Ìjàmbá ọkọ̀ mú ẹ̀mí èèyàn mẹ́rìndílógún lọ nílùú Eko, márùn ún jóná kọjá mímọ̀

O kere tan, eeya marun un lo ti jona kọja didamọ lẹyin ijamba ọkọ kan to waye niluu Alaro, to wa lagbegbe Epe, nipinlẹ Eko.

Afẹmọju ọjọ Iṣẹgun ni ijamba ọkọ naa waye ni nnkan bii aago mẹta oru.

Iroyin ni ọkọ akero funfun kan toun ti ọkọ mii ti wọn fi n ṣiṣẹ alagbara ni wọn fori sọ ara wọn ki ina to sọ.

Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, ina sọ lara awọn ọkọ mejeji ni kete ti ọkọ akero naa fori sọ ọkọ ti wọn fi n ṣiṣẹ naa tan ti awọn eeyan inu rẹ si jona gurugu.

Ninu atẹjade kan ti ọga agba ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri nipinlẹ Eko, LASEMA, Olufemi Damilola Oke-Osanyintolu fi sọwọ si awọn akọroyin, o ni awọn marun un to jona ninu ijamba naa jẹ ero to n bọ lati ipinlẹ Katsina.

Atẹjade naa ni “Nigba ti ikọ adoola ẹmi LASEMA de ibi ti ijamba naa ti waye, a ri pe ọkọ to n ko yẹpẹ ati ọkọ to ko ero mẹfa lo fori sọ ara wọn.”

“Bakan naa, ọkọ meji mii tun fara gba ninu ina ọhun lẹyin ti awọn ọkọ akọkọ fori sọ ara wọn, ọkunrin marun un to n bọ lati ipinlẹ Katsina lo ba ina ọhun lọ.”

Eeyan maẹrindinlogun lo ku nibi ijamba naa - FRSC

Ẹwe, ninu agtẹjade mii ti ajọ to n ri si kalọ-kabọ ọkọ loju popo, FRSC, fi lede, wọn ni eeyan mẹrindinlogun lo padanu ẹmi wọn ninu iṣẹlẹ ọhun.

Atẹjade naa ti Olabisi Sonusi buwọlu sọ pe ọkunrin mẹrindinlogun lo ku nibi ijamba naa, ti awọn marun mii si farapa yanayana.

Sonusi ni ọga agba ajọ naa niluu EKo, Olusegun Ogungbemide ba awọn mọlẹbi awọn to ba iṣẹlẹ naa lọ kẹdun.

Lẹyin naa lo kilọ fun awọn araalu pe ki wọn maa ṣọra fun irinajo oru ganjọ lọna ati le dena irufẹ ijamba bẹẹ lọjọ mii.