Ọdún méjì ìṣèjọba Tinubu ló burú jù nínú ìtàn ìjọba àwaarawa ní Naijiria - Dalung

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Minisita tẹlẹ fun ọdọ ati ere idaraya lorilẹede Naijiria, Solomon Dalung, ti ṣapejuwe ọdun meji aarẹ Bola Tinubu gẹgẹ bii ti ko da rara fun orilẹede Naijiria.

Dalung sọ eyi nigba to n ba BBC sọrọ lori ayajọ ijọba awarawa ati ayẹyẹ ọdun mẹrindinlọgbọn iṣejọba ijọba awarawa lorilẹede Naijiria.

O ni ohun kan ti awọn ọmọ orilẹede Naijiria le sọ nipa iṣejọba Bola Tinubu ni pe awọn dupẹ pe awọn wa laaye.

" Ọwọngogo gbode, iṣẹ, ebi ati inira awọn ẹsọ alabo, gbogbo eyi lo ṣokunfa inira fun araalu," o sọ.

Solomon Dalung ni awọn ti ko ri ọwọ mu si ẹnu lorilẹede Naijiria n padanu ẹmi wọn nitori ebi ti ijọba Tinubu mu wa si orilẹede Naijiria.

Dalung tun bu ẹnu atẹlu bi ijọba Tinubu ṣe yọ owo iranwọ epo bẹntiroolu lai pese ọna lati fi di fun araalu ti yoo mu nnkan rọrun fun wọn.

"Pẹlu bi inira ṣe pọ to, nigba ti wọn bi Tinubu, o ni oun ko kabamọ pe oun yọ owo epo bentiroolu".

Ọpọ igba ni ijọba Bola Tinubu ti jẹ ko di mimọ pe igbesẹ yiyọ owo epo bentiroolu ṣe pataki fun ọrọ aje orilẹede Naijiria lọjọ iwaju.

Ijọba Tinubu ki ṣe fun awọn alaini rara

Solomon Dalung ni iṣejọba Tinubu fun ọdun meji ti fihan bayii pe ijọba naa ko si fun awọn ọmọ Naijiria to jẹ alaini ati pe awọn ọmọ Naijiria ko ti ri pato anfani ti yiyọ owo iranwo epo rọọbi ti mu wa lati igba ti wọn ti yọ kuro.

"Lẹyin ipiparọ baalu ati ọkọ, kikọ ile fun igbakeji rẹ, n ko ti ri ipa ijọba Tinubu fun ọdun meji," o sọ.

Ipo ti ijọba awarawa wa lorilẹede ko da rara

Minisita ọhun tun tẹsiwaju pe ọdun meji iṣejọba Aarẹ Tinubu ti mu ọpọ idojukọ ba ijọba awarawa, eyi to ni o jẹ akọkọ ninu itan orilẹede Naijiria.

O tun fẹsun kan ijọba pe o lọwọ ninu bi awọn agbofinro ṣe mu awọn ajafẹtọ ọmọniyan si ahamọ.

Bakan naa ni Dalung ni ijọba to wa lode yii n saa ipa lati ra awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu alatako ki wọn le darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu rẹ.