You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ṣé lóòótọ́ ni pé ilé ejọ̀ ní kí wọ́n fi Simon Ekpa ránṣẹ́ sí Naijiria?
Kaarle Gummerus, agbẹjọro fun Simon Ekpa, olori fun ikọ to n pe fun ominira orilẹede Indigenous Pipo of Biafra (IPOB) to wa ni ọgba ẹwọn ni orilẹede Finland ti sọrọ lori iroyin kan to ni wọn fẹ fi onibaara rẹ sọwọ si orilẹede Naijiria lati wa koju ẹsun rẹ.
Bẹẹ ba gbagbe, nigba ti ọwọ tẹ Ekpa, Ọga ileeṣẹ Ologun lorilẹede Naijiria ni ijọba n gbe igbesẹ lati ri pe wọn fi Ekpa ransẹ wa si orilẹede Naijiria lati wa koju ẹsun to wa niwaju rẹ.
Ni oṣu kọkanla ọdun 2024, ileeṣẹ iroyin abẹle kede pe ile ẹjọ Päijät-Hämeni ki wọn lọ fi Ekpa si ahamọ, to si jẹ pe lati igba naa ni oloṣelu Lahti municipal ti n gba atẹgun ni ọgba ẹwọn.
Bi Ekpa ṣe ti wa lọgba ẹwọn, ijọba orilẹede Naijiria fi orukọ rẹ sinu awọn eeyan mejila, ti wọn ti apo owo banki wọn fun ẹsun igbesunami.
Ẹ ma gbagbe pe Ekpa, jẹ ọmọ ọrilẹede Naijiria lati apa guusu lo tun jẹ ọmọ onilu ni orilẹede Finland
Agbẹjọro rẹ sọ fun BBC ni ọsẹ to kọja pe ninu oṣu kẹfa ni Ekpa yoo foju ba ile ẹjọ.
Kaarle Gummerus ni ẹjọ Ekpa si wa ni idaduro bayii, ti oun ko si ni iroyin kankan nipa pe wọn yoo gbe Ekpa wa si orilẹede Naijiria.
"N ko mọ ohunkohun nipa pe wọn fẹ mu Simon Ekpa wa si Naijiria. Ọrọ rẹ si wa ni ile ẹjọ."agbẹjọro Ekpa sọ fun BBC.
Gummerus ni otitọ ni pe awọn ti gba iwe lati ọwọ ile ẹjọ ṣugbọn awọn si n yẹwo lọwọ.
O ni Ekpa yoo farahan ni ile ẹjọ ni oṣu kẹfa ọdun 2025.
Bakan naa ni Päijät-Hämeni, sọ fun BBC News pe awọn ko ti ka ẹsun kankan si ẹsẹ Ekpa, ti awọn si ni di oṣu Karun un lati ka ẹsun si ẹsẹ Ekpa.
Ṣaaju ni Ijọba apapọ kede pe adari ẹgbẹ IPOB to n ja fun ominira orilẹede Biafra, Simon Ekpa, atawọn mẹrindinlogun mii n ṣatilẹyin owo fawọn agbesunmọmi ni Naijiria.
Bakan naa ni ijọba tun ti gbẹse le akaunti owo Ekpa atawọn mẹrindinlogun yooku.
Ta a ni Simon Ekpa?
Ọmọ bibi ijọba ibilẹ Ohaukwu nipinlẹ Ebonyi ni Simon Ekpa ti wọn si bi ni Ọjọ kọkanlelogun, ọsu kẹta odun 1985.
O jẹ ọmọ ọba Nwangbo ni Ngbo ati Lolo Nwangbo.
Orilẹede Finland ni Simon n gbe nibi to ti n saaju ipe fun ominira fun Biafra, to si sọ fun awọn ẹẹya igbo lorilẹede Naijiria lati kopa ninu eto idibo ti ijọba apapọ ba kuna lati tu Nnamdi Kanu silẹ.
Simon, lori opo ayelujara Twitter rẹ sapejuwa ara rẹ gẹgẹ bi ajafẹtọ ọmọniyan, oludasilẹ, agbẹjọrọ, oloṣelu, agbẹnusọ Biafria ati bẹbẹlọ.
O kede ọjọ marun un lati ọjọ kẹtalelogun titi di ọjọ kẹjidinlọgbọn gẹgẹ bi ọjọ konilegbele rẹ, to si ti da rukerudo silẹ ni apa guusu ila oorun naa.