You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Biola Adebayo, gbajúmọ̀ òṣèré tíátà, di ọlọ́mọ lẹ́yìn tó wá abánigbóyún fún ìgbà mẹ́ta láàrin ọdún méjì láì rí
Gbajumọ oṣere tiata, Adebayo Abiola Ayọmide ni Eleduwa ti ṣe ọmọ tuntun jojolo kan fun oun ati ọkọ oun.
Ninu atẹjade kan to fi si oju opo Instagram rẹ, gbajumọ oṣere naa ni eto imọ igbalode oyun abanigbe ti oloyinbo n pe ni ‘surrogacy’ loun fi bi ọmọ naa .
O ni igba mẹta ọtọtọ loun wa obinrin to ba oun gbe oyun, ti eto naa si tun ja si otubantẹ laarin odun meji, ki Olorun to da oun loun.
"Mo gbé atọ ọkunrin sinu ile ọmọ mi lati bimọ amọ pabo naa lo ja si"
Bakan naa lo ṣalaye pe ohun tun ṣe eto gbingbin atọ ọmọ sinu ile ọmọ oun lọna igbalode, IVF ni igba kan ti eyi pẹlu tun ja si otubantẹ.
“Ọlọrun ti pada fun emi ati ọkọ mi ni ọmọ ọkunrin lantilanti nipasẹ imọ igbalode oyun abanigbe ti oloyinbo n pe ni ‘surrogacy’
“Igba ọtun ti de. Kaabọ ọmọ wa TA.”
Eekan oṣere tiata naa tun fikun pe oun yoo sọ itan irin ajo bi oun ṣe di ọlọmọ nípasẹ ilana imọ igbalode surrogacy laipẹ.
O ni eyi yoo ṣe koriya fun awon obi to ṣi n tiraka lati ri ọmọ tiwọn gbe jo nipasẹ eto imọ igbalode yii.