Ààrẹ láti ẹkùn gúsù Nàìjíríà ni mo fọwọ́sí fún ìdìbò 2023 – Obasanjo 

Aarẹ Naijiria tẹlẹ, Oluṣẹgun Obasanjọ ti sọ pe ayipada rere lo yẹ ki ero idibo odun 2023 jẹ fun Naijiria.

Bakan naa lo tun sekilọ pe bi awọn eeyan ba lọ n dibo nitori bi ara ṣe n ta wọn si, afaimọ ki nnkan ma bajẹ ju bi o ti wa tẹlẹ lọ.

Ọbasanjọ ni “bi o ba jẹ pe lootọ lorilẹede Naijiria ti ṣetan fun ayipada rere, ero idibo odun 2023 gan ni yoo sọ ibi ti okun yo wọ lara akeregbe.

”Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ rẹ Kẹhinde Akinyẹmi fi sita lọjọ Aiku, Oloye Ọbasanjọ ṣalaye fun igbimọ adari ẹgbẹ ọmọ bibi ẹya Tiv lati ipinlẹ Benue,

Mzough U Tiv to bẹẹ wo nilu Abeokuta pe ki ipo adari ṣi kuro ni apa oke oya Naijiria wa si ẹkun gusu ni oun fọwọsi,

ki ẹkun aringbungbun orilẹede Naijiria, MiddleBelt pẹlu maa gbaruku ti eto mọkanmọkan fun akoso Naijiria.

O rọ awọn ọmọ Naijiria lati ri Naijiria gẹgẹ bi orilẹede ajumọni lati da a pada si ipo ti Eledumare ṣẹda rẹ lati wa.

”Aarẹ Naijiria tẹlẹ naa wa tun tẹnu mọ pe pẹlu bi iye awọn eeyan ṣe n pọ si bayii lorilẹede Naijiria, epi rọbi ko le tan iṣoro rẹ mọ, afi ki kaluku gbaruku ti iṣẹ ọgbin ni sisẹ.

“Eto ọgbin nikan lo le koju iṣoro bi eeyan ṣe n pọ sii lorilẹede Naijiria bayii. Eto ọgbin nikan lo le bọ Naijiria.”