You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Wo ọ̀nà tí ó lè fi dáàbò bo ọmọdé létí adágún omi ‘swimming pool’
Lẹyin ti ọmọ olorin takasufe, Davido jade laye latari bo ṣe ko sinu omi odo ‘swiming pool’ nile rẹ to wa niluu Eko, oniruru ọrọ lo ti n jade nipa bi eeyan ṣe le daabo bo awọn ọmọ wẹwẹ leti agbami odo inu ile wọn.
Ṣaaju iṣẹlẹ yii ni ọmọ olorin takasufe mii ni Naijiria, Oladapo Oyebanjo, ti ọpọ mọ si Dbanj naa jade laye lẹyin to ko sinu odo ninu ile rẹ.
Amọ onimọ kan nipa ile kikọ, to tun jẹ akọṣẹmọṣẹ ayaworan ile, Daniel Ette ti sọ pe irufẹ ijamba to ṣẹlẹ si ọmọ Davido yii le waye ti eeeyan ko ba bikitia, ati bi wọn ko ba tẹlẹ awọn ilana to yẹ ki wọn tẹle.
Awọn ilana to yẹ ki o tẹle leti adagun omi ‘swimming pool’
Ọgbẹni Ette sọ pe gbogbo awọn to ba ni adagun omi sile wọn gbọdọ ṣe awọn eto to yẹ lati ri pe awọn ọmọ wọn ko ri sinu irufẹ adagun omi bẹẹ.
Gẹgẹ bii ohun to sọ, riri sinu omi ni ijamba to ṣaba maa n waye leti irufẹ odo bẹẹ.
O ni “Oniruru ọna ni wọn fi n kọ adagun omi ninu ile, amọ ọna kan naa ni eeyan yoo gba lati daabo bo ara rẹ lọwọ ijamba rẹ.”
Ara awọn ọna lati dabo bo ara ẹni ree:
- Tẹle ofin to rọ mọ odo ‘swiming pool’ ti o ti fẹ wẹ
- Maṣe bẹ sinu ‘swiming pool’ ti ko ba jin daadaa
- Ṣọra fun erekere ninu adagun odo
- Maṣe sare leti odo ‘swimming pool’
- Maṣe danikan wẹ
- Ri daju pe o wọ aṣọ idaabobo ara ẹni ‘life jacket’
- Maṣe luwẹ lasiko ti ojo ba n rọ ki ara ma baa san pa ọ
Awọn ohun miran ti o le ṣe
Yatọ so awọn ofin to rọ mọ liluwẹ ninu adagun omi yii, ọgbẹni Ette ṣalaye siwaju si pe ọna kan pataki lati dabo bo awọn ọmọde ni lati fi nnkan bo ori dagun odo naa.
Gẹgẹ bii ohun to sọ, ṣiṣẹ bẹẹ yoo mu ko ṣoro ki ọmọde ja sinu rẹ.
O ni “Pẹlu imọ ẹrọ, eeyan le ṣe orule sori adagun odo inu ile rẹ.”
“Bakan naa ni eeyan le lo ohun ti yoo maa ta onile lolobo ti eeyan ba fẹ wọ inu adagun odo ile rẹ.
O pari ọrọ rẹ pe o ṣe pataki ki eeyan ni awọn alakalẹ nipa bi wọn yoo ṣe maa lo adagun omi ninu ile fun abo gbogbo awọn ti yoo lo.