You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ọkọ̀ ojú irin Abuja sí Kaduna bẹ̀rẹ̀ iṣẹ̀ padà, iléeṣẹ́ reluwé fowó kún Eko sí Ibadan
Lónìí ọjọ́ Ajé, ọjọ́ Karùn-ún, oṣù Kejìlá ọdún ni iléeṣẹ́ ọkọ̀ ojú irin Abuja sí Kaduna bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ padà lẹ́yìn oṣù mẹ́jọ tí àwọn agbébọn ṣe ìkọlù sí ọkọ̀ ojú irin náà ní oṣù kẹta.
Ní báyìí tí ọkọ̀ ojú irn náà ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ padà, iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Nàìjíríà ni àwọn ti dá àwọn ọlọ́pàá sí ibùdókọ̀ ojú irin náà èyí yóò máa pèsè ètò ààbò fún àwọn tó wá ń wọkọ̀.
Àtẹ̀jáde kan tí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá fi síta ní wí pé àwọn ọlọ́pàá lẹ́ka tó ń rí sí ìwà ọ̀daràn, àwọn ọlọ́pàá tó wà lẹ́ka àwọn tó ń lo ajá láti ṣèwádìí àti àwọn ẹ̀ka mìíràn ni yóò máa tẹ̀lé àwọn ọkọ̀ ojú irin náà.
Bákan náà ni wọ́n ní ìgbésẹ̀ yìí wáyé láti dá ààbò bo ẹ̀mí àti dúkìá àwọn èrò tó ń wọkọ̀ ojú irin àti ọkọ̀ ojú irin náà kí irúfẹ́ ìkọlù bẹ́ẹ̀ má ba à wáyé mọ́.
Ṣaájú ni adarí iléeṣẹ́ rélùwéè Nàìjíríà, NRC, Fidet Okhira ti sọ pé àwọn ń pọkún ètò ààbò nígbà tí àwọn yóò bá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ padà.
Ó ní lára ìgbésẹ̀ tí àwọn ń gbé ni wí pé kí ẹnikẹ́ni tó le ra tíkẹ́ẹ̀tì láti wọ ọkọ̀ ojú irin náà, onítọ̀hún gbọ́dọ̀ pèsè nọ́mbà ìdánimọ̀ NIN rẹ̀ àti nǹkan mìíràn.
Iléeṣẹ́ ọkọ̀ ojú irin Eko sí Ibadan fowó kún ọkọ̀
Iléeṣẹ́ ọkọ̀ ojú irin Eko sí Ibadan ti kéde àfikún owó ọkọ̀ ojú irin Eko sí Ibadan.
Nínú àtẹ̀jáde kan tó tẹ BBC News Yorùbá lọ́wọ́ ni àwọn aláṣẹ ilé iṣẹ́ náà ti sọ nípa àlékún tó bá àwọn ọkọ̀ ní ipele tí àwọn èrò fi máa ń wọ ọkọ̀ ojú irin náà.
Fún ipele àkọ́kọ́ èyí tí wọ́n ń gbé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́fà náírà tẹ́lẹ̀ (#6,000) ló ti di ẹgbẹ́rùn mẹ́sàn-án àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta náírà báyìí (#9,500).
Ti ipele kejì tí wọ́n ń gbé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́rin náírà tẹ́lẹ̀ (#4,000) ti ní àfíkún ẹgbẹ̀rún méjì àbọ̀ náírà èyí tó túmọ̀ sí pé ó ti di ẹgbẹ̀rún mẹ́fà àbọ̀ náírà (#6,500) báyìí.
Bákan náà ni àtẹ̀jáde náà fi kun pé ipele tó kẹ́yìn tó jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjì àti ẹgbẹ̀ta náírà (#2,600) ti wá di ẹgbẹ̀rún mẹ́ta àti ẹgbẹ̀ta náírà (#3,600) báyìí.