Ìwọ̀nyí ni orílẹ̀èdè mẹ́wàá ní Afrika tí wọ́n ya òbítíbitì owó sọ́tọ̀ fún ètò àbò wọn

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

1. Egypt

Awọn ọmọ ogun Egypt

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Orilẹede Egypt jẹ ọkan lara awọn orilẹede to na owo to pọju si eto abo wọn lọdun 2025.

Iroyin to tẹ wa lọwọ fi han pe iye owo to le ni $5.88b ni orilẹede naa ko si ẹka eto abo rẹ.

2. Algeria

Awọn ologun Algeria ni awọn ti wọn jẹ akọmọṣẹ to maa n koju awọn ohun to ṣoro ti wọn n pe ni special forces.

A gbọ pe gbogbo igba ni ileeṣẹ ọmọ ogun naa wa ni digbi lati daabo orilẹede wọn lọwọ ipenija kankan.

Lọwọ yii, owo to le ni $25b ni wọn ko si ẹka eto abo orilẹede naa.

3. Naijiria

Awọn ọmọ ogun Naijiria

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Orilẹede Naijiria jẹ ọkan lara awọn orilẹede ti ọmọ ogun rẹ pọ julọ nilẹ Afrika.

Apapọ iye ọmọ ogun to n daabo bo Naijiria le ni 230,000.

A gbọ pe iye owo to le ni $3.16m ni Naijiria ya sọtọ fun eto abo rẹ.

4. South Africa

South Africa gbajumọ fun akinkanju awọn ọmọ ogun rẹ ti wọn si jẹ akọṣẹmọṣe lori ilẹ, lori omi ati loju ofurufu.

O ṣoro lati sọ ni pato iye owo ti orilẹede naa ya sọtọ fun eto abo rẹ amọ a gbọ pe o le ni $3.1m lọdun 2025 yii.

5. Ethiopia

Awọn ọmọ ogun Ethipia lagbara to bẹẹ ti awọn akẹgbẹ wọn lorilẹede mii ko fi ko iyan wọn kere.

Iroyin to tẹ wa lọwọ ni pe owo ti iye rẹ to $2.10b ni orilẹede naa ko le eto abo rẹ lori lọdun yii.

6. Angola

Awọn ọmọ ogun Algeria

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Angola ti ko owo to pọ le eto abo rẹ lori, awọn ọmọ ogun rẹ si lagbara.

Lara awọn ohun ti wọn gbajumọ fun ni eto abo orilẹede naa lati ilẹ okeere wa.

Lọdun yii, owo to iye rẹ to $1.1b ni wọn la kalẹ fun eto abo orilẹede naa.

7. Morocco

Yatọ si awọn ologun to pọ yanturu, Morocco tun ni oniruru ohun ija lati koju awọn ọta rẹ.

Lara awọn agbegbe ti ileeṣẹ ọmọ ogun naa n sọ ni alagbalugbu omi okun Mediterranean ati Atlantic.

Iroyin ni owo to le ni $13b ni wọn la kalẹ fun eto abo orilẹede naa lọdun yii.

8. DR Congo

Bo tilẹ jẹ pe orilẹee naa kere, awọn ọmọ ogun rẹ ko kere latari pe ọmọ ogun rẹ lo wa ni ipo kẹjọ eyii to tobi julọ ni Afrika.

$800m ni orilẹede naa ko si ẹka eto abo rẹ lọdun 2025 yii nikan ṣoṣo.

9. Sudan

Lọwọ yii ogun n lọ lọwọ ni Sudan amọ ileeṣẹ ọmọ ogun rẹ fẹsẹ rinlẹ ṣaaju ogun ọhun.

$342m ni orilẹede naa maa n ko si ẹka eto abo rẹ lọdọdun.

10. Libya

Libya lo wa ni ipo kẹwaa ninu ileeṣẹ ologun to lagbara ju ni Afrika.

Gẹgẹ bo ṣe wa ni Sudan, ipenija wa ni Libya bayii amọ ileeṣẹ ọmọ ogun rẹ fẹsẹ rinlẹ daadaa lasiko ijọba Aarẹ Muammar Gaddafi.

A gbọ pe nnkan bii biliọnu mẹta dọla ni wọn n na lori ileeṣẹ ọmọ ogun naa lọdọdun.