Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Osun fi òfin de kí ọlọ́kadà má a wọ ìbòmú àti ìbòrí

Ami idanimọ ileeṣẹ ọlọpaa

Oríṣun àwòrán, NIGERIAN POLICE FORCE

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun ti fi ofin de awọn ọlọkada lati ma a wọ ibomu ati ibori.

Ninu ikede kan to fi sita lori aṣẹ tuntun naa, agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun, SP Yemisi Opalola, sọ lọjọ Aje pe igbesẹ naa jẹ ọna lati mu fi opin si awọn iwa ọdaran to wọpọ nipa lilo ọkada.

SP Oplalola ni “ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun n fi asiko yii kilọ fun awọn ọlọkada to ma n wọ ibomu ati fila to ma n de oju, lati dẹkun ṣiṣe bẹẹ.”

O ni awọn ọlọkada to fi n gbe eero ni ọrọ naa kan julọ.

Agbẹnusọ ọlọpaa ṣalaye pe awọn pinnu lati gbe igbesẹ naa nitori oriṣiriṣi iroyin to tẹ ileeṣẹ ọlọpaa lọwọ, nipa bi awọn ọlọkada kan ṣe n wọ ibori to de oju, pẹlu erongba lati hu awọn iwa ọdaran bii ole jija, ifipabanilopọ, ati bẹẹbẹẹ lọ.

O ni wọn ṣaba ma n hu awọn iwa naa si awọn eero ti wọn ba gbe nigba ti ilẹ ti ṣú.

Ileeṣẹ ọlọpaa wa kesi awọn adari ẹgbẹ ọlọkada nipinlẹ Osun, lati kilọ fun awọn ọmọ ẹgbẹ wọn ki wọn o ma ba jiya ni abẹ ofin, ti ọwọ ba fi tẹ wọn pe wọn ko tẹle ilana tuntun ti ileeṣẹ ọlọpaa fun wọn.

Bakan naa ni SP Opalola tun kesi awọn araalu lati ma gun ọkada ti ẹni to wa a ba lo ibomu ati ibori.