Àjọ NAFDAC ń bèèrè ìdájọ́ ikú fún àwọn tó ń ta òògùn olóró

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ajọ to n mojuto lilo ati tita oogun ati ounjẹ ni NAFDAC ti bere fun idajọ iku fun awọn eeyan to n ta oogun oloro lawujọ.

Eyi ni ọrọ ti alaga ajọ naa, Mojisola Adeyeye sọ, o ni idajọ iku bayii yoo jẹ ki ọpọ yago fun tita awọn oogun eyi to n ṣekupa ọpọ ọmọde.

"Ẹnikan ra oogun ọmọde fun ẹgbẹrun mẹtala, elomii ra ni ẹgbẹrun mẹta ni ile itaja kankan," Adeyeye sọ eyi lasiko to n ba ileeṣẹ Channels sọrọ.

"Eyi fa ọpọ ariwo. Ẹ wa gbọ nnkan o. Ko si nkankan ninu awọn oogun naa nigba ti a se ayẹwo rẹ ni laabu wa to wa ni Kaduna. Fun idi eyi, mo fẹ idajọ iku.

"Nitori ẹ ko nilo lati fi ibọn si ọmọ lori ki ẹ to pa, ẹ kan fun awọn ni awọn oogun yii," Adeyeye ṣalaye.

Adeyeye ni awọn ti n sisẹ pọ pẹlu ile igbimọ aṣofin ati ẹka idajọ lorilẹede Naijiria lati mu idajọ naa wa si imusẹ.

"A ko le da ja ija gbigbe oogun oloro yii lasan. Ẹka NAFDAC n sa gbogbo agbara rẹ ṣugbọn ti a ko ba ri iranlọwọ, wahala yoo wa.

"Ẹ ni kan ra oogun oloro Tramdol to le sekupa ẹnikẹni, ẹ wa fun eeyan bẹ ni ẹwọn ọdun marun un tabi ko san owo itanran N250,000. Tani ko mọ pe eeyan bẹ yoo san san N250,000 ni kiakia.

"Ọkan lara iṣoro wa niyẹn. Ko si ofin to mulẹ ti yoo sẹruba awọn eeyan lati ma se nnkan yii mọ. A n sa gbogbo agbara ṣugbọn ti ofin wa ko ba le to, a ma ni iṣoro.

"Ile idajọ ni lati gbe igbesẹ. A n sisẹ pẹlu ile igbimọ aṣofin lati fi idi ofin yii mulẹ. To ba le ṣekupa ọmọde pẹlu oogun ti ko da, o jẹ ibi iku."