A ń gbọ́ pé nítorí àwọn olùdókòwò kan láti China nìjọba fi ń wó ṣọ́ọ̀bù wa ní Alaba – Adarí ọjà Alaba

Gẹgẹ bi ileri rẹ lati da awọn ile itaja to ti n di ẹgẹmiti wo lọja nla Alaba to wa nilu Eko, ijọba ipinlẹ Eko ko awọn katakata rẹ wọ ọja naa lọjọ Aje.

Gẹgẹbi iroyin oju mi to ti akọroyin BBC News Yoruba mu bọ nibẹ nnkan bi agogo mejila Ọsan lawọn katakata naa bẹrẹ si ni da awọn ṣọọbu to ti di pakute ijamba naa wo.

Amọṣa alaga gbogbo awọn ẹgbẹ ọlọja ni ọja Alaba, Ọgbẹni Nbọnu Tochukwu Geoffery sọ pe ilana ti ijọba ipinlẹ Eko n gbe ọrọ gba lori ọja Alaba ru awọn loju.

Ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC News Yoruba, Nbọnu Tochukwu Geoffery ṣalaye pe ọsẹ meji ni gbendeke ti ijọba fun awọn ati pe gbogbo iwe ti wọn beere fun lori ọpọ awọn ile naa.

O ni ohun ti awọn n gbọ ni pe ijọba atawọn oniṣowo kan lati orilẹede China ti jọ ni ajọsọ pọ ọrọ lati kọ awọn ṣọbu itaja nlanla lọja naa.

O ni ohun ti ijọba sọ ni pe awọn ṣọọbu to ti di panpẹ iku nikan ni wọn fẹ wo, ṣugbọn ọrọ naa yi pada nigba ti wọn ko katakata de ti wọn si n wo awọn ile miran to duro daadaa.

‘Awọn kan lo n da ofin ara wọn pa l'ọja Alaba’

Ọkan lara awọn adari ọja naa Nnamdi Amaju ni gbogbo awọn to yẹ ni pipe lawọn ti pe ati pe ọrọ naa fẹ da bi eyi to lọwọ kan oṣelu ninu.

Oloye Amanju fi kun un pe awọn kan lọja naa ni wọn n da aṣẹ ara wọn pa laifi ọrọ to awọn alaṣẹ ọja Alaba leti to fi di eyi ti gbogbo ara ọja n jiya rẹ.

O tun rọ awọn ontaja lọja naa lati fiye denu ki wọn si kọ eti ikun si awọn to n sọ pe gbogbo ọja naa ni wọn fẹ wo.

‘Lootọ ni wọn ti fun wa ni gbendeke lati ọdun 2016’

Bakan naa lara awọn ontaja lọja naa ti ṣọọbu wọn fi ara gba ninu igbesẹ naa ṣalaye fun BBC News Yoruba pe lootọ ni pe ijọba ipinlẹ Eko ti fi gbedenke ṣọwọ si awọn tẹlẹ.

“O ni awọn ile kan to ti n wo lapa ẹyin, ṣugbọn (idi ti wọn fi n wo awọn ti iwaju yii) ko ye wa. Ko si ohun to buru pẹlu wiwo awọn to wa lẹyin yẹn, ṣugbọn ti awọn ti ita yii ti wọn wo ni ko ye wa.”

Ọpọ awọn ontaja naa lo ni pẹlu bi ọrọ ṣe ri bayii awọn ko mọ ibi ti awọn yoo patẹ ọja awọn si bayii pẹlu wiwo ti wọn wo awọn ṣọbu naa.

Wọn ni awọn ṣi n reti awọn ilana ti ijọba yoo gbe lati ṣeto iranwọ fun awọn ti iṣẹlẹ naa ba.

Gbagbagba lawọn agbofinro wa nikalẹ lasiko ti wọn fi n da awọn ṣọọbu naa wo lati rii pe awọn janduku ko yi i pada si nnkan miran to le da omi alaafia agbegbe naa ru.

Irọ́ ni wọ́n ń pa lórí ayélujára, ìgbésẹ̀ Sanwo-Olu kò kan ẹ̀yà Igbo ní Alaba - Ohanaeze Ndigbo

Ẹgbẹ awọn ẹya Igbo lagbaye, Ohanaeze Ndigbo ti fesi ori awuyewuye ati iroyin ofege to n jade pe wọn sọrọ si bi ijọba ipinlẹ Eko ṣe fẹ wo awọn ile itaja kan ninu Ọja nla Alaba to wa ni ipinlẹ naa.

Lẹyin ti igbesẹ bẹrẹ latọdọ ijọba ipinlẹ Eko lati wo awọn ile to ti dogbó ni ọja Alaba ni awọn eeyan bẹrẹ si ni gbe iroyin kiri ti wọn si n fẹsun kan wipe igbesẹ naa jẹ lati ṣe ika fun awọn ẹya Igbo to wa ni ipinlẹ Eko ni.

Ẹwẹ, Aarẹ ẹgbẹ Ohanaeze Ndigbo, Oloye Emmanuel Iwuanyanwu fesi si iroyin naa to gba ori ayelujara kan lọjọ Aiku to si rọ awn ẹya Igbo to wa ni ilu Eko lati fara balẹ wipe ki wọn ma gbọ iroyin irọ to n lọ kaakiri toripe ko wulo fun wọn ni akoko yii.

“Iwadi wa fihan pe awọn iroyin to jade yii, ofege ni wọn bẹ si ni wọn n gbe wọn jade lati ru ọkan soke ati lati wu irira soke laarin awọn Igbo atawọn ara ipinlẹ Eko to gba wọn sile ni.”

Gẹgẹ bi Iwuanyanwu ṣe sọ ọ, ojulowo iroyin to tẹẹ lọwọ fihan pe aṣẹ ijọba ipinlẹ Eko ko fi ọna kankan jọ ohun tawọn eeyan n gbe kiri.

Ninu atẹjade ti akọwe ẹgbẹ naa, Ọmọwe Alex Ogbonnia fi sita lọjọ Aiku sọ pe: “Lati igba ti iroyin adanilọkanru ọhun ti jade, a ti ṣe iwadii lati fidi ohun to jẹ otitọ gan mulẹ ti ọkan lara awọn ta le gba ọrọ wọn gbọ, Họnọrebu Comrade Chinedu Ukatu to jẹ ọmọ igbimọ to n gba ijọba nimọran lori ọrọ ọja ni Eko to si tun jẹ aarẹ ẹgbẹ itẹsiwaju ọlọja to jẹ ẹya Igbo sọ pe “Ileeṣẹ to n ri si ọrọ idagbasoke ayika ni Eko ti n fi ikilọ sita tipẹ lori awọn oju ọna omi kan.”

“Ukatu fikun un pe: “Gbogbo ohun to ṣẹlẹ ni ọja Alaba to fi mọ ibẹwo pajawiri ti awọn oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ Eko ṣe nii ṣe pẹlu didi ọna ti omi n gba ṣan kọja daadaa ni”.

O wa rọ awọn eniyan lati kọ eti ikun si gbogbo iroyin ti wọn n gbọ kaakiri lori ayelujara to si rọ awọn araalu pe iru iroyin ibanilorukọjẹ yii ko dara to fun awọn ẹya Igbo lasiko yii.

Ẹwẹ ẹlomiran to n gbe ni agbegbe Alaba, Oloye Ikechukwu Okolo sọ pe: “Otitọ ibẹ ni pe awọn ile kan wa ti wọn kọ le oju gọta to yẹ ki omi maa gba kọja eyi to n ṣe idiwọ fun ṣiṣan omi to si le fa omiyale paapaa lasiko ojo”.

O ni wọn ti sọ fun awọn to ni awọn ile naa lati ọpọlọpọ oṣu sẹyin “amọ gbogbo igba ti asiko lati gbe igbesẹ ba ti to nia wọn alajẹbanu oṣiṣẹ ọba kan yoo tun gba ọjẹgẹ bẹẹ si ni ipenija omiyale n tẹsiwaju titi di asiko yii”.

Ìjọba Èkó bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ láti wó ọjà Alaba, àwọn òǹtàjà fọnmú

Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko ti kéde pé àwọn fẹ́ da ilé mẹ́tàdínlógún wo nínú ọjà Alaba tó wà ní ìjọba ìbílẹ̀ Ọjọ.

Ọ̀gá àgbà àjọ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ilé kíkọ́ Eko ìyẹn Lagos State Building Control Agency (LASBCA), Gbolahan Oki ló fi ìkéde náà síta nígbà tó ṣe àbẹ̀wò sínú ọjà náà lọ́jọ́ Ẹtì.

Oki ní láti ọdún 2016 ni àwọn ti ń ṣe ìkìlọ̀ fún àwọn olùgbé ilé náà, tí àwọn sì ti ń ṣe àmì si wí pé àwọn máa wó wọn àti pé àbẹ̀wò òun náà wáyé láti sọ fún àwọn tó ń gbébẹ̀ láti kó kúrò lẹ́yẹ ò sọkà.

Èyí ti ń mú kí àwọn ènìyàn máa pòkìkí ọjà Alaba, níbi tí wọ́n ti máa ń ta ohun èlò ilé bíi ẹ̀rọ àmóhùnmáwòrán, fírìjì àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ lórí ayélujára.

Àwọn ẹ̀yà Igbo ló pọ̀ tí wọ́n ń ta ọjà nínú Alaba tí àwọn kan sì ń sọ wí pé nítorí à ti gbẹ̀san ohun tó wáyé ní Eko lásìkò ìbò tó kọjá ló fa ìgbésẹ̀ ìjọba yìí.

Láti ọdún 2016 ni a ti ń ṣe ìkìlọ̀ fáwọn onílé ọjà Alaba - LABSCA

Ẹ̀wẹ̀, nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, Oki ní láti ọdún 2016, 2020, 2022 títí di ọdún yìí ni àwọn ti ń fún àwọn ènìyàn tó ni àwọn ilé náà ni ìwé pé kí wọ́n kúrò níbẹ̀.

Ó ní àkíyèsí ọdún méje náà tó láti fún àwọn tó ń gbé ibẹ̀ láti kúrò àmọ́ dípò kí àwọn ènìyàn náà gbọ́ ìkìlọ̀ níṣe ni wọ́n máa ń ṣe ìkọlù sí àwọn òṣìṣẹ́ àwọn tí wan bá ti dé ibẹ̀.

Bákan náà ló ṣàlàyé pé àwọn ilé náà kò bá wà lára àwọn ilé 349 tí àwọn fi léde ní ìb€rẹ̀ ọdún yìí pé àwọn fẹ́ wó àmọ́ nítorí àwọn kìí ríbi ṣe iṣẹ́ àwọn tí àwọn bá dé ibẹ̀ nítorí ìkọlù tí wọ́n máa ń ṣe sí àwọn òṣìṣẹ́ àwọn kò jẹ́ kí àwọn le fi wọ́n sínú rẹ̀.

“Ohun tí à ń ṣe báyìí ni láti ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn ikọ̀ “Task Force” Eko láti lè ri wí pé á ri àwọn ilé náà wó palẹ̀ lọ́tẹ̀ yìí.

“Ó pọn dandan fún wa láti wó àwọn ilé náà báyìí nítorí wọ́n ti di ẹgẹrẹ mìtì, tí wọ́n sì lè ṣe àkóbá fún àwọn ilé mìíràn tó wà ní agbègbè wọn àti àwọn tó ń ta ọjà níbẹ̀ pàápàá.”

Oki fi kun pé ìjọba yóò tẹ̀síwájú láti máa pàtàkì ẹ̀mí àwọn olùgbé ìpínlẹ̀ Eko láì ẹ̀yà tàbí ohunkóhun ṣe, kí ìgbé ayé le rọrùn fún mùtúmùwà.

A ò rí ìwé ìkilọ̀ kankan látọ̀dọ̀ ìjọba - Ẹgbẹ́ àwọn ọlọ́jà fèsì

Agbẹnusọ ẹgbẹ́ àwọn tó ń ta ọjà nínú Alaba International Market, Theo Ezeani sọ fún BBC Igbo pé ìgbà àkọ́kọ́ rèé tí àwọn ń gbọ́ pé ìjọba fẹ́ wó àwọn ilé kan nínú ọjà náà.

Ezeani ní àwọn kò rí ìwé ìkìlọ̀ kankan láti ọdún 2016 èyí tí ìjọba ní àwọn fi ṣọwọ́.

Ó ní òun gẹ́gẹ́ bí agbẹnusọ kò mọ̀ nípa ìwé tí ìjoba ní àwọn ti ń kó ránṣẹ́ tó sì jẹ́ ohun ìyàlẹ́nu fún òun nítorí ó ti pẹ́ tí òun ti wà nínú ọjà náà.

“Kò sí pigbà kankan tí a sọ ohun tó bẹ́ẹ̀ nínú àwọn ìpàdé wa, àwọn tí a gba ipò lọ́wọ́ wọn náà kò sọ ohun tó jọ bẹ́ẹ̀ fún wa, lórí amòhúnmáwòrán ni mo ti kọ́kọ́ rí ìròyìn náà lálẹ́ ọjọ́ Ẹtì. ”

Ezeani ní ó ṣeéṣe kó jẹ́ wí pé àwọn tó ni ilé gangan ni ìjọba kọ̀wé ránṣẹ́ sí àmọ́ àwọn tí àwọn ń ta ọjà níbẹ̀ kò gbọ́ nǹkankan.

Ó ṣàlàyé pé àwọn ọlọ́jà ti bẹ̀rẹ̀ sí ní kó ẹrù wọn kúrò níbẹ̀ nítorí ohun tí àwọn gbọ́ ni pé ọjọ́ Ajé, ọjọ́ Kọkàndílógún, oṣù Kẹfà ni ìjọba yóò bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ wíwó àwọn ilé náà.