Ṣé lóòtọ ni ìjọba tún fẹ́ ẹ́ fi kún iye owó iná tí aráàlú n san?

Bo tilẹ jẹ pe eto n lọ lorii bi ijọba yoo ṣe mọ iye owo ti wọn fi n pese ina mọnamọna fun araalu, ti araalu naa ko si ni i sanwo to kere tabi to pọju fun ina ti wọn ba n lo, ijọba apapọ Naijiria ti kede pe oun ko lero lati fowo kun iye tawọn eeyan n san lasiko yii.

Ọjọ Aje, ọjọ kinni, oṣu Kinni, ọdun 2024, nijọba kede pe oun ti n ṣagbeyẹwo nipa bi oun yoo ṣe mọ iye owo to n ba ipese ina ọba lọ.

Ṣugbọn ko si ninu erongba ijọba lati yọwọ iranwọ rẹ kuro fawọn eeyan ti agbara ko fi bẹẹ si fun.

Minisita fun ọrọ ina mọnamọna ni Naijiria, Oloye Adebayọ Adelabu lo sọ eyi di mimọ ninu atẹjade kan ti ileeṣẹ ijọba to n dari fi sita lọjọ Aje ọsẹ yii.

O ṣalaye pe opin yoo de ba bi ẹka apinnaka ati tawọn to n ri si owo ti wọn n pa wọle ṣe n ṣiṣẹ pọ.

Adelabu sọ pe laarin oṣu mẹta akọkọ ninu ọdun 2024 ni awọn yoo gbe igbesẹ naa.

Ṣaaju ni iroyin kan ti gbode pe, ileeṣẹ mọnamọna fẹẹ fi kun iye owo ina ti araalu yoo maa san, ati pe ọjọ kinni, oṣu Kinni, ọdun 2024 ni igbesẹ naa yoo bẹrẹ.

‘’Ohun to jẹ wa logun ni kina kari’’

Gẹgẹ b’Adelabu ṣe wi, ‘’ ohun akọkọ to jẹ wa logun ni bi ina ṣe maa kari, ti adinku yoo si ba gbese ati adanu to n waye.

A n ṣiṣẹ lorii iye ti a n na, yoo han si kaluku. Bẹẹ la ṣe ṣiṣẹ gidi lasiko ọdun to kọja yii, kawọn eeyan le gbadun asiko isinmi wọn’’

Owo iranwọ tijọba Naijiria n san lorii ina mọnamọna pọ si i lati ibẹrẹ ọdun to kọja, gẹgẹ bi akọsilẹ Nigerian Electricity Regulatory Commission,(NERC) to n ri si ọrọ ina ṣe sọ.

Ohun to fa eyi ni bi wọn ṣe ni ko si eto lori iye ti ijọba n na lori ipese ina mọnamọna.

Aarẹ Bọla Tinubu sọ ninu ọrọ rẹ lọjọ akọkọ ninu ọdun 2024 , sọ pe ọrọ ina mọnamọna jẹ oun logun pupọ, ijọba oun yoo si sapa lati ri i pe atunṣe ba ẹka naa.