Ọlọ́pàá mú afurasí òbinrin méjì tó jí ọmọ ọ̀sẹ̀ kan gbé ní Ogun

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti mu arabinrin ẹni dun mẹtalelaadọta, chinyere Nwozu, fun ẹsun pe o ji ọm tuntun gbe.

Iroyin sọ pe ko tii ju ọsẹ kan ti wọn bi ọmọ naa, ni Arabinrin Nwosu ji i gbe.

Ninu atẹjade ti agbẹnusọ ọlọpaa, Abimbola Oyeyemi, fi sita lori ọrọ naa, ọjọ karundinlọgbọn, oṣu Keje, ọdun 2022, ni ọwọ tẹ Nwosu.

Arakunrin Oyeyemi sọ pe ara fun awọn araalu si obinrin naa, nigba ti wọn ri ọmọ naa lọwọ rẹ, ti ọmọ naa si n sunkun, amọ to kọ̀ lati fun ni ọmu gẹgẹ bo ṣe yẹ ki iya ọmọ ṣe.

Eyi lo mu ki awọn to wa layika naa fura, ti wọn si tete ranṣẹ pe awọn ọlọ̀paa ni olu ileeṣẹ ọlọpaa ni ẹkun Sango Ota, ti wọn si mu.

Ni agọ ọlọpaa ni arabinrin naa ti jẹwọ pe oun kọ ni iya to bi ọmọ tuntun ọhun.

O ni oun ra ọmọ tuntun naa lọwọ ẹnikan ni, ni agbegbe Agege nipinlẹ Eko, pẹlu iranlọwọ Ngozi Akaeme.

Ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta Naira (N500,000) lo ni oun ra ọmọ naa.

Ijẹwọ rẹ lo mu ki awọn ọlọpaa tọpinpin Ngozi, ti ọwọ fi tẹ oun naa.

Ṣugbọn ọrọ naa ko tan sibẹ o, Ngozi paapaa jẹwọ fun ọlọpaa pe oun ni oun duna-dura pẹlu iya to bi ọmọ naa, lẹyin to gbalati ta a.

Amọ ṣa, igbiyanju awọn ọlọpaa lati ṣawari iya ọmọ naa ni ko tii so eso rere.

Agbẹnusọ ọlọpaa nipinlẹ Ogun, Abimbola Oyeyemi sọ pe wọn o gbe obinrin naa lọ sile ẹjọ, lẹyin iwadii awọn ọtẹlẹmuyẹ.

Iṣẹlẹ jiji ọmọ tuntun gbe, tabi ta, ko ṣẹṣẹ ma a waye ni orilẹ-ede Naijiria.

Ọjọ diẹ sẹyin ni ọwọ tẹ arabinrin kan nilu Ibadan, olu ilu ipinlẹ Oyo, fun pe o ji ọmọ tuntun gbe.

Iya ọmọ naa, sọ fun BBC Yoruba pe ileewosan ni oun ati ẹni to ji ọmọ gbe ti pada, ti oun si gba a sile nitori pe o ni iṣoro.

Ọjọ keji, lo ji ọmọ gbe salọ.

Irufẹ iṣẹlẹ yii naa ti waye lọsẹ diẹ sẹyin nigba ti arabinrin kan pẹlu ji ọmọ tuntun gbe nilu Okitipupa, nipinlẹ Ondo, to si gbe e lọ si ipinlẹ Ogun.

Ni ibi ti wọn ti n ṣe isọmọlorukọ ọmọ naa ni ipinlẹ Ogun ni ọwọ awọn ọlọpaa ti tẹ obinrin naa.