Àlàyé rèé lórí ìdí tí ìfẹ̀hónúhàn Ibadan, Kano àti Kogi fi peléke

    • Author, Nkechi Ogbonna
    • Role, BBC News, Lagos

Ọpọ araalu ni ko le ra ounjẹ mọ latari ọwọngogo to gbode kan ni Naijiira, eyii si ti n fa ifẹhonuhan lawọn ilu kan.

Lootọ ni kii ṣe Naijiria ni nnkan ti le koko, amọ ti Naijiria tun le kenka latari owo iranwọ ori epo bẹntiro ti Aarẹ Bola Tinubu fopin si lọdun to kọja.

Yatọ si owo iranwọ epo ti Aarẹ yọ, agbara owo naira tun n fi ojojumọ ja silẹ, eyii to n mu ki nnkan wọn si lojojumọ.

Ni Naijiria lonii, ti eeyan ba ra nnkan ni naira mẹwaa, iye ti wọn n ta nnkan naa le ti di naira mẹẹdogun tabi ogun naira lọjọ keji.

Ki lo n bi awọn ọmọ Naijiria ninu?

Ebi ọpagba to n pa araalu ni eredi pato ti inu awọn ọmọ Naijiria ko ṣe dun si ijọba lasiko yii.

Lẹnu ọjọ mẹta yii ni awọn eeyan tu si igboro nipinlẹ Niger, Kano, Kogi ati ilu Ibadan, nipinlẹ Oyo, nibi ti wọn ti ke si ijọba lati wa ojutu si ebi to n pa araalu lasiko yii.

Lọsẹ to kọja, ajọ oluṣiro Naijiria, NBS, sọ pe nnkan ti wọn si ni ida 29.9%.

Bawo ni ounjẹ ṣe wọn si bayii Naijiria?

Fun apẹrẹ, iye ti wọn ta buredi tẹlẹ ni ₦500, bayii burẹdi ti di ₦1,500 laarin ọdun kan.

Awọn ounjẹ mii bii ẹyin, ẹja, irẹsi, epo pupa, ororo, gari ati bẹẹ bẹẹ lọ lo ti gbowo lori.

Iwọn irẹsi 50kg ti fo soke lati ₦35,000 si ₦75,000.

Ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ, NLC, ti fun ijọba apapọ ni ọjọ mẹrinla lati wa ojutu si iṣororo naa, bi bẹẹ kọ, o ni wọde nla nbọ lọna.

Ẹwẹ, banki idagbasoke ilẹ Afrika, AfBD ti kede pe o ṣeeṣe ki rogbodiyan waye lorilẹ-ede Naijiria, to fi mọ Ethiopia, Angola ati Kenya, latari ọwọngogo owo epo ati ounjẹ laarin ilu.

Ki lawọn eeyan n ṣe bayii?

Awọn fidio ori ẹrọ ibanidọrẹ ti ṣafihan bi awọn eeyan ṣe n pin ounjẹ jẹ bayii.

Fidio kan tilẹ ṣafihan bi obinrin kan ṣe pin ẹja kan ṣoṣo si ọna mẹsan an ko le kari awọn ẹbi rẹ.

Ki ni ijọba n ṣe?

Igbakeji Aarẹ, Kashim Shettima ti kede ajọ kan ti yoo maa ṣakoso iye owo ti wọn n ta ounjẹ.

Ijọba apapọ tun ti paṣẹ ki wọn da ounjẹ ti iye rẹ to ẹgbẹrun mejilogoji tọọnu saarin ilu ki awọn eeyan le ri ounjẹ ra.

Ki ni nnkan mii ti awọn ṣe?

Awọn ileeṣẹ kan ti din iye ọjọ ti awọn oṣiṣẹ wọn yoo maa lọ si ibiṣẹ laarin ọsẹ ku.

Bẹẹ lawọn ileeṣe mii ti ṣe afikun iye owo oṣu oṣiṣe wọn ni ida 50%.