You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Kí ló mú kí China máa ti Mọ́ṣálásí pa, tí wọn sì tún ń wó o?
Ẹgbẹ ajijagbara kan, Human Rights Watch (HRW) ti fẹsun kan orilẹ-ede China pe o n wó awọn mọsalaaṣi to wa lorilẹ-ede naa palẹ, kawọn ẹlẹsin Islam to wa nibẹ le maa rọna lati jọsin mọ.
Ninu iroyin kan ti HRW fi sita ni wọn ti ṣalaye pe lara ọgbọn arekereke China ni wọn n lo, ti wọn fi n ti awọn mọṣalaaṣi pa, ti wọn si n wo awọn mi-in palẹ.
Gẹgẹ bi akọsilẹ, o to ogun miliọnu eeyan ti wọn jẹ ẹlẹsin Islam lorilẹ-ede China, nigba ti ọpọ eeyan nibẹ ko gbagbọ ninu Ọlọrun.
Sugbọn wọn faaye silẹ fawọn ẹlẹsin mi-in lati ṣe ẹsin wọn.
Awọn awoye ọrọ fidi ẹ mulẹ laipẹ yii, pe idaamu n ba awọn ẹlẹsin yooku naa lasiko yii ju ti tẹlẹ lọ.
Beijing tako ẹsun naa
Ikọ iroyin BBC kan si ẹka to n ri si ọrọ ẹsin ati ẹya ni China, lati gbọ latọdọ wọn, ṣaaju ki ẹgbẹ HRW too gbe ẹsun tiwọn jade.
Beijing tako ẹsun naa.
Maya Wang, Adele to n dari ẹgbẹ HRW, sọ pe, ‘’Bijọba China ṣe n ti mọṣalaaṣi pa, ti wọn n ba a jẹ, ti wọn si n sọ ọ di nnkan mi-in, jẹ ọna kan lati dẹkun ṣiṣe ẹsin Islam ni China"
Ṣugbọn ijọba China sọ pe bawọn ṣe n se adapọ awọn mọṣalaaṣi, eyi to si jẹ pe abule lo ti n ṣẹlẹ ju, maa n waye nigba tawọn ara abule kan ba fi ibi ti wọn n gbe silẹ, ti wọn lọ sibomi-in.
Wọn lo maa n din iṣoro owo nina ku fawọn musulumi naa ni, ṣugbọn awọn Musulumi Hui kan maa n ro pe awọn fi n dan igbagbọ awọn wo ni.
Pupọ ninu awọn ẹlẹsin Islam ni China ni wọn n gbe ni Ariwa-Iwọ Oorun orilẹ-ede naa, awọn agbegbe bii Xinjiang, Qinghai, Gansu ati Ningxia.
Abule kan ti wọn n pe ni Liaoqiao, nibi tawọn musulumi pọ si ni Ningxia, awọn fẹsun kan ijọba China pe mẹta ninu mọṣalaaṣi mẹfa to wa nibẹ ni wọn ti yọ irin gogogoro to maa n kede mọṣalaaṣi kuro (dome).
Wọn ni bẹẹ naa ni wọn ṣe yọ aaye ti Ladani ti n perun kuro pẹlu.
Wọn ni ọpa gogoro to n kede ileejọsin onitẹmpili ni wón fi rọpo rẹ.