You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Wo ìlú tí o ti lè dèrò ẹ̀wọ̀n bí o bá mú ajá jáde síta
Awọn ẹranko kan wa ti wọn jẹ ẹranko ti ko mọ, ti wọn si ri nini wọn gẹgẹ bii iwa ọlaju lawujọ.
Fun idi eyi, mimu awọn ẹranko naa rin sita le fa ki agbofinro gbe eeyan tabi ko san owo itanran.
Ni orilẹede Iran, nibi ti ẹṣin Musulumi ti gbinlẹ, sinsin ẹranko, paapa aja, tako ofin ẹsin Islam.
Olori orilẹede Iran, Ayatollah Ali Khamenei, ẹni to ni yatọ si pe ki a pa Aja tabi ni fun ipese eto aabo, ko si aaye fun aja sinsin nilẹ naa.
Orilẹede Iran ti fofin de mimu aja rin nita gbangba, o kere tan, ni ilu mejidinlogun kaakiri orilẹede naa.
Bakan naa wọn tun fi ofin de gbigbe awọn ẹranko sinu ọkọ fun irinajo.
Aja ati imọ toto
Nini aja ni ijọba gbagbọ pe o tako imọ toto, ti ofin naa si wa lati ọdun 1979.
Igbagbọ wọn ni pe iwa ilẹ Okere ni ọpọ n wu pẹlu bi wọn ṣe ti n sin aja.
Pẹlu gbogbo igbiyanju ijọba lori ofin yii, alekun n ba awọn to n sin aja, paapa laarin awọn ọdọ, ti wọn si ri wọn gẹgẹ eeyan to n tako ofin ẹṣin Islam.
Gẹgẹ bii AFP news agency ṣe gbe sita, awọn ilu Isfahan ati Kerman gbe ofin tuntun jade ni ẹnu ijọ mẹta yii.
Ijọba ni awọn yoo bẹrẹ si ni ma gbe igbesẹ lilọ ile ẹjọ fi gbe ogun ti awọn to b alu ofin naa, ti wọn si jiya labẹ ofin.
Mimu ofin wa si imusẹ ni ko ri ẹsẹ fi mulẹ fun ọpọ igba, ti a si ri ọpọ eeyan to ni aja, ti wọn n mu sita fun irin nita gbangba ni Tehran ati awọn ilu mii ni Iran.
Islam ati aja nini
"Mimu aja rin le wu pupọ fun alaafia ati eto ilera ilu ," Abbas Najafi, sọ fun ileeṣẹ iroyin kan fun apẹẹrẹ.
Ni igba miiran, awọn olowo aja ti bọ sọwọ awọn agbofinro, ti wọn si fẹsun kan wọn lori mimu aja rin
Awọn oloṣelu ni iṣejọba Ayatollah ri ohun ti awọn to n sin aja ṣe gẹgẹ bii itapa si ofin Islam.
Ọpọ onimọ ẹṣin ti sọrọ lori bi itọ aja ṣe le ba imọ toto ara jẹ.
Ni ọdun 2010, Ẹka ijọba Iran to n risi aṣa ati iṣe fofin de ipipolowo ounjẹ aja ati awọn nnkan mii to ṣomọ aja sinsin.
Ni 2014, ile igbimọ aṣofin gbe ofin sisan owo itanran ati lilu awọn olowo aja sita ṣugbọn wọn ko buwọlu ofin naa.
Awọn agba to ba BBC sọrọ ni ọpọ igba ni ọlọpaa ti mu awọn eeyan lori ẹsun mimu ajar in tabi gbigbe sinu ọkọ.
Ashkan Shemirani,ni ijọba tun ṣe idasilẹ ọgba ẹwon kekere fun awọn ẹranko yii,ti wọn yoo sig be wọn pamọ fun ọpọ ọjọ lia fun wọn ounjẹ tabi omi, ti awọn olowo wọn si n koju ile ẹjọ.
Ni ọdun 2021, aṣofin 75 fofin de olowo aja, ti wọn si ri iwa sinsin aja gẹgẹ bii to lodi si ofin ati iwa Iran.
Owo toto $800 ni eeyan ma san fun gbigba ẹranko wọle lati oke okun, tita, ati nini awọn ẹranko bii Aja, Ologinni, Ijapa ati Eworo. Koda wọn darukọ Ọọni.
Bakan naa ni wọn kede pe ki gbogbo olowo aja lo gbe awọn aja naa si ile awọn ẹranko Zoo tabi ki wọn ju wọn sinu nu si jinarere.
Ọpọ araalu lo ti tako igbesẹ yii ti wọn si kesi ijọba lati mojuto ohun to ṣe pataki to n ba ilu naa ja bi iwa ibajẹ to n ba wọn finra ju aja nini lọ.