You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Mo dúpẹ́ pé mo wà láyé láti ṣe ọjọ́ ìbí oṣù kan ọmọ mi - Azeez Ijaduade
Gbajugbaja osere tiata, Azeez Ijaduade ti fi ẹmi imore han si Ọlọrun to fun ni anfani lati se ọjọbi oṣu kan ọmọ rẹ lẹyin oriyọ lọwọ ikọlu Ọlọpaa to sina bolẹ fun un laipẹ yii.
Ninu ọrọ rẹ to gbe sori opo ayelujara rẹ, o ni ko si bi ogun ati wahala aye se le sẹlẹ to, orin ayo ni oun yoo ma kọ sita.
O ni; “Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun to jẹ ki wa laye lati se ajọyọ ọjọbi ọmọ mi, Oluwafirefemi Sultan Obaloluwa Ijaduade.
Bakan naa o fi akoko naa dupẹ lọwọ fun ololufẹ rẹ to sugba rẹ lẹyin ti Ọlọpaa kan sina bolẹ fun, to si dero ile iwosan.
Ijaduade ni o ti kuro ni ile iwosan lẹyin to gba itọju tan.
“Lati ọkan mi ni mo ti n dupẹ fun ifẹ ti awọn eeyan fi han si mi,
“Awọn ẹbi mi, awọn akọroyin, ọrẹ, awọn akẹgbẹ mi ati ẹgbẹ TAMPAN.
“Iranlọwọ yin ni n ko le fọwọ rọ sẹyin rara, ẹ ku adoro ti mi .
“Bi mo se n gba itọju bayii, mo fẹ ki ẹ mo pe ninu ọkan mi ni mo fiyin si.”
Ki lo sẹlẹ saaju?
Iroyin to n tẹ wa lọwọ lọdun to kọja nipa Azeez Ijaduade sọ pe ọlọpaa kan ti dana ibọn ya oṣere tiata Yoruba,Ijaduade, lagbegbe Iperu, nipinlẹ Ogun.
Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, oṣerẹ naa, to tun jẹ oludari fiimu ti wa nile ẹkọ ẹkọṣe iṣegun Babcock University Teaching Hospital niluu Ilishan-Remo, nibi to ti n gba itọju lọwọ.
Ọkan lara awọn akẹgbẹ rẹ, Abiodun Adebanjo lo fi ọrọ naa lede loju opo Instagram rẹ ni afẹmọju.
Atẹjade naa ni “Ẹ jọwọ a nilo iranlọwọ niluu Iperu.
“Ọlọpaa ti yinbọn fun oludaru fiimi mi, Azeez Ijaduade, o si ti wa ni Babcock University Teaching Hospital bayii fun itọju.
“Ẹ jọwọ ki ẹnikẹni to ba ni nọmba ọga agba ọlọpaa patapata tabi ti kọmiṣọna fi ṣọwọ si wa.”
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun sọrọ lẹyin iroyin to ni ọkan lara oṣiṣẹ rẹ yinbọn lu oṣere tiata Yoruba, Azeez Ololade Ijaduade, niluu Iperu.
Ninu atẹjade kan ti ileeṣẹ naa fi lede loju opo Twitter ni alukoro rẹ Odutola Omolola ti ni kii ṣe pe ọlọpaa naa mọọmọ yinbo lu oṣere ọhun, amọ korofo ọta ibọn lo ṣeṣi ba a.
Gẹgẹ bii ohun ti ọlọpaa sọ, ibi ti wọn ti n ṣajọyọ opin ọdun ‘end of year party’ ileeṣẹ kan ni iṣẹlẹ naa ti waye.
O ni “Ọkunrin kan, Fakoya Adewale to jẹ alakoso ile itura Napoli sọ fun ọlọpaa pe lasiko ti wọn n ṣe ayẹyẹ orikadun ileeṣẹ Bramaj nile itura naa ni ọlọpaa to n ṣọ ọmọ orilẹ-de China kan yinbọ soke, ti korofo ọta ibọn naa si ba Azeez Ijaduade lọrun.
“Wọn gbe digbadigba lọ sile iwosan fun itọju, ara rẹ si ti n balẹ bayii.”