Ẹ dákẹ́ ogun jíjà ní Gaza - Amẹ́ríkà rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Israel níwájú àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé

Orilẹ ede Amẹrika ti da aba idaduro ogun laarin Israel ati Palestine ni ẹkun Gaza.

Amẹrika da aba yii niwaju igbimọ alaṣẹ ajọ iṣọkan agbaye UN.

Bakan naa ni Amerika tun kìlọ fun orilẹede Israel lati ma yabo ilu Rafah to kun akunfaya.

Amẹrika ko kọkọ gbe ọrọ didawọ ogun duro wo tẹlẹ, bo tilẹ lẹ jẹ pe Aarẹ Joe Biden ti mẹnu ba a.

Awọn eeyan to le ni abọ miliọnu kan eeyan Palestine eleyii to ju idaji awon olugbe Gaza lọ lo ti di ogunlende bayii niluu Rafah.

Eeyan 250,000 lo wa ni ilu Rafah ti o ni ibode pẹlu orilẹ ede Egypt ki ogun to bẹrẹ ni Gaza.

Israel doju ija kọ Gaza lẹyin ti ẹgbẹ Hamas ṣe ikọlu si apa guusu Israel lọjọ keje oṣu Kẹwaa, nibi ti ẹgbẹrun kan ati igba eeyan ti dero ọrun, ti wọn si tun ji ojilerugba eeyan lọ.

Ẹka ileeṣẹ ilera Hamas sọ pe Israel ti pa ẹgbẹrun mọkandinlọgbọn eeyan ni Gaza.

Amọ, iṣẹ yoo bẹrẹ lori aba ti Amẹrika da lọsẹ yii.

Ṣugbọn ko si ẹni to mọ bo ya ibo didi yoo waye lori aba ti Amẹrika da.

Ẹ ma gbagbe wi pe gbogbo igbesẹ to ba waye ni ajọ UN ko pọn dandan labẹ ofin.

Igba àkọkọ ree ti orilẹ ede Amẹrika yoo pe fun idaduro ogun ni ẹkun Gaza.

Amẹrika tun sọ pe kikọ oju ija si ilu Rafah yoo mu ipalara to pọ wa fawon araalu, yoo si tun jẹ ki ọpọ eeyan di ogunlende lawon orilẹ ede to wa ni ayika bii Egypt.

Aba idawọ ogun duro yii wa ni ibamu pẹlu ọrọ ti Aarẹ Biden sọ pẹlu Olootu ijọba Israel, Benjamin Netanyahu lọsẹ to kọja.

Ọgbẹni Netanyahu ti n kọ eti ikun s'awọn to n pe fun idawọ ogun duro, o ni oun gbọdọ doola awọn ọmọ Israẹli ti wọn jigbe, ati pe o fẹ pa ẹgbẹ Hamas run ni Gaza.

Ọmọ ẹgbẹ igbimọ ologun Israel kan, Benny Gantz kilọ pe awọn ko ni da ogun duro, ayafi ti Hamas ba tu gbogbo awọn ọmọ Israel ti wọn jigbe lọjọ Kẹwaa oṣu Kẹta.

Ọjọ naa ni awẹ Ramadan bẹrẹ.

Ajọ awọn orilẹ-ede Araabu ti sọ pe igbimọ alaṣẹ ajọ iṣọkan agbaye UN ko le tẹsiwaju lati maa kọ eti ikun si b'awọn orilẹ ede agbaye ṣe n pe fun idawọ ogun duro ni Gaza.