You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Mọ̀ nípa ìlànà ètò ẹ̀kọ́ tuntun ''12-4'' tí yòó da ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ àti girama pọ̀ èyí tí ìjọba ń gbèrò
Ijọba apapọ n gbero lati sẹ agbekalẹ eto ẹkọ tuntun '12-4' eyi ti yoo jẹ kawọn akẹkọọ maa lo ọdun mejila nile ẹkọ lai si idaduro lati igba ti wọn ba ti wọle ile ẹkọ alakọọbẹrẹ.
Nigba ti o n sọrọ nibi ipade ajọ NCE to n ri si ọrọ eto ẹkọ ni Naijiria l'Ọjọbọ niluu Abuja, Minisita eto ẹkọ, Tunji Alausa, sọ pe irufẹ eto ẹkọ yii yoo fawọn akẹkọọ lanfaani lati kẹkọọ lai si idaduro kankan fun wọn di igba ti wọn yoo fi pe ọdun mẹrindinlogun.
Ọgbẹni Alausa ni eto ẹkọ '12-4' wa ni ibamu pẹlu irufẹ eto ẹkọ ti ọpọ orilẹede agbaye n lo.
Ilana ẹkọ '9-3-4' ti Naijiria n lo lọwọ
Irufẹ eto ẹkọ ti orilẹede Naijiria n lo lọwọ ni o pin si '9-3-4 eyi to tumọ si pe akẹkọọ yoo gba iwe ẹri ile ẹkọ alakọọbẹrẹ lẹyin to ba lo ọdun mẹfa tan nile ẹkọ alakọọbẹrẹ.
Lẹyin ile ẹkọ alakọọbẹrẹ ni akẹkọọ yoo tẹsiwaju lọ ile ẹkọ girama ọdun mẹta akọkọ.
Akẹkọọ yoo ṣe idanwo lati wọ ipele keji nile ẹkọ girama eyi ti yoo fi ṣe idanwo aṣekagba oniwe-mẹwaa ti wọn n pe ajọ WAEC ati NECO n ṣagbatẹru rẹ.
Ọdun mẹrin ni ipele to kẹyin eyi ti akẹkọọ yoo lo ni ile ẹkọ giga fasiti lẹyin ti akẹkọọ ba ti yege ninu idanwo aṣekagba ilẹ ẹkọ girama.
Ilana eto ẹkọ '12-4' ti ijọba n gbero ati anfaani rẹ
Ilana eto ẹkọ '12-4' ti minisita eto ẹkọ ni Naijiria fẹ kawọn akẹkọọ maa lo yoo da ile ẹkọ alakọọbẹrẹ ati girama papọ ti ko si ni idaduro fawọn akẹkọọ mọ lẹyin ti wọn ba pari iwe mẹfa akọkọ tan.
''Lilo ọdun mejila nile ẹkọ lai ni idaduro yoo jẹ ki eto ẹkọ Naijiria gberu si tori ko ni si idaduro fawọn akẹkọọ rara lẹnu ẹkọ wọn.
Ilana eto ẹkọ '12-4' yoo tun jẹ kawọn akẹkọọ maa gba ẹkọ to ye kooro si, bakan naa si ni ilana yii yoo tun jẹ kawọn to ni imọ ẹkọ pọ si ni Naijiria eyi yoo si jẹ ki ọrọ aje Naijiria pọ si.
Eto ẹkọ yii yoo tun mu adinku ba ọpọ akẹkọọ ti wọn kii le pari eto ẹkọ wọn tori ko ni si idaduro fun wọn lẹnu ẹkọ wọn nigba kankan ti wọn yoo fi pari ẹkọ girama mọ,'' Minisita eto ẹkọ ṣalaye.
Ajọ NCE tawọn kọmiṣọna eto ẹkọ ni gbogbo ipinlẹ mẹrinlelọgbọn ati Abuja to fi mọ awọn adari oniruuru jẹ ọmọ ẹgbẹ rẹ yoo tun jiroro lori aba yii.
Akẹkọọ to ba ti pe ọdun mẹrindinlogun lo le wọ fasiti
Minisita eto ẹkọ n gbero wi pe akẹkọọ to ba fẹ wọ ile ẹkọ giga gbọdọ pe ọdun
Ti ẹ o ba gbagbe, minisita eto ẹkọ tẹlẹ, Tahir Mamman, paṣẹ fun ajọ JAMB atawọn ile ẹkọ giga lati ma gba akẹkọọ ti ko ba to ọdun mejidinlogun wọle.
Mamman ṣalaye pe o yẹ ki ọmọ to ba fẹ wọ ile ẹkọ alakọọbẹrẹ pe ọdun mẹfa eyi to tumọ si pe yoo pari ile ẹkọ alakọọbẹrẹ lẹni ọdun mejila.
O ni iru akẹkọọ naa yoo pe ọdun mejidinlogun nigba to ba lo ọdun mẹfa nile ẹkọ girama ko to wọ ile ẹkọ giaga fasiti.
Amọ, ọpọ eeyan ati oniruuru ajọ lo tako erongba yii, bo tilẹ jẹ pe ijọba faye gba awọn akẹkọọ ti ko ju ọdun mẹrindinlogun lọ ti wọn ti se idanwo ati wọle si fasiti fun ọdun 2024.
Ṣugbọn minisita eto ẹkọ tuntun yi eto naa pada nigba ti o rọpo Mamman, o si sọ pe akẹkọọ to ba ti pe ọmọ ọdun mẹrinlogun le wọ ile ẹkọ giga.