Ipa wo ni ìṣubú Assad yóò ní lórí àwọn ọmọ ogun Russia ní Africa?

Oríṣun àwòrán, Reuters
- Author, Marco Oriunto
- Role, BBC News
- Reporting from, London
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5
Bi ijọba Aarẹ Bashar al-Assad ṣe ṣubu lorilẹede Syria ti n ṣakoba fun alaafia lẹkun Middle Eastm koda, iṣẹlẹ naa ti bẹrẹ si n ni ipa de orilẹede Russia.
Ni bayii, iṣubu ijọba Assad ni Syria le ṣakoba fun ọmogun Russia ti orilẹede naa fi n ṣeranwọ fawọn orilẹede kan lẹkun Sahel.
Lọdun 2017, ijọba Russia buwọlu iwe adehun kan pẹlu Aarẹ al-Assad eyi to fun Russia lanfaani lati lo ilu Tartus ni Syria lọfẹẹ fun awọn ọmogun ori omi rẹ fun ọdun mọkandinlaadọta.
Russia ni oniruuru ọkọ oju-omi ijagun niluu Tartus to fi mọ oriṣiiriṣii ọkọ oju omi ijagun to maa n wa labẹ omi ati ọgọọgọrun ọmogun ti Russia n lo l'Afirika ati lẹkun Middle East.
Syria ati Russia tun ṣe adehun lati maa lo ilu Latakia to jẹ ilu mii ni Syria fun ibi ti Russia yoo maa ko nnkan ijagun oju ofurufu wọn si atawọn ohun ija oloro to lagbara mii.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Russia maa n lo ibudo iko nnkan ogun pamọ si ni Syria lati fi ohun ijagun ranṣẹ sawọn ọmogun rẹ kaakiri ilẹ Afirika.
Ọgbẹni Oliver Windridge to jẹ adari ajọ to n ṣe iwadii, The Sentry, ṣalaye pe idubo ologun Russia to wa ni Libya lawọn nnkan ija oloro naa maa n kọkọ de si ki wọn to ko wọn lọ sawọn orilẹede Afirika ti wọn ti fẹ lo wọn.
Ko sẹni ti o le sọ bayii bo ya Russia si maa ni ibasẹpọ to dan mọran pẹlu ijọba alatako to gbajọba ni Syria bayii.
Russia lo gba Aarẹ al-Assad Syria tẹlẹ si Russia lẹyin tawọn ọmogun alatako gbajọba rẹ.
Dmitry Peskov to jẹ agbẹnusọ ijọba Russia ti sọ pe ko si ohun ti ko le ṣẹlẹ lọwọ yii.
O ni awọn ọmogun Russia naa n ṣe pẹlẹ pẹlẹ lọwọ yii ni Syria.
Awọn ijọba ilẹ Afirika le bẹrẹ si ni maa ṣe igbaradi fawọn ọmogun labẹle
Windridge sọ pe eyi le jẹ ibẹrẹ opin fun Russia nilẹ Afirika.
Lẹyin awọn iditẹgbajọba to waye, awọn olori ijọba ologun lorilẹede Niger, Mali ati Burkina Faso ti fopin si ibasẹpọ to wa laarin wọn ati orilẹede France atawọn orilẹede Yuroopu ati Amerika.
Lẹyin naa ni wọn bẹrẹ si ni ṣe ajọṣepọ pẹlu orilẹede Russia.
Ọmọwe Alex Vines to jẹ oluwadii pẹlu Chatham House sọ pe Moscow ti ri ọja nibi tawọn ajijagbara wa eyi tawọn orilẹede to ti goke agba ṣatilẹyin fun.
Ileeṣẹ ologun Russia ti wa ni awọn orilẹede bii Mali, Burkina Faso, Niger ati Equatorial Guinea ni ẹkun iwọ oorun ilẹ Afirika.

Gẹgẹ bi Ọmọwe Vines ṣe sọ, ipa Russia wa ni orilẹede C.A.R. gan an nibi to ti ni bi ẹgbẹrun meji ọmogun ti yoo maa dena iditẹgbajọba ti yoo si maa pese eto aabo nibẹ.
Ara nnkan mii to jẹ ki Russia nifẹ si orilẹede C.A.R. ni goolu ti wọn n wa nibẹ ati kara-kata nnkan ijagun.
Russia ni bi ẹgbẹrun kan ọmogun ni Mali, o lawọn ti ko to ọgọrun ni Burkina Faso nigba ti o si ni ẹgbẹrin ọmogun ni Equatorial Guinea lati daabo bo Aarẹ Teodoro Obiang Nguema Mabasogo to jẹ olori orilẹede to ti pẹ julo lori oye lorilẹede naa.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ikọlu kan ṣẹlẹ si ilu Bamako lorilẹede loṣu Kẹsan an to kọja.
Agbẹnusọ ikọ agbesunmọmi Jama'at Nusrat wa al Muslimeen(JNIM) ti ṣeleri pe ẹgbẹ agbesunmọmi naa yoo tun ṣe ikọlu sawọn ilu mii.
Onwoye kan lorilẹede Senegal, Beverly Ochieng, ni iru ẹgbẹ JNIM le fẹ lo iru nnkan to n ṣẹlẹ ni Syria lati ṣe ikọlu sawọn ibomiran.
Ochieng ni awọn ẹgbẹ al Qaeda ti n dunnu ni Mali pẹlu nnkan to n ṣẹlẹ ni Syria.

Oríṣun àwòrán, EPA
Nibo ni Russia te le gbe ibudo ologun rẹ lọ?
Russia le wa ibomiran lati da ibudo ọmogun wọn silẹ nilẹ Afirika.
O ṣee ṣe ki Russia da ibudo ọmogun wọn silẹ ni orilẹede Libya ati Sudan.
O ti pẹ ti Russia ti ni ibaṣepọ pẹlu orilẹede Libya pẹlu ọmogun bii ẹgbẹrun kan ataabọ.
Ọgbẹni Windridge ni Russia yoo ṣe idasilẹ ibudo ologun rẹ ni Libya.
Amọ, o ni Russia yoo nilo lati gbaṣẹ lati ọwọ orilẹede Turkey lati ko awọn nnkan pẹlu ọkọ ofurufu lọ si Libya.
O tun fidi rẹ mulẹ pe olori ẹsin ati ẹgbẹ alatako, Grand Mufti, Ọmọwe Sadiq Al-Ghariani yoo tako Russia lori eto yii.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Sudan ni ibomiran ti Russia ti le lọ da ibudi ologun rẹ silẹ.
Ni bayii, Russia ti n gbero lati kọ ibudo ologun loju omi lẹgbẹ ilu Port Sudan.
Ochieng ni eyi ṣe pataki tori ipa Russia ti n pọ si lati Sudan lọ si Mali.
Amọ, o sọ pe bi iditẹgbajọba ṣe n waye le dena ohun ti Russia fẹ ṣe.















