You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
'Omijé ni mo fi n wẹ ibùsùn mi lálaalẹ́ láti ìgbà tí ìgbéyàwó mi ti túká'
Gbajumọ oṣerebinrin, Abiola Adebayo, ti kede pe igbeyawo oun ti tuka.
Ninu ọrọ kan to kọ si oju opo ayelujara Instagram rẹ lọjọ Iṣẹgun, ni arẹwa oṣere naa ti kede pe lati oṣu Kẹrin ọdun 2024, ni awọn ti pinya.
Oṣu Kẹrin, ọdun 2021 ni Biola ati ọkọ rẹ atijọ, Oluwaseyi Akinrinde, ṣe igbeyawo wọn, ti wọn si bi ọmọ kan ṣoṣo to wa laarin wọn lọdun 2023.
"O wu mi ki igbeyawo mi tọjọ, sugbọn o san ki n wa laye lati fi ẹnu ara mi sọ iriri mi."
Abiola Adebayo ni, bi oun ṣe n mu inu awọn eeyan dun lọsan án, ni oun n fi omije wẹ irọri oun lalaalẹ lati oṣu mẹrinla sẹyin.
O ṣalaye pe awọn mejeeji ti fẹnuko lati fọwọsowọpọ fun itọju ọmọ wọn.
Nnkan to yẹ ki o mọ nipa Biola Adebayo
Abiola Adebayo jẹ gbajugbaja oṣere tiata , to ti kopa ninu ọpọ sinima agbelewo.
Ọdun 1981 ni wọn bi oṣerebinrin yii, to si la ọpọ nnkan kọja ko to di pe o di ilumọka.
Gẹgẹ bii o ṣe wa ninu opo Wikipedia rẹ, Adedayo ni lati ma kiri ọja ko to di pe o ri owo lati lọ si ile ẹkọ.
Ni ọjọ keje, oṣu kẹrin, ọdun 2021 ni o kede igbeyawo rẹ pẹlu ọkọ rẹ, Oluseyi, to si fi da awọn ololufẹ rẹ loju pe oun yoo mojuto ile oun, ti ko si ni faaye gba kudiẹkudiẹ kankan.
Lọdun 2020, o gba ami ẹyẹ Best supporting actress BON award
Bakan naa lo da oju opo ayelujara silẹ, nibi to ti n fun awọn oṣere tiata ni anfaani lati sọ ẹdun ọkan sita ati awọn nnkan mii ti wọn n la kọja.
Laipẹ yii ni o ṣe igbelarugẹ fun awọn agba oṣere bi Jumoke George, Dupẹ Jaiyesinmi ati bẹẹ lọ, ti wọn si tara rẹ ni anu gba lati ọwọ awọn ọmọ Naijiria.