Orilẹ̀èdè Kuwait yan Ọba tuntun

Iyansipo ọba tuntun ni wọn ti kede lorilẹede Kuwait lẹyin ipapoda Ọba Sheikh Nawaf al-Ahmad al-Jaber al-Sabah.

Ọba tuntun, Sheikh Meshal al-Ahmad al-Jaber al-Sabah, lo jẹ ibatan ọba to gbesẹ.

Sheikh Nawaf to waja lẹni ọdun mẹrindinlaadọrun, ni wọn kede iku rẹ lọjọ Abamẹta.

Ọba tuntun naa to ti bẹrẹ iṣe lo sin fun ọpọ ọdun lẹka eto abo ilẹ Kuwait.

Wọn ti kede ogoji ọjo lati fi daro ọba to waja naa jakejado orilẹede ọhun.

Sheikh Nawaf Al-Ahmad Al-Jaber Al-Sabah ni ọba kẹrindinlogun ni Kuwait, oun si ni ọba kẹfa lati igba ti orilẹede naa ti gba ominira lọwọ ilẹ Gẹẹsi.

Ọdun mẹrinla ni Sheikh Nawaf fi jẹ arole ko too di ọba ni 2020 lẹyin iku Sheikh Sabah Al-Ahmad.

Ọjọ kẹẹdogun, oṣu kẹfa, ọdun 1937 ni wọn bi Sheikh Nawaf ni Fareej Al-Shuyoukh ni Kuwait City.

Aafin Dasman nilu Kuwait to jẹ ibujoko ijọba lakoko ijọba Prince Ahmed Al-Jaber to jẹ baba rẹ ni Sheikh Nawaf ti dagba, to si lọ ileẹkọ loriṣiriṣi nilu naa to fi mọ Mubarakiya.

Sheikh Nawaf di ọpọ ipo oṣelu mu, bẹrẹ lati ipo gomina ipinlẹ Hawalli lọdun 1962 fun ọdun mẹrindinlogun, ko too di minisita fọrọ abẹle lọdun 1978.

Lọdun 1988, o di minisita feto abo, to dari bi orilẹede naa ṣe kogun ja Iraq fun oṣu meje ki America too da sii lọdun 1991.

Sheikh Nawaf di ọba lẹyin ipapoda Sheikh Sabah Al-Ahmad.

O si ni ipa to pọ lati ko ninu ibadọrẹ awọn ilẹ okeere, nibi to ti n da si aawọ lawọn ẹlẹkunjẹkun.

Orukọ ti ọpọ eeyan maa n pe ọba naa ni “olori apẹtusaawọ” ni Kuwait ati kaakiri ilẹ Arab.

Sheikh Nawaf di ọba lọjọ kọkandinlọgbọn oṣu kẹsan ọdun 2020, ti wọn si bura fun-un laarọ ọjọ keji niwaju igbimọ aṣofin orilẹede naa.