Kí ló fa wàhálà láàárín Canada àti India?

Orílẹ̀ èdè Canada ti fẹ̀sùn kan India pé wọ́n lọ́wọ́ nínú ikú olórí Sikh Canada kan, Hardeep Singh Nijjar.

Àmọ́ India tí jiyàn ẹ̀sùn náà.

Ní ọjọ́ Ajé ni Olóòtú ìjọba Canada, Justin Trudeau ní àwọn ń ṣe ìwádìí ẹ̀sùn pé India lọ́wọ́ nínú ikú Hardeep Singh Nijjar.

Trudeau sọ fún ilé aṣòfin orílẹ̀ èdè rẹ̀ pé òun bá Olóòtú ìjọba India, Narendra Modi sọ̀rọ̀ nípa ikú Nijjar nígbà tí òun báwọn kópa níbi àpérò G20 tó wáyé ní Delhi.

Ó sọ fún àwọn aṣòfin náà pé ìjọba Canada korò ojú sí kí orílẹ̀ èdè kan lọ́wọ́ nínú ikú ọmọ orílẹ̀ èdè àwọn.

Àmọ́ iléeṣẹ́ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ilẹ̀ òkèrè India ní àwọn kò gba ẹ̀sùn tí Trudeau fi kan àwọn rárá àti pé ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní ọ̀rọ̀ òṣèlú nínú.

Bákan náà ni wọ́n fi ẹ̀sùn kan Canada pé ó ń fi ààyè gba àwọn agbéṣùmọ̀mí Khalistani tí wọ́n ń da India láàmú.

Iléeṣẹ́ náà rọ ìjọba Canada láti gbé ìgbésẹ̀ òfin tako gbogbo àwọn tó ń ṣiṣẹ́ tako India láti Canada.

Ní ọjọ́ kejìdínlógún oṣù Kẹfà ni wọ́n yìnbọn pa Nijjar.

Lórí ọ̀rọ̀ yìí, India ti lé aṣojú Canada lẹ́yìn tí Canada náà lé aṣojú India sí orílẹ̀ èdè wọn, Pavan Kumar Rai kúrò.

Báwo ni Hardeep Singh Nijjar ṣe kú?

Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kejìdínlógún oṣù Kẹfà, àwọn ọlọ́pàá bá Hardeep Singh Nijjar nínú ọkọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ojú ọta ìbọn lára rẹ̀ ní tẹ́ḿpìlì Guru Nanak Sikh Gurdawa ní Surrey.

Nijjar padà dágbére fáyé látàrí ọgbẹ́ tí àwọn ọta ìbọn náà dá si lára.

Àwọn ọlọ́pàá ní àwọn ọkùnrin méjì tó dá àwọ̀n bojú ni wọ́n yìnbọn fún Nijjar.

Nijjar jẹ́ Ààrẹ tẹ́ḿpìlì àti olórí àwọn Sikh tó ń polongo fún Khalistan ìyẹn ìdásílẹ̀ ìlú Sikh ní ẹkùn Punjab ní orílẹ̀ èdè India.

Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ oṣù lẹ́yìn ikú rẹ̀, ìpànìyàn kò ì tíì dẹ́kun.

Àwọn orílẹ̀ èdè àgbáyé dá sí ẹ̀sùn ikú Sikh

Orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà ti rọ India láti fọwọ́sowọ́pọ̀ lórí ìwádìí pé ìjọba wọn lọ́wọ́ nínú ikú Sikh.

Amẹ́ríkà ti ń ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú Canada lórí ẹ̀sùn náà.

Wọ́n ní ìwádìí kíkún ṣe pàtàkì sí ẹ̀sùn yìí àti pé ìjọba India ṣe fọwọ́sowọ́pọ̀ lórí ìwádìí náà.

Iléeṣẹ́ ilẹ̀ òkèrè Australia ní ọ̀rọ̀ náà ń kan àwọn lóminú.

Agbẹnusọ iléeṣẹ́ ilẹ̀ òkèrè, Penny Wong sọ pé Australia ń mójútó gbogbo bí ìwádìí náà ṣe ń lọ.

Britain ní àwọn yóò ṣì máa dúnàádúrà pẹ̀lú India pẹ̀lú gbogbo ẹ̀sùn to wà lọ́rùn wọn.

Ìjọba UK ní àwọn ń ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú Canada lórí ẹ̀sùn náà.

Ta ni Hardeep Singh Nijjar?

Ní ọjọ́ kejìdínlógún oṣù Kẹfà ni wọ́n yìnbọn pa Hardeep Singh Nijjar lẹ́ni ọdún márùndínláàdọ́ta.

Ìlú Bharsinghpur ní Punjab Jalandhar ni wọ́n ti bi kó tó kó lọ sí Canada lọ́dún 1997.

Iṣẹ́ plumber ni ó kọ́kọ́ ń ṣe kó tó gbajúmọ̀ bí olórí Sikh ní ẹkùn Canada ní British Columbia.

Ní ọdún 2020 ni India kéde rẹ̀ bí agbéṣùmọ̀mí fún pé ó lọ́wọ́ nínú ikọ̀ Khalistani.

Nijjar ni ẹnìkẹta tó jẹ́ èèkàn Sikh tó pàdánù lọ́nà aramanda ní oṣù díẹ̀ sẹ́yìn.

Kí ni àwọn nǹkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa Sikh?

Ìjọ ẹ̀sìn tó kó ìdá méjì nínú àwọn ènìyàn India ni Sikh jẹ́.

Ní ọdún 1970, àwọn Sikh bẹ̀rẹ̀ ṣíṣe ìkọlù sí àwọn ènìyàn níbi tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀mí ti sùn kí wọ́n tó paná ìṣẹ̀lẹ̀ lẹ́yìn bí ọdún mẹ́wàá.

Láti ìgbà náà ni àwọn tó ń ṣe Sikh ti ń wà ní Canada àti UK níbi tí wọ́n pọ̀ sí.

Àwọn Sikh tó wà ní Canada tí wọ́n jẹ́ ọmọ bíbí India ló lé ní mílíọ̀nù kan àbọ̀.

India tí júwe Nijjar bí agbéṣùmọ̀mí lẹ́yìn tó ṣáájú ikọ̀ kan àmọ́ tí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ jiyàn rẹ̀.

Wọ́n ní tipẹ́ ni wọ́n ti ń dúnkokò mọ́ àwọn lórí ìṣe rẹ̀.