Ṣé lóòtọ́ ni Ààrẹ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin, Akpabio ṣubú tó sì dákú níbi ayẹyẹ ọjọ́ ìbí rẹ̀?

Aarẹ ile igbimọ aṣofin, Godswill Akpabio, ti sọrọ soke lẹyin iroyin to ni o ṣubu lulẹ nibi ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ.

Akpabio ni ṣe lo rẹ oun, ati pe oun ti n ba aisan iba finra ṣaaju iṣẹlẹ naa.

Ṣaaju ni iroyin ti kọkọ sọ pe Akpabio ṣubu, to si daku lasiko to n sin Aarẹ Bola Tinubu jade ninu gbọngan ile itura Transcorp Hilton to wa nillu Abuja, nibi ti ayẹyẹ naa ti waye.

Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ nile igbimọ aṣofin Abuja lọjọ Ẹti, Akpabio ko sọ boya lootọ ni oun ṣubu tabi daku.

Amọ o fidi rẹ mulẹ pe aisan iba ba oun finra, aisan naa si ti wọ oun lara latari wahala ti oun n ṣe.

O ni “ohun to ṣẹlẹ lẹyin ayẹyẹ naa ṣafihan ifẹ ti a ni si ara wa gẹgẹ bii ọmọniyan.

“Mo lọ sile, mo pe dokita mi, o si jẹ ko ye mi pe mo ni aisan iba lara, pẹlu gbogbo wahala ti mo ti ṣe.

“Ko si ẹni ti ko le ṣaarẹ, ẹ jọwọ ẹ maa mu omi lojojumọ ko ma ba a rẹ agọ ara yin.

“Eyii n tumọ si pe a o tẹsiwaju lati maa ṣe iṣẹ wa.

“Mo fẹ fi akoko yii da awọn ọmọ Naijiria loju pe digbi ni ile igbimọ aṣofin wa, a o si maa tẹsiwaju ninu iṣẹ wa gẹgẹ bii aṣofin.”