You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Igun PDP kan kéde Adebayo Adedamola gẹ́gẹ́ bíi olùdíje gómìnà l'Osun
Igun ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party nipinlẹ Osun ti kede Adebayo Olugbenga Adedamola, ẹni ti ọpọ mọ si FRYO gẹgẹ bii ẹni to bori eto idibo abẹle lati jẹ oludije ẹgbẹ naa lasiko eto idibo Gomina nipinlẹ naa.
Eto idibo abẹle yii lo waye lọjọ Isẹgun, ọjọ keji, oṣu Kejila ọdun 2025, ti awọn asoju to le ni igba si wa lati ijọba ibilẹ ọgbọn nipinlẹ Osun.
Idibo yii waye lẹyin wakati mejila ti Gomina ipinlẹ Osun, Ademola Adeleke kede pe oun ti kuro ninu ẹgbẹ oṣelu PDP nitori rogbodiyan to n lọ lọwọ ninu ẹgbẹ naa, ti wọn si yọ orukọ rẹ kuro ninu awọn oludije eto idibo abẹle.
Adebayo ni apapọ ibo 919 ninu ibo 957 to jẹ ti awọn aṣoju ẹgbẹ naa.
Alaga idibo abẹle naa Humphrey Abba, lasiko to n kede esi idibo naa ṣalaye ni, "eeyan ogun nikan ni a ko ibo wọn. A sọ fun yin ṣaaju pe oludije kan juwọ silẹ. Oludije to ko gbogbo ibo ni Adebayo Adedamola pẹlu apapọ ibo 919."
Pẹlu bii Adeleke ṣe kede pe oun ti kuro, akọwe ẹgbẹ , Theophilus Shan, ni mimi kankan ko ni mi eto idibo abẹle naa, pe yoo waye, to si waye.
Idibo naa waye niluu Osogbo, ti ajọ INEC si ṣe amojuto idito naa pẹlu awọn agbofinro.
Ohun iyalẹnu lo jẹ pe orukọ Adeleke si han ninu iwe idibo abẹle naa.
Ìdí rèé tí orúkọ Gómìnà Adeleke sì fi wà lórí ìwé ìdìbò abẹ́nú PDP fún ipò gómìnà l'Osun, lẹ́yìn tó fẹgbẹ́ sílẹ̀ tán
Igbimọ to ṣagbatẹru eto idibo abẹnu ẹgbẹ oṣelu PDP fun ipo gomina nipinlẹ Osun ti ṣalaye idi ti orukọ Gomina Ademola Adeleke si fi wa lori iwe idibo, bo tilẹ jẹ jẹ pe o ti kọwe fi ẹgbẹ naa silẹ.
Akọwe igbimọ to n ṣakoso eto idibo naa, Ọgbẹni Sunday Solarin, sọ pe orukọ Gomina Adeleke ati alatako rẹ, Adebayo Adedamola, ni yoo si wa ninu iwe idibo nitori ko saye lati ṣe atunṣe lori iwe idibo naa mọ.
Ọgbẹni Solarin ṣalaye pe lalẹ ana ọjọ Aje ọjọ kinni oṣu Kejila ọdun yii ni gomina kede wi pe oun ti fẹgbẹ oṣelu PDP silẹ.
O ni ẹgbẹ si ti tẹ iwe idibo silẹ ko to di akoko yii, eyi to tumọ si pe ko saye lati ṣe ayipada kankan mọ.
''Ni bayii, gbogbo ẹni to ba fẹ dibo gbọdọ mọ pe Adebayo Adedamola nikan ni oludije oludije fun ipo gomina ninu idibo abẹnu ẹgbẹ PDP nipinlẹ Osun tori gomina Adeleke to jẹ alatako rẹ tẹlẹ ti kọwe fi ẹgbẹ silẹ,'' Solarin ṣalaye.
A gbọ wi pe awọn aṣoju kaakiri ẹkun ninu ẹgbẹ ti dibo ninu eto abẹnu ọhun to waye niluu Osogbo lonii nipinlẹ Osun.
Iroyin to tẹ wa lọwọ lati gbọngan Adolak Hall ti eto idibo naa ti waye fidi rẹ mulẹ pe awọn aṣoju ajọ eleto idibo Naijiria, INEC, wa nibẹ lati wo bi eto naa yoo ṣe lọ
Ẹwẹ, Gomina Adeleke ko tii kede ẹgbẹ oṣelu ti yoo darapọ mọ bayii, lẹyin to fi ẹgbẹ oṣelu PDP silẹ.
Gomina Ademola Adeleke kọ̀wé kúrò nínú ẹgbẹ́ òṣèlú PDP
O ku wakati mẹrindinlogun si eto idibo abele ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP nipinlẹ Osun, Gomina Ademola Adeleke kọwe kuro ninu ẹgbẹ oṣelu naa.
Alaga ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Osun, Sunday Bisi kede lọjọ Aje pe ẹgbẹ oṣelu naa ko ni ṣe eto idibo abẹlẹ to yẹ ko waye lọjọ Isẹgun nitori bi iyapa ẹgbẹ ṣe n ba ẹgbẹ naa ja lọwọ yii ati bi Gomina Adeleke ko ṣe fi ifẹ han si gbigba tikẹẹti ẹgbẹ oṣelu PDP lati soju ẹgbẹ ninu eto idibo Gomina to n bọ nipinlẹ Osun.
Ẹwẹ, ninu lẹta kan ti akọwe ẹgbẹ oṣelu PDP buwọlu, tẹnu mọ pe eto idibo abẹle lati yan ẹni ti yoo gbe asia ẹgbẹ ninu eto idibo Gomina yoo waye gẹgẹ bii wọn ṣe ti daba rẹ ni ile gbọngan Atlantic multipurpose Hall niluu Osogbo.
Ninu lẹta miiran, ti wọn buwọlu lọjọ kẹrin oṣu kọkanla ọdun 2025, Gomina ipinlẹ Osun, Ademola Adeleke, ni oun ti kuro ninu ẹgbẹ oṣelu PDP, to si ṣalaye idi rẹ.
Lẹta ọhun to kọ ransẹ si alaga ẹgbẹ oṣelu naa ni wọọdu Sagba niluu Ede, Adeleke ni igbesẹ ohun da lori gbogbo rogbodiyan to koju ẹgbẹ naa lasiko yii. n.
"Nitori rogbodiyan olori to n da ẹgbẹ oṣelu PDP laamu, mo n fi asiko yii kọwe kuro gẹgẹ bii ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP lẹsẹkẹsẹ.
"Mo dupẹ lọwọ ẹgbẹ oṣelu People's Democratic Party fun anfani ti wọn fun mi gẹgẹ bii Sẹnetọ to n soju Osun West ati gẹgẹ bii Gomina ipinlẹ Osun."
Ki lo sẹlẹ ṣaaju?
Ninu oṣu keju, Gomina Ademọla Adeleke sọ pe oun ati awọn alaṣẹ ẹgbẹ oṣelu PDP ni ipinlẹ Ọṣun ti gba lati ṣe atilẹyin fun Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu fun saa keji ni ipo aarẹ Naijiria.
Gomina Adeleke sọ eyi ninu atẹjade kan to fi sita loju opo ayelujara X rẹ ninu eyi to ti sọ pe oun atawọn atukọ ẹgbẹ oṣelu naa ni ipinlẹ ṣe ipinnu yii lẹyin ifikuluku ọpọlọpọ ọsẹ pẹlu awọn obalaye, awọn oṣiṣẹ ijọba atawọn iyalọja ati babalọja kaakiri ipinlẹ naa.
Bakan naa lo fi kun un awọn eeyan wọnyii pẹlu ti buwọlu oun gẹgẹbi oludije ẹgbẹ oṣelu naa fun eto idibo ọdun 2026, eyi to ti pada kuro ninu ẹgbẹ naa bayii.
Atẹjade ọhun ti wọn fi sita lẹyin ijiroro ati ifikuluku naa to waye ni ile ijọba ipinlẹ Ọṣun niluu Oṣogbo sọ pe lara awọn nnkan ti wọn ro mọ Aarẹ Tinubu lara ti wọn fẹ fi tii lẹyin bayii ni pe ọmọ onilẹ loun naa ni ipinlẹ Ọṣun.
Atẹjade naa fi kun un pe lootọ lọrọ didarapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC jade eleyi ti awọn kan ni ẹgbẹ oṣelu APC ko fara mọ, ṣugbọn kii ṣe gomina Adeleke funrarẹ "lo gbe erongba ati dara pọ mọ APC dide"
"Ọpọlọpọ awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP ni ko fara mọ didarapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC, wọn kọ titori ifẹ ati ijolootọ si iṣakoso gomina , fẹ tẹle igbesẹ naa ni"
Lẹyin ipade wọn ọhun, awọn adarigbẹ oṣelu naa gba lati ṣe atilẹyin fun aarẹ Tinubu fun saa keji nitori "ipinlẹ Ọṣun ni ipinlẹ abinibi rẹ…"
Bakan naa ni wọn pinnu pe gomina Adeleke yoo dije fun ipo gomina lọdun 2026 labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu PDP lọdun 2026.