You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Wo àwọn nkan tí o kò fi ojú sí àmọ́ tó n fa àìrọ́mọbí fún ọ̀kunrin
"Wiwọ ṣokoto to fún, ma n mu ki ooru mu abẹ ọkunrin, ti gbigbona rẹ si ma n ba atọ jẹ".
Ki ọkunrin ma le fun obinrin loyun, jẹ aisan kan ti awọn eeyan kii ṣaba sọrọ nipa rẹ.
Sugbọn o jẹ nkan to wọpọ, to si wa lara awọn nkan to ma n fa ipinya laarin tọkọtaya.
Bakan naa ni aisan yii jẹ ara nkan to ma n mu awọn iyawo ile kan jade sita lọ ṣe agbere, tabi wa ọna ẹburu mii titi wọn o fi loyun.
Ti awọn kan ninu wọn si ma n gbe ọmọ naa fun ọkọ wọn, nitori ki igbeyawo wọn ma baa daru paapaa to ba jẹ pe ọkunrin naa ko mọ pe oun ni aisan ailerọmọbi.
Aisan airọmọbi laarin awọn ọkunrin jẹ eyi to ma n mu ko ṣoro fun ọkunrin, lati fun iyawo rẹ loyun.
Gẹgẹ bi ajọ eto ilera l’agbaye, WHO, ṣe sọ, ẹgbẹẹgbẹrun miliọnu eeyan ni asian airọmọbi ma n ṣe ni agbaye, to si ma n ni ipa ti ko dara lori ẹbi ati awujọ.
WHO sọ pe eeyan bi miliọnu 48 si 186 to jẹ tọkọtaya, lo n koju iṣoro airọmọ bi ni agbaye.
Ki lo ma n fa airọmọbi lara ọkunrin?
Onimọ iṣegun oyinbo kan nipa ilera nkan ọmọkunrin, Dokita Adebayo Bamisebi, sọ fun BBC Pidgin pe, nkan pataki to ma n fa iṣoro airọmọbi laarin awọn ọkunrin ni odinwọn àtọ̀ ọkunrin to ba kere tabi ọkunrin ti atọ rẹ ko poju owo to.
Dokita Bamisebi ṣalaye pe ti tọkọtaya ba n ni ibalopọ, ti ko si yọri si oyun fun oṣu mẹfa si ọdun kan, o jẹ apẹẹrẹ pe ẹnikan lara wọn ni iṣoro airọmọbi.
O ni ti ayẹwo ba wa fihan pe odinwọn atọ ọkunrin naa dun ni miliọnu mẹẹdogun, o tumọ si o ni iṣoro airọmọbi.
Bakan naa lo sọ pe awọn nkan miran to tun ma n fa airọmọbi laarin ọkunrin ni iru igbeaye ti wọn n gbe, ati awọn aarun mii.
“Lilo oogun lọna aitọ, amuju ọti, jijoko si ojukan fun igba pipẹ, tabi wiwọ ṣokoto to fún, tun ma n fa airọmọbi fun ọkunrin.”
Dokita mii, Seraph Obasohan ni tiẹ sọ pe amuju ọti ati siga, pẹlu igbo, ni awọn nkan mii to wọpọ to n fa airọmọbi laarin awọ̀n ọkunrin, botilẹ jẹ pe ọpọ eeyan ko mọ eyi.
Dokita Obasohan sọ pe wiwọ ṣokoto to fún, ma n mu ki ooru mu abẹ ọkunrin, ti gbigbona rẹ si ma n ba atọ jẹ.
O ni awọn oogun kan ti wọn fi n tọju inu rirun ati aya didun naa ma n sẹ akoba fun ọkunrin.
“Awọn ọkunrin kan ti ẹ wa, ti wọn kii da àtọ̀ rara, lasiko ibalopọ.
“Wọn ma n bi iru awọn ọkunrin yii bẹẹ ni. Nkan ọmọkunrin wọn yoo dagba bo ṣeyẹ, amọ koropọn rẹ ko nii ṣiṣẹ daadaa.”
O ni awọn ọkunrin ti nkan ọmọkunrin wọn kere, awọn ti ko le ba obinrin lopọ rara, tabi awọn to tete ma n da atọ lasiko ibalopọ, to fi mọ awọn to ti ko aarun ibalopọ, naa ma n ni iṣoro airọmọbi.
Kini ọna abayọ si iṣoro airọmọbi laarin awọn ọkunrin?
Dokita Bamisebi sọ pe itọju ti wọn o fun ọkunrin, nii ṣe pẹlu nkan to fa airọmọbi rẹ, ati esi ayẹwo.
O ni awọn iṣoro airọmọbi fun awọn ọkunrin kan ma n la ṣiṣe iṣẹ abẹ fun wọn lọ, tabi oogun lilo.
O gba awọn ọkunrin ni imọran lati ma a jẹ ounjẹ aṣaraloore to ni eroja Vitamin C, Vitamin D, ati Zinc ninu, lati mu ki atọ wọn o pọ si.