣe bẹẹ si jẹ miliọnu mẹfa le diẹ (6,224,866).
Inec sọ pe iru eyi ko waye ri, nitori pe ṣaaju asiko yii, awọn ọkunrin lo ma n pọ ju.
Ajọ naa fi ikede yi sita loju opo Twitter rẹ, lẹyin to ti kọkọ kede pe opin ti de ba iforukọsilẹ fun gbigba kaadi idibo, ti pari ni ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Keje.
Ọjọgbọn Yagboyaja sọ pe nkan to foju han ni pe awọn obinrin ati awọn ọdọ, ju idaji gbogbo eeyan to wa ni Naijiria lọ.
Eyi to fihan tumọ si pe awọn ọdọ ati obinrin n finnu-findọ fẹ kopa ninu eto osẹlu
Ati pe o jẹ apẹẹrẹ pe awọn obinrin, to jẹ alamojuto ile, ati awọn ọdọ to jẹ ireti ọjọ iwaju, jẹ ko ṣee ma ni ninu eto iṣejọba.
O ni o tumọ si pe awọn obinrin to jẹ alamojuto ẹbi, ni imọlara ijọba kọọkan to ti n jẹ ni Naijiria lati ọdun 1999 to ti pada si ijọba awaarawa.
Eyi to mu ki wọn o fẹ kopa ninu eto ti yoo gbe ijọba miran wọle ni ijọba apapọ, ipinlẹ ati ibilẹ.
Ṣugbọn, o ni bi ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu eeyan ṣe fi orukọ silẹ ko tumọ si pe yoo wulo lasiko idibo.
“Idi ni pe ọpọ igba, ninu awọn idibo to ti kọja, ni eeyan perete ti ma n jade dibo, bo tilẹ jẹ ọpọlọpọ miliọnu ni awọn to gba kaadi idibo.
“Amọ ti awọn ti yoo jade dibo, ba wa ni ibamu pẹlu iye awọn to gba kaadi, a jẹ pe eto oṣelu ti di nkan ti ọpọ eeyan ni oye nipa rẹ ni Naijiria.”
Bakan naa lo ni ti gbogbo wọn o ba tiẹ kopa ninu eto idibo, o ni eyi tun le tumọ si pe ilọsiwaju n waye lagbo osẹlu Naijiria, ju ti atẹ́yinwa lọ
O wa gba gbogbo awọn to gba kaadi oludibo, lati lo o fun nkan to wa fun, eyi tii sẹ idibo.
8 miliọ̀nù ọ̀dọ́ ló yarí forúkọ sílẹ o! Ẹkùn Ìwọ̀ Oòrùn Àríwá àti Gúúsù Nàìjíríà sì ló forúkọ sílẹ̀ jùlọ fún káàdì ìdìbò
Bí àjọ elétò ìdìbò INEC ṣe ti parí ètò ìforúkọ́sílẹ̀, iyé àwọn tó forúkọ sílẹ̀ fún káàdì ìdìbò ní àlékún ti bá báyìí.
Àjọ tó ń rí sí ètè ìdìbò Nàìjíríà, INEC nínú àtẹ̀jáde kan tí wọ́n fi léde lẹ́yìn tí ètò ìforúkọsílẹ̀ fún káàdì ìdìbò náà wá sópin lọ́jọ́ Àìkú ọjọ́ Kọkànlélọ́gbọ̀n, oṣù Keje, ọdún 2022 ní ó lé ní àwọn mílíọ̀nù méjìlá ló tún ti forúkọ sílẹ̀.
Èyí ni yóò sọ àwọn ènìyàn tó ní àǹfàní láti dìbò ní Nàìjíríà di mílíọ̀nù mẹ́rìndínlọ́gọ́rùn-ún kúrò ní mílíọ̀nù mẹ́rìnlélọ́gọ́rin tó wà tẹ́lẹ̀.
Gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀jáde INEC náà èyí tó wà lórí Twitter ṣe ṣọ, ẹkùn ìwọ̀ oòrùn àríwá Nàìjíríà tó kó àwọn ìpínlẹ̀ bíi Sokoto, Zamfara, Kano, Kaduna, Katsina, Kebbi àti Jigawa sínú ló ni àkọsílẹ̀ àwọn ènìyàn tó forúkọ sílẹ̀ jùlọ.
Ní ọdún 2019, àpapọ̀ àwọn tó forúkọ sílẹ̀ ní ẹkùn yìí jẹ́ ogún mílíọ̀nù lé díẹ̀ ṣùgbọ́n ní báyìí ó ti lé ní mílíọ̀nù méjìlélógún le ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹ̀ta pẹ̀lú bí àwọn mílíọ̀nù méjì àbọ̀ ṣe ṣẹ̀ṣẹ̀ forúkọ sílẹ̀.
Ẹkùn tó tẹ̀lé ni ìwọ̀ oòrùn gúúsù Nàìjíríà níbi tí àpapọ̀ àwọn ènìyàn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ forúkọ sílẹ̀ fún káàdì ìdìbò ní àwọn ìpínlẹ̀ bíi Eko, Oyo, Ogun, Ondo, Ekiti ati Osun ṣe lé díẹ̀ ní mílíọ̀nù méjì.
Mílíọ̀nù mẹ́rìndínlógún àwọn ènìyàn ló forúkọ sílẹ̀ ní ẹkùn yìí lọ́dún 2019 àmọ́ ó ti di mílíọ̀nù méjìdínlógún lé díẹ̀ nínú àtẹ INEC tuntun.
Ààrin gbùngbùn gúúsù ló wà ní ipò Kẹta tí àwọn tó lẹ́tọ̀ọ́ láti dìbò ní ọdún 2023 ti di mílíọ̀nù mẹ́ẹ̀dógún lé díẹ̀ báyìí dípò mílíọ̀nù mẹ́tàlá dín ẹgbẹ̀rún lọ́nà igba tó jẹ́ lọ́dún 2019.
Bákan náà ni ààrin gbùngbùn àríwá tó wà ní ipò kẹrin ti ní àwọn ènìyàn mílíọ̀nù mẹ́rìnlá tó ní àǹfàní láti dìbò lọ́dún 2023.
Ìlà oòrùn àríwá ló wà nípò karùn-ún pẹ̀lú bí àwọn ènìyàn tó forúkọ sílẹ̀ ṣe jẹ́ mílíọ̀nù kan àbọ̀, tí àpapọ̀ àwọn tó lè dìbò ní Yobe, Taraba, Adamawa, Bauchi àti Gombe jẹ́ mílíọ̀nú mẹ́tàlá dín ẹgbẹ̀rún lọ́nà igba.
Ẹkùn ìlà oòrùn gúúsù ló wà nípò kẹfà níbi tí àpapọ̀ àwọn ènìyàn tó lẹ́tọ̀ọ́ láti dìbò ní Ebonyi, Abia, Enugu, Anambra àti Imo jẹ́ mílíọ̀nù mọ́kànlá àbọ̀ dín díẹ̀.
Ìpínlẹ̀ Eko ló wà ní ipò àkọ́kọ́ fún àwọn ènìyàn tó forúkọ sílẹ̀ jùlọ pẹ̀lú mílíọ̀nù méje ènìyàn tó le dìbò níbẹ̀ lọ́dún 2023 tí ìpínlẹ̀ Kano sì tẹ̀lé pẹ̀lú àkọsílẹ̀ mílíọ̀nù mẹ́fà ènìyàn tó le dìbò.
Kaduna ló wà ní ipò kẹta mílíọ̀nù mẹ́rin lé ọwọ́ mẹ́rin, kó tó kan ìpínlẹ̀ Rivers àti Katsina nípò kérin àti karùn-ún pẹ̀lú àkọsílẹ̀ mílíọ̀nù mẹ́ta lé ọwọ́ mẹ́fà àti márùn-ún.
Àwọn ọ̀dọ́ kó ìdá 71% nínú àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ fi orúkọ sílẹ̀
Gẹ́gẹ́ bí àtljáde INEC ṣe fìdí ẹ̀ múlẹ̀, nínú àwọn ènìyàn mílíọ̀nù méjìlá lé ọwọ́ méjì tó ṣẹ̀ṣẹ̀ fi orúkọ sílẹ̀ mílíọ̀nù mẹ́jọ lé ọwọ́ méje ló jẹ́ ọ̀dọ́ tí ọjọ́ orí wọn wà láàárín ọdún méjìdínlógún sí mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n.
Bákan náà ni àwọn tí ọjọ́ orí wọn wà láàárín ọdún márùndínlógójì sí mọ́kàndínláàdọ́ta tó forúkọ sílẹ̀ jẹ́ mílíọ̀nù méjì lé ọwọ́ mẹ́rin.
Àwọn yòókù ni ló jẹ́ láti àádọ́ta ọdún lọ sókè.
Bẹ́ẹ̀ náà ni àtẹ̀jáde náà ṣàlàyé pé àwọn obìnrin ló pọ̀ ju ọkùnrin lọ nínú àwọn tó forúkọ sílẹ̀ náà.