You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Wo ìdí tí ìdìtẹ̀gbàjọba míràn ko fi leè wáyé ni Nàíjíríà
Orilẹ ede Naijiria n sajọyọ ayẹye ọdun marundinlọgbọn eto ijọba awarawa loni.
Nibi pọpoṣinṣin ayẹyẹ naa ni Aarẹ Bola Tinubu ti bi awọn eeyan ilẹ Naijiria sọ ọpọlọpọ ọrọ, Ṣugbọn yatọ fun bi ayẹyẹ ọun ti n waye ni awọn eeyan n beere pe kini idi ṣiṣe ọdun naa.
Gbolohun to saba maa n jade latẹnu awọn adari ni ipo oselu ni wi pe, ṣe eeyan lee jẹ eto ijọba awarawa, bẹẹ lo tun jẹ ọrọ ti wọn fi n kilọ nipa ohun ti iye ero awujọ to pọ ju lee sokunfa.
Ọpọlọpọ ọmọ ilẹ Naijiria lo n tiraka lati gbe igbe aye wọn ninu iṣoro eto ọrọ aje to dẹnukọlẹ ati bi owo ohun elo ti gbẹnusoke lọja ni inu awọn eeyan ko fi bẹẹ dun si.
Ninu ayẹwo to jade lọdun 2022, ko to di i pe rogbodiyan eto ọrọ aje gbode lo fihan pe ọpọ eeyan ile Naijiria ni ko faramọ bi eto ijọba tiwan tiwa ti ri.
Ẹwẹ, iwadi yi kan naa lo fihan pe ọpọ awọn eeyan ọun ni wọn fẹran ilana ijọba awarawa ju ilana ijọba miran lọ.
Lati ọdun 1960, ti ilẹ Naijiria ti gba ominira, ilana iṣejọba alagbada ko fi bẹẹ pẹ, lori bi awọn ologun ti dari di ọdun 1999.
Ètò ìjọba àwaarawa pín àwọn ọmọ ilẹ̀ Nàíjíríà yẹ́lẹyẹ̀lẹ
Ọjọgbọn Kayọde Sorẹmẹkun onimọ nipa itan tọka si i pe igbesẹ iditẹ gbajọba lo ṣeeṣe ko maa lee waye ni Naijiria.
O fikun ọrọ rẹ pe ile iṣẹ ologun ti kọ iwe itan ara wọn dori ipele tawọn eeyan ilu ko fi riwọn bii olugbeja wọn mọ.
Adedeji Adekunle ẹni ọdun mọkandinlọgọta mẹnuba iriri rẹ gẹgẹbi akẹẹkọ ni ibere ọdun 1998, O sọ fun BBC pe inira oun ifiape pọ lasiko ti ijọba ologun gbode.
O ṣalaye ohun toju rẹ ri nigba ti wọn ṣe iwode tako awọn ologun ni ilu Eko, nipa bi awọn soja ti mu wọn satimọle pelu ijiya to nipọn leyi to juwe gẹgẹbi iriri to nira julọ.
Ajọ kan towa fun ipolongo ẹtọ ọmọniyan ni ilu New York tọka sii pe laarin ọdun 1980 si 1990 ti awọn ologun fi dari ni.
Abawọn ti de ba eto ọrọ aje ilẹ Naijiria, wahala ọrọ oṣelu ati igbesẹ titẹ ẹtọ ọmọniyan loju mọlẹ ti bẹrẹ.
Lẹyin ti Ọgagun Sani Abacha papoda lọdun 1998, ti Ọgagun Abdulsalami Abubakar bẹrẹ iṣakoso pẹlu ileri mimu ki ijọba alagbada gberasọ ni ilẹ Naijiria lẹyin ọdun kan.
Asofin tẹlẹri Shehu Sani ṣalaye wi pe nigba ti ijọba tiwa n tiwa pada de silẹ Naijiria lo tubọ mu igbagbọ awọn eeyan ru soke si i nipa nini anfaani lati sọ ohun tiwọn ba fẹ, isokan ati alaafia ilẹ baba wọn.
Sugbọn awọn ọdọ iwoyi niko ni ekunrẹrẹ imọ nipa ohun gan to sẹlẹ lasiko iṣejọba ologun, bẹẹ ni itan naa ko fi taratara ni itumọ siwọn.
Idari Aarẹ Bola Tinubu to wa lori ipo lọwọ lowa ni ọkan ọpọ ọdọ ilẹ Naijiriria lori bi ipenija eto ọrọ aje ti gbode laarin ọdun kan iṣejọba rẹ.
Ifopinsi sisan owo iranwọ ori epo bentiro ati aiṣe deede owo Naira ti muki owo nnkan tubọ fo fẹẹrẹ soke ninu awọn lọja.
Ọkan o jọkan alakalẹ ofin atunto ti Aarẹ Tinubu n ṣe lo wa fun mimu idurore ba eto ọrọ aje ati idagbasoke ọlọjọ pipẹ, ṣugbọn awọn ofin naa ko mu idẹrun ba awọn to n ṣakoba fun lawujọ.
Agbeyẹwo ilẹ Naijiria lati ọdun marundinlọgbọn sẹyin, alekun onilọpo mẹrin inanwo lo ti gori iye owo to n wọle fun awọn eeyan, gẹgẹ bi oju ọjọ eto ọrọ aje awujọ ti n ri si.
Awọn eeyan to n fẹ ki ijọba ologun pada wa ni ko ni ifẹ ilẹ Naijiria lọkan.
Ọpọ awọn ọdọ iwoyi fin n sọ pe wọn fẹran ki ijọba ologun pada waye,
Gẹgẹbi Thomas ẹni ọdun mẹtalelogbọn kan ti salaye, o ni, lati igba ti oun ti pe ọmọ ọdun mejidinlogun ni oun ti bẹrẹ sini di ibo sugbọn ti awọn adari ti ja oun kulẹ.
O tọka si i pe ijọba ologun maa n duro lori ipinnu wọn, ati pe ki wọn gbegbesẹ onikia lati muki imunadoko wọnu iṣejọba ilẹ Naijiria, leyi to si jẹ gbolohun ti ọpọ sọ loju itakun ayelujara.
Awọn ọdọ naa tun sọ pe ko fi bẹẹ si iwa jẹgudujẹra ati iwa ọdaran nigba ijọba ologun bi ti asiko yi.
Ṣugbọn o ṣeeṣe ki diẹ lara wọn ti gbagbe bi Ọgagun Sani Abacha ti fẹyin pọn owo ilu lọ silẹ okeere, bẹẹ ni wọn si ti ri dukia naa gba pada.
Aarẹ Bola Tinubu gan ko fi bẹẹ sọrọ nipa idari ologun nitori bi wọn ti figbakanri fi pamọ sinu atimọle lasiko iwode tako awọn ologun.
Kete lẹyin ti Aarẹ Tinubu bọ sori ipo ni orilẹ ede alamulegbe Niger dojukọ igbesẹ iditẹ gbajọba ṣugbọn ti wọn bu ẹnu atẹluu, bẹẹ oorun irufẹ igbeṣẹ ọun fẹ mu nilẹ Naijiria nigba naa.
Ijọba gbọdọ ṣiṣẹ si i lati mu ironi lagbara ba eto ijọba tiwa n tiwa.
Ẹwẹ, Awọn adari ologun ilẹ Naijiria sọpe awọn ko nifẹ si gbigba iṣakoso mọ, ninu ọrọ ti olori ile iṣẹ eleto aabo ilẹ Naijiria Ọgagun Christopher Musa ti sọ losu erele ọdun 2024.
O ni awọn eeyan to n pefun ki ijọba ologun pada wa ni ko nifẹ ilẹ Naijiria lọkan.
O sọ pe ojuṣe ile iṣẹ ologun ni lati daabo bo eto ijọba tiwa n tiwa pẹlu atilẹyin to muna doko tẹsiwaju sii.
Oriṣiriṣi iṣẹlẹ lo si ti waye laarin ọdun marundinlọgbọn sẹyin, nigba ti ko sẹni to mọ ibi ti Aarẹ Umar Musa Yar’Adua wa, wi pe, o yẹ ki ologun gbajọba sugbọn ti nnkan kan ko ṣẹlẹ rara.
Ọkan lara awọn ọmọ ile igbimọ asofin apapọ ni Naijiria Babangida Hussaini lati ipinlẹ Jigawa sọ pe igbagbọ oun ni wipe wọn ti ṣagbekalẹ awọn ofin to ka awọn ologun ti wọn ni iru ero ọun lọwọ ko, ati wipe wọn ti ṣe irolagbara fun eto ijọba awarawa.
Asofin Babangida ni o ṣeeṣe ki wọn maa tii ṣe to fun awọn eeyan ilẹ Naijiria sugbọn igbeṣẹ ṣi n tẹsiwaju lori rẹ.
Ọjọgbọn Fidelis Allen wa lara awọn ọmọ bibi ilẹ Naijiria to n beere nipa bi awọn ologun ko ṣe si lori aga iṣakoso ṣe papọ mọ ilana ijọba tiwa n tiwa.
O ni ọpọ awọn eeyan lo n dibo lati ọdun 1999, ti wọn ko si dakẹ beere nipa bi awọn adari ti n jiyin iṣẹ iriju wọn si fun awọn ara ilu to dibo fun wọn, lori nina owo to n wọle ati bi wọn ti n ṣe otitọ si awọn ipinnu wọn.
Ọjọgbọn Sorẹmẹkun mẹnuba igbagbọ rẹ nipa wọn gbọdọ ṣiṣẹ si i lati mu ironi lagbara ba eto ijọba tiwa n tiwa.
O ni eto ijọba awarawa dun ju iṣejọba ologun lọ, ṣugbọn ki wọn tubọ muki ere ijọba awarawa to awọn eeyan ilu lẹnu si i ni orilẹ ede Naijiria.