You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Irọ́ ni ìròyìn tó sọ pé àrùn Covid-19 tún padà ṣẹ́yọ ní Naijiria – Ìjọba àpapọ̀
Ijọba apapọ ti sọ pe irọ ni awọn iroyin kan to ni arun Covid-19 ti pada ṣẹyọ ni Naijiria.
Adari ileeṣẹ to n ri si eto ilera, Ọjọgbọn Ali Pate lo sọ ọrọ naa ni fasiti ikọṣẹ iṣegun oyinbo to wa niluu Otukpo, nipinlẹ Benue.
Ali Pate sọ pe ko si iwadii ijinlẹ kankan to tii fidi rẹ mulẹ pe aarun ọhun ti pada ṣẹyọ ni Naijiria.
Oludamọran pataki fun Pate, to sọju rẹ nibi idanilẹkọọ naa, Emmanuel Oduh, sọ pe aarun bii Covid-19 kii ṣe eyii ti awọn eeyan yoo maa gbe iroyin nipa rẹ lai fi ẹri tẹ iroyin naa nidi.
O ni “iwadii imọ ijinlẹ sayẹnsi ni a fi n ṣayẹwo COVID, kii ṣe nnkan ti eeyan kan yoo kan maa gbe iroyin nipa rẹ kiri nitori igbagbọ to ni.
“Lootọ awọn eeyan le maa sọrọ nipa ohun ti wọn fura si, amọ niwọn igba ti a ba ṣe iwadii, ti iwadii naa si fi han pe kii ṣe COVID, o tumọ si pe kii ṣe COVID ni.”
O ni ọrọ Covid-19 ti di ohun atijọ ni Naijiria.
O ni “Arun Ebola lo kọkọ wa, Naijiria si wa lara awọn orilẹ-ede to kọkọ kapa rẹ.
“Lẹyin rẹ ni Covid-19 tun de, a sa ipa wa lati koju rẹ, koda, Naijiria wa lara awọn orilẹ-ede l'agbaye to tete kapa aarun naa bo tilẹ jẹ pe ẹka eto ilera wa ko lagbara to ti awọn orilẹ-ede kan.”
Minisita naa wa ke si fasiti ikọṣẹ eto ilera naa pe ijọba n reti ko mu eredi agbekalẹ rẹ ṣẹ.
Ọga agba fasiti ọhun, Ọjọgbọn Innocent Ujah sọ pe awọn ti gba akọṣẹmọṣẹ onimọ eto ilera ọgbọn sile ẹkọ naa lati kọ ọọdunrun oṣiṣẹ eto ilera ni ẹkọ to ye koro nibẹ.