Wo àwọn ibi tí o ti lè yí ọkọ̀ rẹ padà láti èyí tó ń lo bẹntiró sí gáàsì CNG

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Latari bi epo bẹntiro ṣe gbowo lori kaakiri Naijiria ti ko si si ireti pe owo epo naa yoo pada walẹ, ijọba ti rọ awọn araalu lati bẹrẹ si n lo gaasi Compressed Natural Gas, CNG, ninu ọkọ wọn.

Gaasi naa ni yoo dipo epo bẹntiro ti ọpọ n lo lonii, amọ wọn kọkọ gbọdọ ṣe ayipade ọkọ wọn si eyii ti yoo maa lo gaasi CNG ọhun.

Fun di eyii, ijọba ti wa kede ibi mẹfa ti awọn eeyan ti le lọ yi ọkọ wọn pada lati eyii to n lo bẹntiro si CNG.

Kọmiṣọna fun irinkerinde ọkọ nipinlẹ Eko, Oluwaseun Osiyemi lo fi ọrọ naa lede loju poo X rẹ nibi to ti sọ pe igbimọ ti ijọba apapọ gbe kalẹ nipa ọrọ CNG ọhun lo ṣagbatẹru eto naa.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, lati ọjọ kẹtala, oṣu Kẹsan an, ọdun 2014 yii ni wọn bẹrẹ eto ọhun lati aago mẹta ọsan si mẹfa irọlẹ.

O fi kun pe ẹni to ba yara ni ogun yoo gbe lori ọrọ naa.

Osiyemi fi kun pe ọkọ aadọta akọkọ to ba kọkọ yọju si ojukọ naa to si pegede lẹyin ayẹwo yoo janfani ayipada lati bẹntiro si CNG ọfẹ.

Iwọnyii lawọn ibi ti o ti le yi mọto rẹ pada si CNG niluu Eko

Femadec

Km 42, Lekki-Epe Expressway, Majek Second Gate Stop, Abiju Ibeju, Lekki, Lagos.

Portland

No. 1, Ojota Interchange Terminal, Bayo Shodipo, Ojota, Lagos.

Mezovest

KM 23, Lekki-Epe Expressway, Ajah, opposite Kilimanjaro, beside Libmat Motors, by Abraham Adesanya Bus Stop.

Dana Motors

Dana Motors Ltd Kia Plaza, 117 Oshodi-Apapa Expressway, Isolo, Lagos.

MBH Power

Km 5, Ikotun Road, Itamope, Ikorodu, Lagos.

Autogig

Plot 144b Gbagada Expressway, Gbagada, Lagos.

Ki ni CNG?

CNG ni gaasi ti eeyan le lo ninu ọkọ dipo epo bẹntiro.

Awọn ọkọ kan wa to jẹ CNG ni wọn ṣe fun lati maa lo lati ibẹrẹ, amọ o ṣeeṣe lati yi ọkọ pada lati bẹntiro si CNG ọhun.

Ẹni to ba fẹ yi ọkọ rẹ pada si CNG yoo nilo awọn ohun elo fun ayipada, lara ni silinda wa.

Elo ni eeyan yoo na lati yi ọkọ rẹ lati bẹntiro pada si CNG?

Ninu ifọrọwerọ pẹlu ileeṣẹ iroyin Daily Trust lọdun 2023, olori igbimọ ijọba apapọ (P-CNGi) lori ọrọ naa, amojuẹrọ Michael Oluwagbemi ni yoo na araalu to N300,000 si N600,000 lati yi ọkọ wọn pada si CNG.

O ni eyii da lori iye owo ti wọn n parọ owo dọla si naira latari pe oke okun ni wọn ti n ko awọn ohun elo ti wọn fi n ṣe ayipadfa naa wọle.

Wayi o, ijọba apapọ ti fi ẹgbẹrun kan awọn ohun elo ti wọn fi n yi ọkọ pada si CNG ṣọwọ si awọn ipinlẹ.

O ni afojusun oun ni lati yi milọnu mẹta ọkọ pada si CNG laarin ọdun mẹta si asiko yii.

Ijọba sọ pe ṣiṣe eyii yoo tun pese ẹgbẹruin lọna ọọdurun iṣẹ frun awọn ọdọ.