You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Àwọn nǹkan méje tí Peter Obi ní òun fẹ́ ṣe tó bá di Ààrẹ nìyí
Olùdíje sípò ààrẹ lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party, Peter Obi ti fi àkọ́lẹ̀ ohun tó fẹ́ ṣe tó bá di ààrẹ Nàìjíríà léde.
Ní orí ayélujára Twitter ni Peter Obi ti kéde àkọ́lẹ̀ àwọn nǹkan tó fẹ́ ṣe náà lọ́jọ́ Àìkú ọjọ́ Kẹrin, oṣù Kèjílà ọdún 2022 tó pe àkọ́lé rẹ̀ ní “Ó ṣeéṣe: ìdásílẹ̀ Nàìjíríà tuntun”.
Ṣaájú ni àwọn ènìyàn ti ń bèèrè pé kí ni ohun tó ń dá Peter Obi dúró láti kéde àwọn nǹkan tó fẹ́ ṣe fún àwọn ọmọ Nàìjíríà tó bá di ààrẹ lẹ́yìn tí àwọn olùdíje bí i Bola Tinubu, Atiku Abubakar, Omoyele Sowore ti fi ti wọn síta.
Kí ni àwọn nǹkan tí Peter Obi ní òun yóò ṣe?
Àwọn nǹkan méje ni Peter Obi ní òun máa gbájúmọ́ tí òun bá di ààrẹ Nàìjíríà èyí tó kọ sínú abala ìwé méjìlélọ́gọ́ta
Àwọn nǹkan náà nìyí:
- Mímú ètò ààbò Nàìjíríà ní ọ̀kúnkúndùn, ṣe ìdádúró àwọn agbébọn àti àwọn agbéṣùmọ̀mí, gba ìṣọ̀kan láàyè àti pé kò ní sí ẹnìkan tí ìjọba òun yóò fi ọwọ́ rọ́ sẹ́yìn.
- Yíyọ Nàìjíríà kúrò ní orílẹ̀ èdè tí kìí pèsè àwọn ọjá nípa ṣíṣe àtúnkọ́ àwọn ilé iṣẹ́ tó ń pèsè oúnjẹ àti ilé iṣẹ́ ńláńlá, tí Nàìjíríà náà yóò máa kó ọjà lọ sí òkè òkun dípò kíkó ọjá láti ilẹ̀ òkèrè wọ Nàìjíríà nìkan.
- Ṣíṣe àtúntò ìjọba nípa ìmúdúró ìbọ̀wọ̀ fún òfin, gbígógun ti ìwà àjẹ́bánu, mímú àdínkù bá owó tí wọn ń n’s sí ètò ìṣèjọba àti fífọ ẹ̀ka iṣẹ́ ọba mọ́ tónítóní
- Sísọ Nàìjíríà di ọ̀kan lára àwọn orílẹ̀ èdè tó ń dàgbà nípa lílo àwọn ìmọ̀ ẹ̀rọ àti sáyẹ̀ǹsì láti fi pèsè ètò ọrọ̀ ajé ìgbàlódé.
- Pípèsè àwọn ohun amáyédẹrùn tó gbé oúnjẹ fẹ́gbẹ́ gba àwo bọ̀ bí i pípèsè iná ọba, ètò ìrìnà ilẹ̀ àti ti ojú irin nípasẹ̀ àjọṣepọ̀ ìjọba pẹ̀lú àwọn aládani.
- Ìgbágbára wọ àwọn ọ̀dọ́ Nàìjíríà nípasẹ̀ pípèsè iṣẹ́ aládani, ètò ìlera tó péye, ẹ̀kọ́ tó yè kooro.
- Láti ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ òkèrè pàápàá àwọn orílẹ̀ èdè tó jẹ́ Áfíríkà láti dókoòwò papọ̀ àti láti dá ààbò bo àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tó wà ní ilẹ̀ òkèrè.